Àwọn Ìwé Mímọ́
Àsọyé Ní Kúkúrú Nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì


Àsọyé Ní Kúkúrú Nípa
Ìwé ti Mọ́mọ́nì

Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ìwé ìrántí mímọ́ ti àwọn ènìyàn ilẹ̀ Amẹ́ríkà àtijọ́, a sì fí wọn sórí ewé oríṣiríṣi àwo. Irú oríṣiríṣi àwo mẹ́rin ni a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú ìwé nã tìkalãrẹ̀:

  1. Àwọn Àwo ti Nífáì, èyítí ó jẹ́ oríṣi méjì: àwọn Àwo Kékeré àti àwọn Àwo Nlá. Ti tìṣãjú ni a lò ní pàtàkì fún àwọn nkan ti ẹ̀mí àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti àwọn ẹ̀kọ́ àwọn wòlĩ, nígbàtí ti ìkẹhìn kún fún ìwé ìtàn ti ayé ti àwọn ènìyàn tí ó kàn (1 Nífáì 9:2–4). Ṣùgbọ́n láti ìgbà Mòsíà, àwọn àwo nlá nã ní àwọn ohun pàtàkì tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí nínú pẹ̀lú.

  2. Àwọn Àwo ti Mọ́mọ́nì, èyí tí ó ní ìkékúrú nípa ọwọ́ Mọ́mọ́nì láti inú Àwọn Àwo Nlá ti Nífáì, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé àsọyé. Àwọn àwo wọ̀nyí ní ìfápẹ́títí ìwé ìtàn nípa ọwọ́ Mọ́mọ́nì àti àwọn àfikún láti ọwọ́ ọmọ rẹ̀ Mórónì.

  3. Àwọn Àwo Étérì, èyí tí ó gbé ìwé ìtàn àwọn ará Járẹ́dì kalẹ̀. Ìwé ìrántí yí ni a ké kúrú lati ọwọ́ Mórónì, ẹni tí ó fi àsọyé tirẹ̀ sì I lãrín tí ó sì pa ìwé ìrántí nã pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwé ìtàn lábẹ́ orúkọ “Ìwé ti Étérì.”

  4. Àwọn Àwo Idẹ tí àwọn ènìyàn Léhì mú wá láti Jerúsálẹ́mù ní ẹgbẹ̀ta ọdún kí á tó bí Krístì. Àwọn wọ̀nyí ní “àwọn ìwé márun ti Mósè,…Àti pẹ̀lú ìwé ìrántí àwọn Jũ láti ìbẹ̀rẹ̀,…títí dé ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sẹdẹkíàh, ọba Júdà; Àti pẹ̀lú àwọn ìsọtẹ́lẹ́ àwọn wòlĩ mímọ́” (1 Nífáì 5:11–13). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ gan-an láti inú àwọn àwo wọ̀nyí, tí ó nsọ ọ̀rọ̀ Isaiah àtí àwọn wòlĩ míràn tí ó wà nínú bíbélì àti tí kò sí nínú bíbélì, ni ó yọ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

Ìwé ti Mọ́mọ́nì pín sí apá tàbí abala mẹ́ẹdógún, tí a mọ̀, yàtọ̀ sí ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwé, ti a n fi orúkọ olórí ẹni tí o kọ̀wé nã pè. Apá èkíní (àwọn ìwé mẹ́fà tí ó ṣãjú, títí de Ómúnì) jẹ́ ìyírọ̀padà láti inú Àwọn Àwo Kékeré ti Nífáì. Lãrín àwọn ìwé Ómúnì àti Mòsíà ni àfisínú kan tí à npè ní Àwọn Ọ̀rọ̀ Mọ́mọ́nì. Àfisínú yí so ìwé ìrán tí a fín sórí Àwọn Àwo Kékeré pọ̀ pẹ̀lú ìkékúrú Mọ́mọ́nì ti Àwọn Àwo Nlá.

Abala tí ó gùn jùlọ, láti Mòsíà dé Mọ́mọ́nì, pẹ̀lú orí keje, jẹ́ ìyírọ̀padà ìkékúrú Mọ́mọ́nì ti Àwọn àwo Nlá ti Nífáì. Abala tí a ṣe parí, láti Mọ́mọ́nì, orí kejọ, dé òpin ìwé nã, ni Mórónì, ọmọ Mọ́mọ́nì fín, ẹni tí, lẹ́hìn tí ó ti parí ìwé ìrántí ìgbé ayé bàbá rẹ̀, ṣe ìkékúrú ìwé ìrántí àwọn ará Járẹ́dì (bí Ìwé ti Étérì) ó sì fi àwọn apá kan kún un tí a mọ̀ sí Ìwé ti Mórónì.

Ní, tàbí níwọ̀n ọdún 421 lẹ́hìn ikú Olúwa wa, Mórónì, tí ó jẹ́ ìkẹhìn nínú àwọn wòlĩ-òpìtàn àwọn ará Nífáì, fi èdídì di ìwé ìrántí mímọ́ nã ó sì pa á mọ́ sí Olúwa, kí á mú u jáde wá ní ìgbà ìkẹhìn, bí ohùn Ọlọ́run ti sọtẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlĩ rẹ̀ àtijọ́. Ní ọdún 1823 lẹ́hìn ikú Olúwa wa, Mórónì kannã, tí ó ti jínde nígbànã, bẹ Wòlĩ Joseph Smith wò, ó sì gbé àwọn àwo tí a fín fún un.