Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Ibùgbé Dídára Jùlọ
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Àwọn Ibùgbé Dídára Jùlọ

Olùgbàlà ni onimọ̀-ẹ̀rọ, olùkọ́lé, àti atúnú-ilé ṣe pípé. Iṣẹ́ Rẹ̀ ni ìsọdipípé àti ayọ̀ ayérayé ti ẹ̀mí wa.

Ní àìpẹ́ yi pátákó ìpolowó ọjà kan mú àkíyèsí me. Ó polowó ile iṣẹ́ kan tí nṣe àwọn ohun ọ̀ṣọ́ inú ilé. Ó kàn rọra sọ pé, “A nṣiṣẹ́ fún Àwọn Ibùgbé Dídára Jùlọ ní Salt Lake City.”

Ọrọ̀ náà wọni lára—kínni “ibùgbé dídára jùlọ kan”? Mo rí ara mi ní ríronú nípa ìbéèrè n.aà, ní pàtàkì bí ó ti ní í ṣe sí àwọn ọmọ tí ìyàwó mi, Kathy, àti èmi tọ́ dàgbà àti àwọn ọmọ tí àwọn náà ntọ́ lọ́wọ́ lóni. Bíi ti àwọn òbí níbigbogbo, a nṣe àníyàn nípa àwọn ẹbí wa a sì ngbàdúrà lórí wọn. A sì nṣe bẹ́ẹ̀. A fi pẹ̀lú ìtara fẹ́ ohun dídára jùlọ fún wọn. Báwo ni àwọn àti àwọn ọmọ wọn ti lè gbé nínú àwọn Ibùgbé dídára jùlọ? Mo ti ronú lóri àwọn ìbùgbé àwọn ọmọ Ìjọ tí Kathy àti èmi ti ní ànfààní láti bẹ̀wò. Wọ́n ti pè wá sí àwọn ìbùgbé ní Korea àti Kenya, ní ti àwọn Philippine àti Peru, ní Laos àti Latvia. Ẹ jẹ́kí nṣe àbápín àwọn àkíyèsí mẹ́rin nípa àwọn ìbùgbé dídára.

Ní àkọ́kọ́, làti inú ìwòye ti Olúwa, síṣe àgbékalẹ̀ àwọn Ibùgbé dídára jùlọ ní ohun gbogbo í ṣe pẹ̀lú yíyẹ ti ara ẹni láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ngbé níbẹ̀. A kò ṣe àwọn ibùgbé wọ̀nyí ní dídára ní èyíkéyi ọ̀nà pàtàkì tàbí tí yío pẹ́ títí kan nípa àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wọn tàbí ipò tí àwọn ènìyàn tí ó ni wọ́n wà ní àwùjọ. Àpèjúwe dídára jùlọ ti èyíkéyí ibùgbé ni àwòrán Kristì tí ó fi ara hàn nínú àwọn olùgbé ibùgbé náà. Ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni títú-inú ti ọkàn àwọn olùgbé ṣe, kìí ṣe ti ìkọ́lé funrarẹ̀.

Àwọn ìwà ti Krístì wọ̀nyí ni a máa nní ní àwọn “ìpele àkókò”1 nípa mímọ̀ọ̀mọ́ ìtẹ̀síwájú ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú. Àwọn ìwà bíi ti Krístì nṣe ìgbé ayé àwọn wọnnì tí wọ́n ntiraka láti gbé pẹ̀lú ìṣerere lọ́ṣọ̀ọ́. Wọ́n nkún àwọn ibùgbé pẹ̀lú ìmọ́lè ìhìnrere, bóyá ilẹ̀ rẹ̀ jẹ́ eruku tàbí mábù. Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìwọ nìkan ní agbo ilé yín tí ó ntẹ̀lé àṣẹ láti “wá àwọn ohun wọ̀nyí,”2 o le lọ́wọ́ sí síṣe àwọn ọ̀ṣọ́ ti ẹmí ní ibùgbé ẹbí rẹ.

A ntẹ̀lé ìmọ̀ràn Olúwa láti “ṣe ètò [ara wa]; ẹ pèsè olúkúlúkù ohun tí ẹ nílò; kí ẹ sì gbé ilé kan kalẹ̀” nípa síṣe ètò, pípèsè, àti gbígbé kalẹ̀ ìgbé ayé wa nípa ti ẹ̀mi, kìí ṣe àwọn ilé àti ilẹ̀ wa. Bí a ti nfi sùúrù lé ipa ọ̀nà májẹ̀mú ti Oluwa, ibùgbé wa ndi “ilé ògo, ilé elétò, [àti] ilé Ọlọ́run.”2

Èkejì, àwọn olùgbé inú inú àwọn ìbùgbé dídára jùlọ nfi àkókò sílẹ̀ láti ṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì alààyè ní ojoojúmọ́. Ààrẹ̀ Russell M. Nelson ti pè wá láti “yípadà” àti “tún àwọn ibùgbé wa ṣe” nípasẹ̀ àṣàrò ìwé mímọ́.3 Ìfipè rẹ̀ dáa mọ̀ pé àwọn ibùgbé dídára máa njẹ́ ilé fún ìfẹ́ni, kókó iṣẹ́ ìdàgbàsókè ara ẹni àti síṣe àtúnṣe àwọn àìlera wa. Ìrònúpìwàdà ojoojúmọ́ ni irinṣẹ́ ìyípadà tí ó nmú kí ó ṣeéṣe fúnwa láti ní inúrere díẹ̀ síi, láti fẹ́ni díẹ̀ síi, àti láti ní òye díẹ̀ síi. Síṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ nmú wa súnmọ́ Olùgbàlà díẹ̀ síi, ẹnití ọ̀pọ̀ ìfẹ́ àti oore ọ̀fẹ́ rẹ̀ nrànwá lọ́wọ́ pẹ̀lú ìdàgbàsókè wa.

Bíbélì, Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Píẹ̀lì Iyebíye Nlá sọ ìtàn ti àwọn ẹbí, nítorínáàkò yani lẹ́nu pé àwọn àtọ̀runwá wọnnì jẹ́ ìwé ìléwọ́ tí kò ní àfiwé fún síṣe àgbékalẹ̀ àwọn ibùgbé dídára jùlọ. Wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ àdúrà àwọn obí, àwọn ewu ti àdánwò, ìṣẹ́gun ti òdodo, àwọn ìdojúkọ ti ìyàn àti ọ̀pọ̀, ìrírí ikú àti síṣe ọ̀fọ̀, àti àwọn ẹ̀rù ogun àti èrè alàáfíà. Lẹ́ẹ̀kansíi àti lẹ́ẹ̀kansíi àwọn ìwé mímọ́ nfihàn wá bí àwọn òbí ti nṣe oríire nípasẹ̀ ìgbé ayé òdodo àti bí wọ́n ti nkùnà nípa títẹ̀lé àwọn ipa ọ̀nà míràn.

Ìkẹta, àwọn ibùgbé dídára ntẹ̀lé èrò tí a ṣe láti ọwọ́ Olúwa fún ibùgbé dídára jùlọ Rẹ̀, tẹ́mpìlì. Tẹ́mpìlì kíkọ́ nbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìgbésẹ̀ àkọ́bẹ̀rẹ̀—igbó síṣán àti mímú ilẹ̀ tẹ́ pẹrẹsẹ. Àwọn aápọn ìbẹ̀rẹ̀ wọnnì láti pèsè ilẹ̀ náà ni a le fi wé pípa àwọn òfin àkọ́bẹ̀rẹ̀ mọ́. Àwọn òfin náà ni ìpìlẹ̀ èyítí a kọ́ jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn lé lórí. Dídúró nínú jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn ndarí wa sí dídà líle, dídúróṣinṣin, àti àìleyẹsẹ̀,4 bíi ti àwòrán irin fún tẹ́mpìlì kan. Àwòrán dídúróṣinṣin yi nfi ààyè fún Olúwa láti rán Ẹ̀mí Rẹ̀ láti yí ọkàn wa padà.5 Níní ìrírí ìyípadà ọkàn nlá dà bíi àfíkún àwọn ohun ẹlẹ́wà sí inú tẹ́mpìlì náa.

Bí a ti ntẹ̀síwájú nínú ìgbàgbọ́, Olúwa nyíwa padà díẹ̀díẹ̀. A ngba àwòrán Rẹ̀ ní ìwò ojú wa a sì nbẹ̀rẹ̀ láti fi ìfẹ́ àti ẹwà ìhùwàsí Rẹ̀.6 Bí a ti ndàbí Rẹ̀, a ó ní ìmọ̀lára wíwà ní ibùgbé nínú ilé Rẹ̀, Òun ó sì ní ìmọ̀lára wíwà ní ibùgbé nínú tiwa.

A lè ṣe ìmúdúró àsopọ̀ tímọ́tímọ́ ti ibùgbé wa sí ibùgbé Rẹ̀ nípa yíyẹ fún àti lílo ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì ní léraléra bí àwọn ipò wa ba ti fi ààyè sílẹ̀. Bí a ti nṣe bẹ́ẹ̀, ìjẹ́ mímọ́ ti ilé Olúwa nsinmi sí inú ilé tiwa náà.

Títóbí Tẹ́mpílì Salt Lake dúró nítòsí. Tí a kọ́ láti ọwọ́ àwọn aṣaájú pẹ̀lú àwọn irinṣẹ́ alákọbẹ̀rẹ̀, àwọn ohun èlò abẹ́lé, àti àìlópin iṣẹ́ àṣekára, tẹ́mpìlì náà di kíkọ́ láti 1853 sí 1893. Dídára jùlọ tí àwọn ọmọ Ìjọ ní láti fi lélẹ̀ ní ti ìmọ̀ ẹ̀rọ, yíya àwòrán ilé, àti ètò inú ilé mú iṣẹ́ pàtàkì kan jáde tí ó jẹ́ dídámò sí àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún èniyàn.

Ó ti fẹ́rẹ̀ tó ọgọ́rũn àti ọgbọ̀n ọdún tí ó ti kọjá láti ìgbà tí a ti ya tẹ́mpìlì náà sí mímọ́. Bí Alàgbà Gary E. Stevenson ti ṣàkíyèsí lana, àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìmọ̀ ẹrọ tí a lò láti ya àwòrán tẹ́mpìlì náà ni a ti pààrọ̀ sí èyítí ó tuntun tí ó sì ní ààbò síi. Kíkùnà láti ṣe ìgbésókè iṣẹ́ ẹ̀rọ àti àtúnṣe àwọn àìlera àwọn ìmúdúró tẹ́mpìlì náà yío dalẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé àwọn aṣaájú náà, tí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n le ṣe tí wọ́n sì fi ìtọ́jú tẹ́mpìlì náà sílẹ̀ fún àwọn ìran àtẹ̀lé.

Ìjọ ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìmúpadàbọ̀sípò síṣe ọlọ́dún-mẹ́rin láti mú agbára imúdúró tẹ́mpìlì náà dára síi.8 Ìpìlẹ̀, àwọn ilẹ̀ ayíká, àti àwọn ògiri ni a ó ró ní agbára síi. Ìmọ̀ ẹ̀rọ tí ó dára jùlọ tí ó wà ní àrọ́wọ́tó lóni yío mú tẹ́mpìlì náà bá ìgbà mu. A kò ní le fi ojú rí àwọn àyípadà ìmúdúró náà, ṣùgbọ́n àwọn abájáde wọn yío jẹ́ òtítọ́ àti pàtàkì. Nínú gbogbo iṣẹ́ yi, àwọn àwòrán rírẹwà bí inú tẹ́mpìlì náà ti wà ní a ó pa mọ́.

A nílati tẹ̀lé àpẹrẹ tí a fifún wa nípasẹ̀ Tẹ́mpìlì Salt Lake kí a sì mú àkókò láti ṣe àgbéyẹ̀wò ìmọ̀ ẹ̀rọ ti ẹ̀mí tiwa bíi ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ríi dájú pé ó bá ìgbà mu. Àgbéyẹ̀wò ara ẹni ní ẹ̀kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú bíbèrè lọ́wọ́ Olúwa, “Kínni mo ṣe aláìní síbẹ̀?”7 le ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ibùgbé dídára jùlọ

Ìkẹrin, àwọn ibùgbé dídára jẹ́ ibi ìsádi latinu àwọn ìjì ayé. Olúwa ti ṣe ìlérí pé àwọn wọnnì tí wọ́n pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ yíò “ṣe rere lórí ilẹ̀ náà.”8 Síṣe rere ti Ọlọ́run ni agbára láti tẹ̀síwájú láìka àwọn wàhálà ayé sí.

Ní 2002 mo kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nípa àwọn wàhálà. Nígbàtí mo wà ní Asunción, Paraguay, mo pàdé pẹ̀lú àwọn ààrẹ èèkàn ní ilú náà. Ní àkókò náà, Paraguay dojúkọ ìṣoro ètò ìṣúná owó tí ó le, púpọ̀ àwọn ọmọ Ìjọ sì njìyà tí wọn kò sì le ṣe àwọn ojúṣe. Èmi kò tíì lọ sí Gúsù Amẹ́ríkà láti ìgbà mísọ̀n mi èmi kò sì tíì lọ sí Paraguay. Mo ti nṣe iṣẹ́ ìsìn ní Àgbègbè Àjọ Ààrẹ náà fún àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ péré. Ní síṣe àníyàn nípa àìlágbára mi láti pèsè ìtọ́nisọ́nà fún àwọn ààrẹ èèkàn wọnnì, mo béèrè pé kí wọn ó sọ ohun tí ó nlọ déédé ní àwọn èèkàn wọn fúnmi. Ààrẹ èèkàn àkọ́kọ́ sọ fúnmi nípa àwọn ohun tí nlọ déédé. Èyítí ó tẹ̀lé sọ àwọn ohun tí nlọ déédé àti àwọn wàhálà díẹ̀. Nígbàtí a dé ọ̀dọ̀ ààrẹ èèkàn tí ó gbẹ̀hìn, ó kan sọ oríṣiríṣi àwọn ìpèníjà tí ó nbini nínú nìkan. Bí àwọn ààrẹ èèkàn náà ti ṣe àlàyé bí ipò náà ti tóbi tó, mo nní àníyàn púpọ̀ síi, tí ó ti súnmọ́ àìnírètí, nípa ohun tí èmi ó xọ.

Gẹ́gẹ́bí ààrẹ èèkàn ṣe nparí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, èrò kán wá sínú mi: Alàgbà Clayton, bi wọ́n ní ìbéèrè yi: ‘Ẹyin ààrẹ, nínú àwọn ọmọ ijọ ní àwọn èèkan yín tí wọ́n nsan ìdámẹ́wàá ní kíkún, nsan ọ̀pọ̀ ọrẹ ààwẹ̀, nmú ìpè wọn nínú ijọ tóbi, tí wọ́n nbẹ̀ àwọn ẹbí wọn wò bíi olùkóni ní ilé tàbí abẹníwò kíkọ́ni9 ní oṣooṣù, tí wọ́n nṣe ìpàdé ẹbí nírọ̀lẹ́, nṣe àṣàrò ìwé mímọ́, àti tí wọn nṣé àdúrà ẹbí ní ojoojúmọ́, mélo nínú wọn ní ó ní wàhálà tí wọn kò le yanjú funra wọn láìjẹ́pé Ìjọ níláti dá síi kí wọn ó sì yanjú àwọn ìṣòro náà fún wọn?’”

Ní dídáhùn sí àtẹ̀mọ́ra tí mo ti gbà, mo bi àwọn ààrẹ èèkan ní ìbéérè that issue/

W/ọ́n wò mí pẹ̀lú ìdákẹ́rọ́rọ́ tí ó ní ìyanu àti lẹ́hìnnáà wọ́n sọ pé, “Pues, ninguno,” tí ó túmọ̀sí, “Ó dára, kò sí ọ̀kankan.” Lẹ́hìnnáà wọ́n sọ fúnmi pé kò sí ọ̀kankan nínú àwọn ọmọ ìjọ tí ó ṣe gbogbo àwọn ohun wọnnì tí ó ní àwọn ìṣòro ti wọn kò ní agbára láti yanjú fúnra ara wọn. Kínni ìdí? Nítoripé wọ́n ngbé nínú àwọn Ibùgbé dídára jùlọ. Ìgbé ayé ìgbàgbọ́ wọn pèsè okun, ìran, àti ìrànlọ́wọ́ ti ọ̀run tí wọ́n nílò nínú wàhálà ètò ọrọ̀ ajé tí ó yí wọn ká.

Èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn olódodo kò ní ṣe àìsàn, jìyà ìjànbá, dojúkọ àjórẹ̀hìn etò oko òwò, tàbí ní ìpèníjà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣòro míràn nínú ayé, Ayé kíkú nfi ìgbàgbogbo mú àwọn ìdojúkọ wa, ṣùgbọ́n àkókò lẹ́hìn àkókò mo ti ríi pé àwọn wọnnì tí wọ́n ntiraka láti gbọ́ràn sí àwọn òfin máa nní ìbùkún láti rí ọ̀nà wọn síwájú pẹ̀lú àlàáfíà àti ìrètí. Àwọn ìbùkún wọnnì wà fún ẹni gbogbo.10

Dafidì kéde pé, “Bíkòṣepé Olúwa kọ́ ilé náà, àwọn tí wọ́n kọ nṣiṣẹ́ lásán.”11 Ní ibikíbi tí ẹ ngbé, ohunkóhun tí ilé yín fi ìwò jọ, àti bí ó ti wù kí àkójọpọ̀ ẹbí yín jẹ́, ẹ le kọ́ ibùgbé dídára jùlọ fún ẹbí yín. Ìhìnrere Jésu Krístì tí a múpadàbọ̀sípò npèsè àwọn èrò fún ibùgbé náà. Olùgbàlà ni onimọ̀-ẹ̀rọ, olùkọ́lé, àti ayàwòrán- inú-ilé tí ó pé. Iṣẹ́ Rẹ̀ ni ìsọdipípé àti ayọ̀ ayérayé ti ọkàn wa. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìfẹ́ni Rẹ̀, ọkàn yín le da gbogbo ohun tí Ó fẹ́ ẹ láti dà, ẹ̀yin sì le da ẹ̀dà dídára jùlọ gãn ti ara yín, múrasílẹ̀ láti gbékalẹ̀ àti láti gbé ibùgbé dídára jùlọ kan.

Mo fi pẹ̀lú ìmoore jẹ́rìí pé Ọlọ́run náà àti Baba gbogbo wa wà ní ààyè. Ọmọ Rẹ̀, Oluwa Jésù Krístì, ni Olùgbàlà àti Olùràpadà gbogbo ẹ̀dá ènìyàn. Wọ́n fẹ́ràn wa ní pípé. Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn jẹ́ ìjọba Ọlọ́run ní orí ilẹ̀ ayé. Àwọn wòlíì alààyè àti àwọn àpọ́stélì ntọ́ ọ lóni. Ìwé Ti Mọ́mọ́nì jẹ́ òtítọ́. Ìhìnrere Jésu Krístì tí a múpadàbọ̀sípò ni àmì pípé fún gbígbé ní àwọn ibùgbé dídárajùlọ̀. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Mósè7:21

  2. Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ 1:13.

  3. Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 88:119.

  4. Wo Russell M. Nelson, “Dída Àpẹrẹ Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn,” Liahona, Nov. 2018, 113.

  5. Wo 1 Nífáì 2:10; Mòsíàh 5:15; 3 Nífáì 6:14 Owuro.

  6. Wo Mòsíàh 5: 2; Álmà 5:7.

  7. Wo Alma 5:14.

  8. Ìṣẹ́lẹ̀ kan ní Ọjọ́ Kejìdínlógún Oṣù Kẹta, 2020, júwe ìnílò gan láti ṣe iṣẹ́ náa.

  9. Matteu19:20.

  10. Mòsíàh 2:22.

  11. Home teaching and visiting teaching were retired and ministering was implemented in 2018 (see Russell M. Nelson, “Ministering,” Làíhónà May 2018, 100).

  12. Nígbàtí a bá yàn láti máṣe gbé ìgbé ayé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin, nígbànáà àwọn ìbùkún Olúwa yíò fà sẹ́hìn dé àwọn ààyè kan. Àwòṣe tó nṣẹlẹ̀ padà tí a rí nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni à nfi ìgbàmíràn tọ́kasí bí àyíká àdodo àti ìkà (wo Book of Mormon Student Manual [Church Educational System manual, 2009], 414, ChurchofJesusChrist.org).

  13. OrinDáfídì 127:1.