Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Hosanna àti Hallelúyà—Jésù Krístì Alààyè: Ọkàn Ìmúpadàbọ̀sípò àti Ọdún Àjínde
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Hosanna àti Hallelúyà—Jésù Krístì Alààyè: Ọkàn Ìmúpadàbọ̀sípò àti Ọdún Àjínde

Ní àkókò hosanna àti halleluyàh yi, ẹ kọrin halleluyah—nítorí Òun yío jọba láé àti títí láéláé!

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n: pẹ̀lú hòsannà àti hallelúyà, a nṣe àjọyọ̀ Jésù Krístì alààyè ní àkókò títẹ̀síwájú Ìmúpadàbọ̀sípò àti Ọdún Àjinde. Pẹ̀lú ìfẹ́ pípé, Olùgbàlà wa nfi dá wa lójú pé: “Nínú mi ẹ̀yin yío le ní àlàáfíà. Nínú ayé ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú: ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”1

Ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, bí Arábìrin Gong àti èmi ti pàdé ẹbí rírẹwà kan, ọ̀dọ́ ọmọbìnrin wọn Ivy fi ìtìjú mú apò faolínì rẹ̀ jáde. Ó fa bóò faolínì náà jáde, ó dè é ó sì fi rósìnì sí i. Lẹ́hìnnáà ó rọra fi bóò náà padà sí inú apò, ó tẹríba, ó sì jókòó. Àṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ tuntun, ó kàn ti ṣe àbápín gbogbo ohun tí ó mọ̀ nípa faolínì náà. Nísisìyí, ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́hìnnáà, Ivy nlo fáolínì náà dáradára.

Àwòrán
Ivy àti faolínì rẹ̀

Ní àkókò ayé kíkú yi, gbogbo wa fi díẹ̀ rí bíi Ivy àti faolínì rẹ̀. A nbẹ̀rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀. Pẹ̀lú ìdánrawò àti ìtẹramọ́, a ndàgbà a sì ngbèrú. Pẹ̀lú bí àkókò ti nkọjá, òmìnira láti yàn dáradára àti àwọn ìrírí ayé kíkú nràn wá lọ́wọ́ láti dàbí Olùgbàlà wa síi bí a ti nṣiṣẹ́ pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ọgbà àjàrà Rẹ̀2 tí a sì ntẹ̀lé ipa ọ̀nà májẹ̀mú Rẹ̀.

Àwọn àjọ̀dún, pẹ̀lú ti igba odún yi, máa nṣe ìtànná àwọn ètò ìmúpdàbọ̀sípò.3 Nínú síṣe àjọyọ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì ti ó nlọ lọ́wọ́, a nmúrasílẹ̀ fún Ọdún Ajínde bákannáà. Nínú méjèèjì, a nyọ̀ nínú ìpadàbọ̀ ti Jésù Krístì. Ó wà láàyè—kìí ṣe nígbànáà nìkan, ṣùgbọ́n nísisìyí pẹ̀lú; kìí ṣe fún àwọn díẹ̀, ṣùgbọ́n fún ẹni gbogbo. Ó wá Ó sì nbọ̀ láti wo oníròbinújẹ́ ọkàn sàn, lati dá àwọn òndè sílẹ̀, láti dá ìríran padà fún afọ́jú, àti láti sọ àwọn wọnnì tí a ti pa lára di òmìnira.4 Èyíinì ni olukúlùkù wa. Àwọn ìlérí agbanilà Rẹ̀ yẹ fún mímúlò, bí ó ti wù kí àtẹ̀hìnwá wa àti ìsisìyí wa ó rí, tàbí àwọn àníyàn fún ọjọ́ iwáju wa.

Àwòrán
Ìwọlé ìṣẹ́gun sí Jerúsalẹ́m

Ọ̀la ni Ìsinmi Ọpẹ. Bí àṣà, àwọn imọ̀ ọ̀pẹ jẹ́ àmì mímọ́ láti fi ayọ̀ hàn nínú Olúwa wa, bíi nínú Ìwọlé Ìṣẹ́gun ti Krístì sí Jerúsalẹ́m, nibití “ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn … mú àwọn ẹka igi ọ̀pẹ, tí wọ́n sì jáde lọ láti padé rẹ̀.”5 (Ẹ le ní ìfé láti mọ̀ pé ojúlówó iṣẹ́ ọnà ti Harry Anderson yi ni a fi kọ́ ní ọfísì Ààrẹ Russell M. Nelson, ní ẹhìn tábìlì rẹ̀ gãn. Nínú ìwé Ìfihàn, àwọn wọnnì tí wọ́n nyin Ọlọ́run àti Ọdọ́-àgùtàn ṣe bẹ́ẹ̀ “ní wíwọ àwọn ẹ̀wù funfun, àti imọ̀ ọ̀pẹ ní ọwọ́ wọn.”5 Ní lílọ pẹ̀lú “àwọn ẹ̀wù òdodo” àti “àwọn adé ògo,” àwọn imọ̀ ọ̀pẹ wà nínú àdúrà ìyàsọ́tọ̀ ti Tẹ́mpìlì Kirtland.6

Ní tòótọ́, pàtàkì Ọjọ́ Ìsinmi Ọpẹ tayọ àwọn èrò tí wọn nkí Jésù pẹ̀lú àwọn ìmọ̀ ọ̀pẹ. Ní Ọjọ́ Ìsinmi Ọpẹ, Jésù wọ Jérúsálẹ́mù ní àwọn ọ̀nà tí àwọn onígbàgbọ́ damọ̀ bíi ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀. Bí Sakaríàh8 àti Oní Sáàmù ti sọtẹ́lẹ̀ bíi wòlíì, Olúwa wa wọ Jérúsálẹ́mù ní gígun ọ̀dọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bí àwọn ọ̀pọ̀ èrò ti nkígbe “Hossana ní ibi gíga jùlọ.”9 Hosanna túmọ̀ sí “gbàlà nísisìyí.”10 Nígbànáà, bíi ti ìsisìyí, a yọ̀, “Ìbùkún ni fún ẹni náà tí nbọ̀wá ní orúkọ Olúwa.”11

Ọsẹ̀ kan tí ó tẹ̀lé Ọjọ́ Ìsinmi Ọpẹ ni Ọjọ́ Ìsinmi Ọdun Àjinde. Ààrẹ Russel M. Nelson kọ́ni pé Jésù Krístì “wá láti san gbèsè kan tí Òun kò jẹ, nítorípé a jẹ gbèsè kan tí àwa kò le san.”11 Nítòótọ́, nípasẹ̀ Ètùtù Krístì, gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run “lè di gbígbàlà, nípa ìgbọràn sí àwọn òfin àti àwọn ìlànà Ìhìnrere.”13 Ní Ọdún Àjínde, a nkọrin halleluyah. Halleluyah túmọ̀ sí “ẹ yìn Olúwa Jehófà.”14 “Ègbè Halleluya“ nínú orin Messiah ti Handel jẹ́ ìkede Ọdún Àjínde tí a fẹ́ràn pé Òun ni “Ọba àwọn Ọba, àti Olúwa àwọn Olúwa.”15

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mímọ́ láàrin Ọjọ́ Ìsinmi Ọpẹ àti Ọjọ́ Ìsinmi Ọdun Àjinde jẹ́ ìtàn ti hossana àti halleluyà. Hossana ni ẹ̀bẹ̀ wa fún Ọlọ́run lati gbàlà. Halleluyà nfi ìyìn àti ìmore wa hàn sí Olúwa fún ìrètí ìgbàlà àti ìgbéga. Nínú hosanna àti hallelúyà a nṣe ìdánimọ̀ Jésù Krístì alààyè bíi ọkàn Ọdún Àjínde àti ìmúpadàbọ̀sípò ti ọjọ́ ìkẹhìn.

Ìmúpadàbọ̀sípò ti ọjọ́ ìkẹhìn náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú tìófánì—ìfarahàn pípé ti Ọlọ́run Baba àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, sí ọ̀dọ́mọdé wòlíì Joseph Smith. Wòlíì Joseph sọ pé, “Bí ẹ̀yin bá le wò sí ọ̀run fún ìṣẹ́jú márũn, ẹ ó mọ̀ púpọ̀ ju ohun tí ẹ ó mọ̀ nípa kíka gbogbo ohun tí a ti kọ rí ní orí àkòrí náà.”16 Nítorípé àwọn ọ̀run tún ṣí sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi, a mọ̀ a sì “gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, àti nínú Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, àti nínú Ẹ̀mí Mímọ́”17—Àjọ Ọlọ́run Olórí ti ọ̀run.

Ní Ọjọ́ Ìsinmi Ọdún Ajínde, ọjọ́ kẹta Oṣù Kẹrin, 1836, ní àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ ti Ìmúpadàbọsípò, Jésù Krístì alààyè fi ara hàn lẹ́hìn tí Tẹ́mpìlì Kirtland di yíyàsímímọ́. Àwọn wọnnì tí wọ́n rí I níbẹ̀ jẹ́rìí nípa Rẹ̀ nínú àwọn àfiwe tí ó yàtọ̀ ní ìdojúkọra bí ti iná àti omi: “Àwọn ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná; irun orí rẹ̀ funfun bíi ìrì dídì tí kò ní èérí; ìwò ojú rẹ̀ tàn tayọ ìtànṣán oòrùn; àti ohùn rẹ̀ dàbíi ìró omi púpọ̀, àní ohùn ti Jèhófàh.”18

Ní àkókò náà, Olùgbàlà wa kéde pe, “Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ikẹhìn; Èmi ni ẹni náà tí ó wà láàyè, Èmi ni ẹni náà tí a pa; èmi ni alágbàwí yín pẹ̀lú Bàbá.””19 Lẹ́ẹ̀kansíi, àwọn àfiwe tí ó yàtọ̀ ní ìdojúkọra—àkọ́kọ́ àti ikẹhìn, tí ó wà láàyè àti tí a pa. Òun ni Alfà àti Omégà, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin,19 olùpilẹ̀sẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa.21

Ní títẹ̀lé ìfarahàn ti Jésù Krístì, Moses, Elias, àti Elijah wá bákannáà. Nípa ìdarí ti ọ̀run, àwọn wòlíì nlá ti ìgbàanì wọ̀nyí mú àwọn kọ́kọ́rọ́ àti àṣẹ oyè àlùfáà padàbọ̀sípò. Báyi, “àwọn kọ́kọ́rọ́ ti àkókò ìríjú yi ní a fi fúnni”22 láàrin Ìjọ Rẹ̀ tí a mú padàbọ̀sípò láti bùkún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.

Wíwá ti Elijah nínú Tẹ́mpìlì Kirtland bákannáà ṣe ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Málákì nínú Majẹ̀mu Láéláé pé Elijah yío padà wá “ṣaájú wíwá ti ọjọ́ nlá àti bíbanilẹ́rù ti Olúwa.”22 Ní síṣe bẹ́ẹ̀, ìfarahàn Elijah ṣẹlẹ̀ báramu, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí ṣe nípa síṣẹlẹ̀ báramu lásán, pẹ̀lú àkókò Àjọ Ìrẹ́kọjá ti àwọn Júù, àṣà èyítí ó nfi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ retí ìpadàbọ̀ Elijah.

Púpọ̀ àwọn ẹbí Júù olùfọkànsìn máa nfi ààyè sílẹ̀ fún Elijàh ní orí tábìlì Ìrékọjá wọn. Púpọ̀ wọn a bu ago kun dé etí láti pè àti láti kí i káàbọ̀ Àti pé àwọn míràn, ní ìgbà àṣà Ìrékọja Sẹ́dà, wọn a rán ọmọdé kan sí ibi ìlẹkùn, tí wọ́n máa nfi sílẹ̀ ní ṣíṣí díẹ̀ nígbàmíràn, láti wòó bóyá Elijah wà ní ìta fún pípè wọlé.24

Ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ àti bíi apákan ìmúpadàbọ̀ sípò àwọn ohun gbogbo tí a ṣe ìlérí,25 Elijàh wá bí a ti ṣe ilér/, ní ìgbà Ọdún Ajínde àti ní ìbẹ̀rẹ̀ Ajọ Irekọjjá. Ó mú àṣẹ fífi èdidi dì wá láti so àwọn ẹbí pọ̀ ní ilẹ̀ ayé àti ní ọ̀run. Bí Moronì ti kọ́ Wòlíì Joseph, Elijah “yío gbin àwọn ìlérí tí a ṣe fún àwọn baba sí inú ọkàn àwọn ọmọ, ọkàn àwọn ọmọ yío sì yí sí àwọn bàbá wọn. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀,” Moronì tẹ̀síwájú, “gbogbo ilẹ̀ ayé yío di fífi ṣòfò pátápátá ní bíbọ̀ rẹ̀ [ti Oluwa].”26 Ẹ̀mí Elijah náà, tí ó jẹ́ ìfarahàn ti Ẹmí Mímọ́, nfà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ìran wa—tí ó ti kọjá, ti ìsisìyí, àti ti ọjọ́ iwájú—nínú àwọn ìwádìí ẹbí, àwọn ìtàn, àti iṣẹ́ ìsìn tẹ́mpìlì.

Ẹ jẹ́kí a rántí ní ṣókí bákannáà ohun tí Ìrékọjá dúró fún. Ìrékọjá nṣe ìrántí ìtúsílẹ̀ àwọn ọmọ Israẹlì láti inú oko ẹrú irinwó ọdún. Ìwé Ẹksódù sọ bí ìtúsílẹ̀ yi ṣe wá lẹ́hìn àwọn àjàkálẹ̀ àrùn ti àwọn ọ̀pọ̀lọ́, iná orí, àwọn eṣinṣin, ikú ẹran ọ̀sìn, eéwo, ìléròrò, yínyín àti iná, àwọn eesú, àti òkùnkùn biribiri. Àjàkálẹ̀ àrùn ti ìgbẹ̀hìn sọ nípa ikú àkọ́bí ní ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n kìí ṣe nínú àwọn ìbùgbé ilé Israẹ́lì bí—bí àwọn ìdílé wọnnì bá fi ẹ̀jẹ̀ àkọ́bí àgùtàn tí kò ní àbàwọ́n sí ibi àtẹ́rígbà ẹnu ọ̀nà wọn.27

Angẹ́lì ikú kọjá lọ́ ní àwọn ilé tí a ṣe àmì sí pẹ̀lú àpẹrẹ ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùtàn náà.28 Kíkọjá náà, tàbí ríré kọjá, dúró fún bíborí ikú ti Jésù Krístì ní ìgbẹ̀hìn. Ní tòótọ́, ẹ̀jẹ̀ ètùtù ti Ọdọ́ àgùtàn Ọlọ́run fún Olùṣọ́ Àgùtàn Rere wa ní agbára láti kó àwọn ènìyàn Rẹ̀ jọ ní ibi àti ní ipò gbogbo sí inú ibi ààbò agbo Rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ti ìkele.

Ní pàtàkì, Ìwé ti Mọ́mọ́nì ṣe àpéjúwe “agbára àti àjinde Krístì”29—kókó Ọdún Àjínde—ní ti àwọn ìmúpadàbọ̀sípò méjì.

Ní àkọ́kọ́, àjínde ní ìmúpadàsípò àfojúrí sí “ipò dáradára àti pípé wa“ nínú; “gbogbo àwọn ẹ̀yà àti oríkẽ,“ “àní irun orí kan kì yíò sọnù.”30 Ìlérí yi fi ìrètí fún àwọn wọnnì tí wọ́n ti sọ àwọn ẹ̀yà ara nù, tí wọ́n ti sọ agbára láti ríran, láti gbọ́, tàbí lati rìn, tàbí àwọn wọnnì tí a rò pé wọ́n ti sọnù sínú àìsàn pípẹ́ títí, àìsà, ọpọlọ, tàbí àìpé ara míràn. Ó wá wa rí: Ó sọ wa di pípé.

Ìlérí kejì ti Ọdún Àjínde àti Ètùtù Olúwa wa ni pé “ohun gbogbo ni a ó múpadà sí ipò dáradára wọn.”30 Ìmúpadàsípò ti ẹ̀mí yí, nfi àwọn iṣẹ́ àti àwọn ìfẹ́ inú wa hàn. Bíi búrẹ́dì ní orí omi náà,32 ó ṣe imúpadà “èyíinì tí í ṣe rere,“ “òdodo,“ “títọ́,“ àti tí ó “kún fún àánú.“33 Abájọ tí wòlíì Almà lo ọ̀rọ̀ náà múpadàsípò ní ìgbà mejìlélógún34 bí ó ṣe nrọ̀wá láti “ṣe pẹ̀lú òtítọ́, láti dájọ́ pẹ̀lú òdodo, àti láti ṣe rere ní ìgbà gbogbo.”35

Nítorípé “Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé,”36 Ètùtù Olúwa le múpadàsípò kìí ṣe ohun tí ó wà tẹ́lẹ̀rí nìkan, ṣùgbọ́n ohun tí ó le wà. Nítorípé Ó mọ àwọn ìrora wa, àwọn ìpọ́njú, àwọn àìsàn, “àwọn àdánwò wa ní onírúurú,“37 Ó le ṣe àtìlẹ́hìn wa, pẹ̀lú àánú, ní ìbámu sí àwọn àìlera wa38 Nítorípé Ọlọ́run jẹ́ “pípé, Ọlọ́run títọ́, àti Ọlọ́run alãnú bákannáà,” èrò àánú le “pẹ̀tù sí ìbéèrè àìṣègbè.”39 A ronúpiwàdà a sì ṣe gbogbo èyítí a le ṣe. Ó yí wa ká títí ayérayé “nínú apá ìfẹ́ rẹ̀”40

Lóni a nṣe àjọyọ̀ ìmúpadàbọ̀sípò àti àjínde. Mo yọ̀ nínú mo sì jẹ́rìí nípa Ìmúpadàbọ̀sípò ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ti Jésù Krístì tí ó ntẹ̀síwájú. Bí ó ti bẹ̀rẹ̀ ní ọgọ́rũn méjì ọdún sẹ́hìn ní ìgbà ìrúwé yi, ìmọ́lẹ̀ àti ìfihàn tẹ̀síwájú láti jáde wá nípasẹ̀ wòlíì alààyè ti Olúwa àti Ìjọ Rẹ̀ tí a pè ní orúkọ Rẹ̀—Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn—àti nípasẹ̀ ìfihàn ara ẹni àti ìmísí láti ọ̀dọ̀ ẹ̀bùn gígajù ti Ẹmí Mímọ́.

Pẹ̀lú yín, ní àkókò Ọdún Àjínde yi, mo jẹ́ ẹ̀rí ti Ọlọ́run, Bàbá wa Ayérayé, àti Ọmọ Rẹ̀ Ọwọ́n, Jésù Krístì alààyè. Àwọn ènìyàn kíkú ni a pa ní ìpakúpa lórí igi agbélèbú àti ní ìkẹhìn a jí wọn dìde. Ṣùgbọ́n Jésù Krístì alààyè nìkan nínú àjínde pípé Rẹ̀ ni ó ní àwọn àpá ìkànmọ́ àgbélèbú ní ọwọ́, ẹsẹ̀, àti ìhà Rẹ̀. Òun nìkan ni Ó le sọ pé, “Èmi ti fín ọ́ sí orí àwọn àtẹ́lẹwọ́ mi.41 Òun nìkan ni Ó le sọ pé: “Èmi ni ẹni náà ti gbé sókè. Èmi ni Jésù Krístì tí a kàn mọ́ àgbélèbú. Èmi ni Ọmọ Ọlọ́run.”42

Bíi ti Ivy kékeré àti faolínì rẹ̀, àwa, ní àwọn ọ̀nà kan, ṣì ṣẹ̀ṣẹ̀ nbẹ̀rẹ̀ ni. Nítòótọ́, “ojú kò tíì rí, tàbí eti gbọ́, tàbí wọnú ọkàn ọmọ ènìyàn, àwọn ohun èyí tí Ọlọ́run ti pesè sílẹ̀ fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ rẹ.”43 Ní àwọn àkókò wọ̀nyí, a le kọ́ pùpọ̀ nípa ìṣerere Ọlọ́run àti agbára àtọ̀runwa fún ìfẹ́ ti Ọlọ́run láti dàgbà nínú wa bí a ṣe nwá A tí a sì nnawọ́ jáde sí ara wa. Ní àwọn ọ̀nà tuntun àti àwọn ibi tuntun, a le ṣe kí a sì dà, ìlà lórí ìlà, àánú lórí àánú, bíi ẹnìkọ̀ọ̀kan àti ní apapọ̀.

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n níbigbogbo, bí mo ṣe npàdé tí mo sì nkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àti láti ọ̀dọ̀ yín, mo kún fún ẹ̀mí ti ìrìnàjò ìhìnrere àti ìmoore. Ẹrí àti ìrinàjò ìhìnrere yín nfikún ẹ̀rí àti ìrinàjò ìhìnrere mi. Àwọn ànìyàn àti ayọ̀ yín, ìfẹ́ yín fún agbo ilé Ọlọ́run àti àwùjọ àwọn Ènìyàn Mímọ́, àti ìgbé ayé yín tí ó ní òye òtítọ́ àti ìmọ́lẹ̀ tí a mú padàbọ̀sípò, nmú kíkún ìhìnrere tí a mú padàbọ̀sípò temi pọ̀ síi, pẹ̀lú Jésù Krístì alààyè ní ọkàn rẹ̀. Ní àpapọ̀ a gbẹ́kẹ̀lé, “nínú ìkukù àti òòrùn, Olúwa, bá mi gbé.”44 Ní ìṣọ̀kan a mọ̀, ní ààrin àwọn ẹrù àti àníyàn wa, àwa le ka àwọn ọ̀pọ̀ ìbùkún wa.45 Nínú apákan àti kékeré àti ìrọ̀rùn àwọn ohun ojoojúmọ́, a le rí àwọn ohun nlá tí yío wá sí ìmúṣẹ nínú ayé wa.46

“Yío sì ṣe tí a ó kó àwọn olódodo jọ papọ̀ láti àwọn orílẹ̀ èdè, wọn ó sì wá sí Síonì, ní kíkọrin pẹ̀lú àwọn orin ayọ̀ àìlópin.”43 Ní àkókò hosanna àti halleluyàh yi, ẹ kọrin halleluyah—nítorí Òun yío jọba láé àti títí láéláé! Ẹ ké hosanna, sí Ọlọ́run àti Ọdọ́-àgùtàn náà Ní orúkọ mímọ́ àti mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín