Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Jíjádewá ti Ìwé Mọ́mọ́nì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Jíjádewá ti Ìwé Mọ́mọ́nì

Àwọn òtítọ́ inú ìtàn àti àwọn ẹlẹ́ri pàtàkì Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ri pé jíjádewá rẹ̀ jẹ́ yíyanilẹ́nu ní tõtọ́.

Nígbàtí ó npàdé pẹ̀lú àwọn alàgbà Ijọ ní àkókò kan, Wòlíì Joseph Smith sọ pé: “Ẹ mú Ìwé ti Mọ́mọ́nì kúrò, àti àwọn ìfihàn, níbo sì ni ẹ̀sìn wa wà? A kò ní ọ̀kankan.”1 Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, títẹ̀lé ìyanilẹ́nu ti jíjade wa ìwé ti Mọ́mọ́nì ni ọ̀nà abáyọ pàtàkì kejì ti nṣe àfihàn \Imúpadàbọ̀ sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì ní àkókò ìríjú yi ní títẹ̀lé Ìran Àkọ́kọ́. Ìwé ti Mọ́mọ́nì njẹri ìfẹ́ Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀, ti àìṣetara ẹni àti ẹbọ ètùtù síṣe àtọ̀runwá ti Olúwa Jésù Krístì, àti ti àṣeparí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ ní ààrin àwọn ènìyàn Néfì ní kété lẹ́hìn Àjínde Rẹ̀.2 Bákannáà ó jẹ́ri pé àwọn ìyókù ilé Israelì yío di ọ̀kan nípasẹ̀ iṣẹ́ ọjọ́-ìkẹhìn Rẹ̀ àti pé a kò sọ wọ́n nù títí láe.3

Bí a ti nṣe àṣàrò ti jíjáde wá ìwé mímọ́ ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yi ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí, a ri pé gbogbo ìdáwọ́lé náà jẹ́ yíyanilẹ́nu—láti ọ̀dọ̀ Wolíì Joseph ní gbígba àwọn àwo wúrà lati ọwọ́ angẹ́lì mímọ́ kan sí ìyírọ̀padà rẹ̀ nípa “ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run,”4 ìpamọ́ rẹ̀, àti títẹ̀ jáde nípa ọwọ́ Olúwa.

Jíjádewá ti Ìwé Mọ́mọ́nì bẹ̀rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ ṣaájú kí Joseph Smíth ó tó gba àwọn àwo wúrà láti ọwọ́ angẹ́lì Mórónì. Àwọn wòlíì ti ìgbàánì sọtẹ́lẹ̀ nípa wíwáyé ìwé mímọ́ yi ní àkókò tiwa.4 Isaiah sọ nípa ìwé kan tí a fi èdidi dì, pé nígbàtí yío fi ara hàn àwọn ènìyàn yío máa jà lórí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ipò yi yío pèsè àyíká nínú èyí tí Ọlọ́run ti le ṣe “iṣẹ́ ìyanu àti yíyanilẹ́nu” Rẹ̀, ní mímú “ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn wọn [kí ó] ṣègbé, àti òye ti àwọn àmòye ènìyàn wọn [kí ó] fi ara sin” nígbàtí àwọn onírẹ̀lẹ̀ yío “mú ayọ̀ wọn pọ̀ síi nínú Oluwa, àti àwọn òtòṣì ní ààrin àwọn ènìyàn yío yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ Israelì.”5 Ezekielì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pá ti Júdà (Bíbélì) àti ọ̀pá ti Ephraim (Ìwé ti Mọ́mọ́nì) ní mímú wọn papọ̀ bí ọ̀kan. Àwọn méjèèjì Ezekíelì (nínú Májẹ̀mu Láéláé) àti Léhì (nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì) tọ́ka sí pé wọn yío “dàgbà papọ̀” láti dààmú ẹ̀kọ́ èké, láti ṣe àgbékalẹ̀ àlàáfíà, àti láti múwa wá sí ìmọ̀ ti àwọn májẹ̀mú.6

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọkànlélógún Oṣù Kẹsãn, 1823, ọdun mẹ́ta àti àbọ̀ lẹ́hìn tí ó ní ìrírí Ìran Àkọ́kọ́, angẹ́lì Mórónì bẹ Joseph wò, wòlíì ìkẹhìn nínú àwọn ará Néfì ní Amẹ́ríkà àtijọ́, bi àyọrísí àwọn àdúrà àtọkànwá rẹ̀. Ní ìgbà àwọn àbẹ̀wò wọn tí ó gùn la òru náà já, Mórónì sọ fún Joseph pé Ọlọ́run ní iṣẹ́ yíyanilẹ́nu kan fún un láti ṣe yọrí—ìyírọ̀padà àti àtẹ̀jáde sí aráyé ti àwọn ọ̀rọ̀ ti àwọn wòlíì àtijọ́ ti ilẹ̀ Amẹríkà.7 Ní ọjọ́ kejì, Joseph lọ sí ibẹ̀, tí kò jìnnà sí ilé rẹ̀, ní ibití àwọn àwo náà wà ní bíbòmọ́lẹ̀ láti ọwọ́ Moronì ní òpin ayé rẹ̀, ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣaájú. Níbẹ̀ Joseph ri Mórónì lẹ́ẹ̀kansíi, ẹnití ó sọ fún un láti pèsè ara rẹ̀ sílẹ̀ láti gba àwọn àwo náà ní ọjọ́ iwájú.

Nínú ọdún mẹ́rin tí ó tẹ̀le, ní ọjọ́ kejìlélógún Oṣù Kẹsãn ọdún kọ̀ọ̀kan, Joseph gba àfikún àwọn ẹ̀kọ́ láti ọwọ́ Mórónì tí ó ní íṣe sí ìmọ̀ nípa bí a ti nílati ṣe àkóso ijọba Oluwa ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Ìmúrasílẹ̀ Joseph bákannáà ní àwọn àbẹ̀wò láti ọ̀dọ̀ àwọn angẹ́lì Ọlọ́run nínú, nípa bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ṣe àfihàn ọlánlá àti ògo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yío wáyé ní àkókò yi.8

Ìgbeyàwó rẹ̀ sí Emma Hale ní 1827 jẹ́ apákan ìmúrasílẹ̀ náà. Ó kó ipa pàtàkì ní ríran Wòlíì lọ́wọ́ jakèjádò ìgbé ayé àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀. Ní tòótọ́, ní Oṣù Kẹsãn 1827, Emma bá Joseph lọ sí orí òkè náà, ó sì dúró dè é bí angẹ́lì Mórónì ṣe gbé àkọsílẹ̀ náà lé Joseph lọ́wọ́. Joseph gba ìlérí pé àwọn àwo náà yío jẹ́ fífi pamọ́ bí òun bá ṣe gbogbo aápọn rẹ̀ láti pa wọ́n mọ́ nínu ààbò títí tí wọn ó fi jẹ́ dídá padà sí ọwọ́ Moronì.9

Ẹyin akẹgbẹ́ mi ọ̀wọ́n nínú ìhìnrere, púpọ̀ nínú àwọn àwárí òde òní láti inú àwọn ìgbà àtijọ́ nṣẹlẹ̀ nígbàtí wọ́n bá nwú ilẹ̀ fún ohun ìtàn kan, tàbí nípa kí ó ṣèèsì ní ìgbà ètò ìdàgbàsókè kan. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Joseph Smith ni a dárí sí ibi àwọn àwo náà nípasẹ̀ angẹ́lì kan. Àbájáde yi fúnra rẹ̀ jẹ́ ìyanu.

Ìlànà ìyírọ̀padà ti Ìwé Mọ́mọ́nì bákannáà jẹ́ ìyanu. Àkọsílẹ̀ mímọ́ ti ìgbà àtijọ́ yi ni a kò “ṣe ìyírọ̀padà” rẹ̀ ní ọ̀nà àṣà tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n yío fi ṣe ìyírọ̀padà àwọn ohun kíkọ ti ìgbà àtijọ́ nípa kíkọ́ èdè ti ìgbà àtijọ́. Ó yẹ kí a wo ìlànà náà bíi “ìfihàn” pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ohun èlò àfojúrí tí a pèsè láti ọwọ́ Olúwa tí ó tako “àyípadà-èdè” láti ọwọ́ ẹnití ó ní ìmọ̀ àwọn èdè. Joseph Smith sọ pé nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run, “mo ṣe ìyírọ̀padà Ìwé ti Mọ́mọ́nì láti inú àwọn àmì, ìmọ̀ èyítí ó ti sọnù sí ayé nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìyanú èyítí mo nìkan dá dúró, ọ̀dọ́ kan ti kò mọ ohunkóhun, láti dojú ìjà kọ ọgbọ́n ayé, àti àìmọkan púpọ̀ ti sẹ́ntíurì kejìdínlógún, pẹ̀lú ìfihàn titun.”10 Ìrànlọ́wọ́ Olúwa nínú àyípadà-èdè àwọn àwo náà—tàbí ìfihàn, kí a sọ bẹ́ẹ̀—hàn kedere bákannáà nígbàtí a bá ṣe àgbéyẹ̀wò ìyanu àkókò kúkúrú tí Joseph Smith lò láti ṣe àyípadà-èdè rẹ̀.11

Àwọn akọ̀wé Joseph jẹ́ri sí agbára Ọlọ́run tó fi ara hàn nígbàtí wọ́n nṣiṣẹ́ lóri àyípada-èdè Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Oliver Cowdery fi ìgbà kan sọ pé: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ọjọ́ náà tí a kì yío gbàgbé láe—láti jóko ní abẹ́ ìró ohùn kan tí a pè nípa ìmísíti Ọ̀run, ó ta ìmoore gígajùlọ ti inú àyà yí jí! Ọjọ́ lẹ́hìn ọjọ́, mo tẹ̀síwájú, láì sí ìdíwọ́, láti kọ̀wé láti ẹnu rẹ̀, bí ó ti nṣe àyípada-èdè … ’wé ti Mọ́mọ́nì.’”12

Àwọn orisun ti ìwé-ìtàn fihàn pé láti àkókò tí Joseph Smith ti gba àwọn àwo náà ní 1827, àwọn ìgbìdánwò ti jẹ́ síṣe láti jí wọn mọ́ ọ lọ́wọ́. Ó wòye pé “agbára tí ó le jùlọ di lílò láti gba [àwọn àwo] náà ní ọwọ́ [rẹ̀]” àti pé “gbogbo ète tí wọn le lò ni wọ́n yọrí sí fún èrò náà.”13 Lẹ́hìnwá Joseph àti Emma di fífi ipá mú láti kó kúrò ní Manchester, New York, sí Harmony, Pennsylvania, láti wá ibi tí ó ní ààbò láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú iṣẹ́ àyípada-èdè, kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn àgbájọ ọ̀pọ̀ èrò àti ẹnikọ̀ọ̀kan tí wọ́n fẹ́ jí àwọn àwo náà.14 Bí onkọ̀tàn kan ṣe kọ: “Báyi ni ìpele síṣòro àkọ́kọ́ ti pé Joseph jẹ́ olùtọ́jú lóri àwọn àwo náà parí. … Síbẹ̀ àwọn àkọsílẹ̀ náà wà ní ààbò, àti pé nínú àwọn ìjàkadì rẹ̀ láti pa wọ́n mọ́ laìsíyèméjì Joseph ti kọ́ ohun púpọ̀ nípa àwọn ọ̀nà Ọlọ́run àti ti ènìyàn tí yío tó fún un dáradára ní àwọn ìgbà tí ó nbọ̀.”15

Bí ó ti nṣe àyípada-èdè Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Joseph kọ́ pé Olúwa yío yan àwọn ẹlẹ́ri láti rí àwọn àwo náà.16 Èyí ni apákan ohun tí Oluwa Funra Rẹ̀ gbékalẹ̀ nígbàtí ó wípé, “Ní ẹnu àwọn ẹlẹ́ri méjì tàbí mẹ́ta a ó fi ìdí gbogbo ọ̀rọ̀ múlẹ̀.”17 Oliver Cowdery, David Whitmer, àti Martin Harris t wọ́n jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ojúgbà Joseph ní ìbẹ̀rẹ̀ nínú àgbékalẹ̀ iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run ní àkókò ìríjú yi, ni àwọn ẹlẹ́ri àkọ́kọ́ tí a pè láti jẹ́ àkànṣe ẹ̀rí nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì sí aráyé. Wọ́n jẹ́ ẹ̀rí pé angẹ́lì kan, ẹnití ó wá láti ọ̀dọ̀ Oluwa, fi àkọsílẹ̀ ìgbàanì náà hàn wọ́n, àti pé wọ́n rí ohun kíkọ náà tí a fín sí inú àwọn àwo náà. Bákannáà wọ́n jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n gbọ́ ohùn Ọlọ́run láti ọ̀run tí ó nkéde pé ìyírọ̀padà náà ni a ṣe nípa ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run. Lẹ́hìnnáà a pàṣẹ fún wọn láti jẹri nípa rẹ̀ sí gbogbo ayé.18

Pẹ̀lú ìyanu, Olúwa pe àwọn ẹlẹ́ri mẹ́jọ miràn láti rí àwọn àwo wúrà náà fúnra ara wọn àti láti jẹ́ àwọn ẹlẹ́ri pàtàkì nípa òtítọ́ àti jíjẹ́ àtọ̀runwá ti Ìwé Mọ́mọ́nì sí gbogbo aráyé. Wọ́n jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n rí wọ́n sì fi pẹ̀lú ìṣọ́ra ṣe àyẹ̀wò àwọn àwo náà àti àwọn ohun fífín rẹ̀. Àní ní ààrin àwọn ìpọ́njú, àwọn inúnibíni, gbogbo onírúurú àwọn ìṣòro, àní tí díẹ̀ nínú wọn sì nṣe ìyèméjì nínú ìgbàgbọ́ wọn níkẹhìn, àwọn àṣàyàn ẹlẹ́ri mọ́kànlá ti Ìwé Mọ́mọ́nì wọ̀nyí kò fi ìgbà kan sẹ́ ẹ̀rí wọn pé àwọn ti rí àwọn àwo náà. Joseph Smith kò nìkan wà mọ́ pẹ̀lú imọ̀ àbẹ̀wò Moroni àti àwọn àwo wúra naà.

Lucy Mack Smith kọ sílẹ̀ pé ọmọkùnrin rẹ̀ dé ilé pẹ̀lú ayọ̀ nlá lẹ́hìn tí àwọn àwo náà di fífihàn sí àwọn ẹlẹ́ri. Joseph ṣe àlàyé fún àwọn òbí rẹ̀ pé, “Mo ní ìmọ̀lára bí ẹnipé a gbé ẹrù kan kúrò ní ara mi èyítí ó fẹ́rẹ̀ wúwo jù fúnmi láti gbé, àti pé ó fi ayọ̀ fún ọkàn mi, pé èmi kò ní dá nìkan wà mọ́ nínú ayé.”19

Joseph Smith dojukọ ọ̀pọ̀ àtakò ní títẹ Ìwé ti Mọ́mọ́nì bí ìyírọ̀padà rẹ̀ ti wá sí ìparí. Ó ṣeéṣe fún un láti rọ ọkàn àtẹ̀wé kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Egbert B. Grandin ní Palmyra, New York, láti tẹ̀ ẹ́ ṣùgbọ́n ó jẹ́ lẹ́hìn tí Martin Harris, nínú ìṣe ti ìgbàgbọ́ àti irúbọ nla, fi pápá oko rẹ̀ sílẹ̀ bí ìdúró fún owó ìtẹ̀wé náà. Nítorí àtakò tí ó ntẹ̀síwájú ní ẹ̀gbẹ́ kan, lẹ́hìn títẹ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Martin Harris fi ìgbàgbọ́ ta ékà 151 (0.6 km2) nínú oko rẹ̀ láti san owó ìwé títẹ̀ náà. Nípasẹ̀ ìfihàn kan tí a fifún Joseph Smith, Oluwa sọ fún Martin Harris láti máṣe ṣe ojúkòkòrò ohun ìní rẹ̀, kí ó sì san owó ìwé títẹ̀ náà fún ìwé tí ó ní “òtítọ́ àti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú.”20 Ní Oṣù kẹta 1830, àwọn ìwé ẹgbẹ̀rún márũn àkọ́kọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì di títẹ̀ jáde, àti pé ní òní yi, ó lé ní ọgọ́sãn mlíọ̀nù ẹ̀dà tí a ti tẹ̀ ní àwọn èdè tí ó lé ní ọgọ́rũn kan

Àwọn òtítọ́ inú ìtàn àti àwọn ẹlẹ́ri pàtàkì Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ri pé jíjádewá rẹ̀ jẹ́ yíyanilẹ́nu ní tõtọ́. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, agbára ìwé yi kò dá lórí ìtàn títóbi rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n lóri ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó kún fún agbára tí kò sì ní ẹgbẹ́ tí ó ti yí àìmọye ìgbé ayé padà—àti tèmi pẹ̀lú!

Mo ka gbogbo Ìwé ti Mọ́mọ́nì fún ìgbà àkọ́kọ́ nígbàtí mo jẹ́ ọ̀dọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ti sẹ́nínárì. Bí a ti dábàá rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn olùkọ́ mi, mo dáwọ́lé kíkà rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ojú ewé ìdámọ̀. Ìlérí tí ó wà nínú àwọn ojú ewé àkọ́kọ́ ti ìwé náà ṣì ndún ní inú mi: “Ẹ ròó jìnlẹ̀ nínú ọkàn [yín] … nígbànáà … kí ẹ bèèrè ní ọwọ́ Ọlọ́run [nínú ìgbàgbọ́] … ní orúkọ Krístì bí iwé náà ba jẹ́ òtítọ́. Àwọn wọnnì tí wọ́n lépa ọ̀nà yí … yío jèrè ẹ̀rí òtitọ́ rẹ̀ àti àtọ̀runwá rẹ̀ nípasẹ̀ agbára Ẹmí Mimọ́”.21

Pẹ̀lú ìlérí náà ní ọkàn ní fífi ìtara wá láti mọ̀ síi nípa òtítọ́ rẹ̀, àti nínú ẹ̀mí àdúrà, mo ṣe àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì, díẹ̀ díẹ̀, bí mo bá ti parí àwọn ẹ̀kọ́ yíyàn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti sẹ́mínárì. Mo rántí, bíi pé àná ni, pé ìmọ̀lára rere kan bẹ̀rẹ̀ sí wú ní inú mi tí ó sì nkún ọkàn mi, tí ó ntan ìmọ́lẹ̀ sí òye mi, tí ó sì nwuni síwájú àti síwájú síi, bí Almà ti ṣe àpèjúwe nínú ìwàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí àwọn ènìyàn rẹ̀.23 Ìmọ̀lára yi yípadà ní ìgbẹ̀hìn sí ìmọ̀ tí ó ní gbòngbò nínú ọkàn mi tí ó sì di ìpìlẹ̀ ẹ̀rí mi nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì àti àwọn ìkọ́ni tí a rí nínú ìwé mímọ́ yi.

Nípasẹ̀ ìwọ̀nyí àti àwọn ìrírí àìdíyelé ti ara ẹni, ní tòótọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì di okúta-pàtàkì tí ó mú ìgbàgbọ́ mi ró nínú Jésù Krístì àti ẹ̀rí mi nípa ẹ̀kọ́ ti ìhìnrere Rẹ̀. Ó di ọ̀kan lára àwọn òpó tí ó njẹ́ ẹ̀rí sí mi nípa ìrúbọ ètùtù àtọ́runwa ti Krístì. Ó di ààbò ní gbogbo ayé mi ní ìlòdì sí ìgbìyànjú ọ̀tá láti rẹ ìgbàgbọ́ mi sílẹ̀ àti láti fi àìgbàgbọ́ nínú mi àti fífún mi ní ìgboyà láti kéde ẹ̀rí mi nípa Olùgbàlà sí ayé.

Ẹyin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ̀rí mi nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì wá ní ìlà lórí ìlà22 bíi iṣẹ́ ìyanu sí ọkàn mi. Títí di òní yi, ẹ̀rí náà ntẹ̀síwájú láti máa dàgbà bí mo ti ntẹ̀síwájú ní wíwá, pẹ̀lú ọkàn òtítọ́, láti ní òye ọ̀rọ̀ Ọlọ́run síi ní kíkún síi bí ó ti wà nínú ìwé pàtàkì ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yìí.

Sí gbogbo ẹni tí ó gbọ́ ohùn mi lóni, mo pè yín láti di ara ìyanu jíjádewa ti Ìwé Mọ́mọ́nì nínú ìgbé ayé tiyín Mo ṣe ìlérí fún yín pé bí ẹ ti nṣe àṣàrò àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà àti ìtẹramọ́, ẹ le ní ìpín nínú àwọn ìlérí àti àwọn ìbùkún alárinrin rẹ̀ nínú ayé yín. Mo fi ẹsẹ̀ ilérí tí ó dún nípasẹ̀ àwọn ojú ewé ìwé rẹ̀ múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kasíi: pé bí ẹ̀yin bá “bẽrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, ní orukọ Krístí, bí àwọn ohun wọ̀nyí kò bá í ṣe òtítọ́; bí ẹ̀yin bá sì bẽrè, tọkàn-tọkàn pẹ̀lú gbogbo ìfẹ́ inú yín, níní ìgbàgbọ́ nínú Krístì,“ Òun yíò fi tàánútàánú “fi òtítọ́ inú rẹ̀ hàn sí yín, nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ̀.“24 Mo le fi da yín lójú pé Òun yío fún yín ní ìdáhùn ní ọ̀nà ti ara ẹni gãn, bí Òun ti ṣe fúnmi àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlòmíràn yíká gbogbo ayé. Ìrírí yín yío jẹ́ ológo àti mímọ́ fún yín bí àwọn ìrírí ti Joseph Smith ti jẹ́ fún un, àti bí ó ti rí fún àwọn ẹlẹ́rí àkọ́kọ́, àti fún gbogbo àwọn tí wọ́n ti lépa lati gba ẹ̀rí kan nípa jíjẹ́ àìlábùkù àti yíyẹ-fún-ìgbẹ́kẹ̀lé ti ìwé mímọ́ yi.

Mo jẹ́ ẹ̀rí mi pé Ìwé Ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nítòótọ́.” Mo jẹ́rìí pé àkọsílẹ̀ mímọ́ yi “gbé àwọn ẹ̀kọ́ ti ìhìnrere sí iwájú, ó la èrò ìgbàlà kalẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ènìyàn ohun tí wọ́n gbọdọ̀ ṣe láti ní alaáfíà nínú ayé yi àti ìgbàlà ayérayé ní ayé tí nbọ̀.“25 Mo jẹ́rìí pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni ohun èlò Ọlọ́run ni láti mú ìkójọ Israẹ́lì wá sí ìmúṣẹ ní àkókò wa, àti láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti mọ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run wà láàyè Ó sì fẹ́ràn wa àti pé Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ni Olùgbàlà aráyé, okúta igun pàtàkì ti ẹ̀sìn wa. Mo sì sọ àwọn ohun wọ̀nyí ni orúkọ mímọ́ Olùràpadà wa, Alákòóso wa, àti Olúwa wa, àní Jésù Krístì, àmín.