Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Alààyè Ẹlẹ́ri kan ti Krístì Alààyè
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Alààyè Ẹlẹ́ri kan ti Krístì Alààyè

Kókó ọ̀rọ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni láti mú ìmọ̀ òtítọ́ ti pàtàkì ipa Jésù Krístì nínú ìgbàlà àti ìgbéga ẹ̀dá ènìyàn padà bọ̀ sípò.

Ní ọjọ́ kan tí òòrùn mú ní ìgbà ìrúwé ní 2017, ìṣílé fún Tẹ́mpìlì Paris France nlọ dáradára nígbàti ọkùnrin kan tọ ọ̀kan lára àwọn afinimọ̀nà lọ pẹ̀lú ìwò ìbànújẹ́ ní ojú rẹ̀. Ó sọ pé òun ngbé ní ilé kejì sí tẹ́mpìlì náà ó sì gbà pé òun ti jẹ́ alátakò gidi sí kíkọ́ rẹ̀. Ó sọ pé ní ọjọ́ kan, bí òun ti nwò òde ní ojú fèrèsé ibi ibùgbé rẹ̀, ó ri bí ẹrọ akẹ́rù kan ti sọ àwòrán Jésù kalẹ̀ láti ọ̀run tí ó sì gbé e kalẹ̀ jẹ́jẹ́ sí orí ilẹ̀ tẹ́mpìlì náà. Ọkùnrin náà wí pé ìrírí yìí mú ìyàtọ̀ bá àwọn ìmọ̀lárá òun sí Ijọ̀ wa pátápátá. Ó mọ̀ pé a jẹ́ àtẹ̀lé Jésù Krístì, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì wa fún ìdíwọ́ àtẹ̀hìnwá tí òun le ti fà.

Àwòrán
Ère tí a gbé sí Tẹ́mpìlì Paris France

Àwòrán ti Krístù náà, èyítí ó ṣe ilẹ̀ Tẹ́mpìlì Paris àti àwọn ohun ìní miràn ti Ìjọ ní ọ̀ṣọ́, njẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ wa fún Olùgbàlà. Ojúlówó àwòrán náà ti a fi mábù ṣe jẹ́ iṣẹ́ oniṣẹ́ ọ̀nà ilẹ̀ Danishì kan Bertel Thorvaldsen, ẹnití ó ṣe iṣẹ́ ọnà rẹ̀ ní 1820—ọdún kannáà bíi ti Ìran Àkọ́kọ́. Àwòrán náà dúró yàtọ̀ ní àìrújú sí púpọ̀ àwọn iṣẹ́ ọnà síṣe ti àkókò náà, èyítí ó ṣáàbà máa nṣe àfihàn Krístì tí njìyà ní orí àgbélébũ. Iṣẹ́ Thorvaldsen ṣe àgbékalẹ̀ Krístì alààyè, ẹnití ó gba ìṣẹ́gun ní orí ikú àti, pẹ̀lú ọwọ́ síṣí sílẹ̀, npe gbogbo ènìyàn láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ǎwọn ojú àpá ìṣó ni ọwọ́ àti ẹsẹ̀ Rẹ̀ àti ọgbẹ́ ní ìhà Rẹ̀ nikan jẹ́ ẹ̀rí nípa ìrora tí kò ṣeé júwe tí Ó fi ara dà láti gba gbogbo ẹdá ènìyàn là.

Àwòrán
Ọwọ́ Olùgbàlà bí a ṣe fihàn nínú Krístọ́s náà

Bóyá ìdí kan tí àwa bíi ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ikẹhìn fi fẹ́ràn àwòrán yi ni pé ó nrán wa létí nípa àpèjúwe tí a fi fúnni nínú Ìwé Ti Mọ́mọ́nì nípa ìfarahàn Olùgbàlà ní ìpínlẹ̀ Amẹ́ríkà:

Àwòrán
Jésù Krístì bẹ àwọn Amẹ́ríkà wò

“Sì kíyèsíi, wọ́n rí Ọkùnrin kan, tí ó nsọkalẹ̀ jáde láti ọ̀run; a sì wọ̀ ọ́ ní ẹ̀wù funfun kan; ó sì sọ̀kalẹ̀ wá ó sì dúró ní ààrin wọn. …

“Ó sì ṣe tí ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí wọn tí ó sì bá àwọn ènìyàn náà sọ̀rọ̀, wípé:

“Ẹ kíyèsĩ, èmi ni Jésù Krístì, …

“… Èmi sì ti mu nínú ago kíkòrò èyítí Bàbá ti fifún mi, mo sì ti ṣe Bàbá lógo ní gbígba àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé sí ara mi.”1

Nígbànáà Ó pe olukúlùkù ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé láti jáde wá kí wọn ó sì fi ọwọ́ wọn sí ẹ̀gbẹ́ Rẹ̀ kí wọn ó sì ní ìmọ̀lára àwọn àpá ìṣó ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀ Rẹ̀, nípa bẹ́ẹ̀ kí wọn ó le gba ẹ̀rí ti araẹni pé ní tòótọ́ Òun ni Mèssiah náà tí a ti ndúró dè fún ìgbà pípẹ́.2

Abala rírẹwà yi ni ìpele gígajù nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Gbogbo “ìròhìn rere” ti ìhìnrere ni ó wà nínú àwòrán Olùgbàla yí, tí ó nna “ọwọ́ àánú” Rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ni3 láti pe olukúlùkù ẹnikọ̀ọ̀kan láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ kí wọn ó sì gba àwọn ìbùkún ti Ètùtù Rẹ̀.

Kókó ọ̀rọ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni láti mú ìmọ̀ òtítọ́ ti pàtàkì ipa Jésù Krístì nínú ìgbàlà àti ìgbéga ẹ̀dá ènìyàn padà bọ̀ sípò. Àkórí yi njẹyọ láti ojú ewé ìdámọ̀ títí dé àwọn ọ̀rọ̀ tí ó parí gan ní orí tí ó gbẹ̀hìn. Ní ààrin àwọn ìgbà ìyapa kúrò nínú òtítọ́ àti ìdárúdàpọ̀ ti ẹ̀mí, ìjìnlẹ̀ ìtumọ̀ nípa ohun tí Krístì ṣe ní Getsemánì àti ní orí Golgotà di sísọnù àti bíbàjẹ́. Báwo ni ìdùnnú tí Joseph Smith ní ìmọ̀lára rẹ̀ yío ti tó nígbàtí, bí ó ti nṣe ìyírọ̀padà 1 Néfì, ó ṣe àbápàdé ìlérí ìyanu yi: “Àwọn ìwé ìrántí ìkẹhìn wọ̀nyí, [Ìwé ti Mọ́mọ́nì] … Yíò fi ìdí òtítọ́ ti èkíní mulẹ̀ [Bíbélì] … yíò sì sọ àwọn ohun kedere àti iyebíye náà di mímọ̀, èyí tí a ti gbà kúrò lọ́wọ́ wọn; a ó sì sọọ́ di mímọ̀ sí gbogbo àwọn ìbátan, èdè, àti ènìyàn, pé Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run náà jẹ́ Ọmọ Bàbá Ayérayé, àti Olùgbàlà aráyé; àti pé gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, tàbí a kì yíò lè gbà wọ́n là.”4

Àwọn òtítọ́ kedere àti iyebíye nípa Ètùtù Olùgbàlà jẹyọ jákèjádò Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Bí mo ti nto àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ní ẹsẹẹsẹ, mo pè yín láti ronú lóri bí wọ́n ti yí, tàbí bí wọn ti le yí, ìgbé ayé yín padà.

  1. Ètùtù ti Jésù Krístì jẹ́ ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan tí a fi lélẹ̀ fún gbogbo àwọn tí wọ́n ti gbé rí, àwọn tí wọ́n ngbé nísisìyí, àti àwọn tí wọn yío gbé ní orí ilẹ̀ ayé.5

  2. Ní àfikún sí gbígbé ẹrù àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, Krístì náà gba àwọn ìbànújẹ́, àwọn àlébù, àwọn ìjìyà, àwọn àìsàn àti gbogbo àwọn ìpọ́njú wa tí ó wà nínú ipò ikú ènìyàn sí ara Rẹ̀. Kò sí oró, kò sí ìrora tàbí ìbànújẹ́ kan tí Òun kò jìyà rẹ̀ fún wa.6

  3. Ẹbọ ọrẹ ètùtù ti Olùgbàlà fún wa ní ààyè láti borí àwọn àyọrísí àìdára ti Ìṣubú Adámù, nínú èyítí ikú ti ara wà. Nítori ti Krístì, gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run tí a bí ní ayé yi, láìka òdodo wọn sí, yío ní ìrírí dídàpọ̀ lẹ́ẹ̀kansí ti àwọn ẹ̀mí àti àwọn agọ́ ara wọn nípasẹ̀ agbára Ajínde7 wọn ó sì padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ láti “jẹ́ dídá lẹ́jọ́ … ní ìbámu sí àwọn iṣẹ́ [wọn].”8

  4. Ní yíyàtọ̀, gbígba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ìbùkún ti Ètùtù Olùgbàlà dá lórí aápọn wa9 ní gbígbé ìgbé ayé “ẹ̀kọ́ ti Krístì.”10 Nínú àlá rẹ̀, Léhì rí “ipa ọ̀nà híhá àti tóóró náà”11 tí ó darí sí ibi igi ìyè. Èso rẹ̀, èyí tí o dúró fún ìfẹ́ Ọlọ́run bí a ti fi hàn nípasẹ̀ àwọn ìbùkún rírẹwà ti Ètùtù Krístì, “jẹ́ iyebíye jùlọ tí ó sì yẹ ní fífẹ́ jùlọ … ó [sì] jẹ́ èyí tí ó tóbi jùlọ nínú gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run.”12 Kí a ba le dé ibi èso yi, a gbọdọ̀ lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, kí a ronúpìwàdà, “fi etí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,”13 gba àwọn ìlànà tí ó ṣe kókó, kí a sì ṣe ìpamọ́ àwọn májẹ̀mú mímọ́ títí di òpin ayé wa.14

  5. Nípasẹ̀ Ètùtù Rẹ̀, Jésù Krístì kò fọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa nú nìkan, ṣùgbọ́n bákannáà Ó pèsè agbára síṣeéṣe nípasẹ̀ èyítí àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ fi le “[kọ] ọkùnrin àdánidá nì [sílẹ̀],”15 tẹ̀síwájú “ní ẹsẹ lé ẹsẹ,”16 kí wọn ó sì pọ̀ síi ní ìwà mímọ́17 kí ó le jẹ́ pé ní ọjọ́ kan wọ́n le di ẹ̀dá pípé ní àwòrán ti Krístì,18 ní yíyẹ láti gbé lẹ́ẹ̀kansíi pẹ̀lú Ọlọ́run19 kí wọn ó sì jogún gbogbo àwọn ìbùkún ti ìjọba ọ̀run.20

Òtítọ́ miràn tí ó tuni nínú tí ó wà nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni pé, bí ìtànká rẹ̀ tilẹ̀ jẹ́ àìní ònkà àti ti gbogbo ayé, Ètùtù ti Olúwa fi àìwọ́pọ̀ jẹ́ ẹ̀bùn ti ara ẹni tí ó sì ṣe ọ̀wọ́n, tí a mú dára sí olukúlùkù wa bíi ẹnikọ̀ọ̀kan.21 Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti pe olukúlùkù àwọn ọmọ ẹ̀hìn ara Néfì láti wo àwọn ọgbẹ́ Rẹ̀, Ó kú fún olukúlùkù wa, ní ẹnikọ̀ọ̀kan, bí ẹni pé ìwọ àti èmi ni ẹni kan ṣoṣo ní orí ilẹ̀ ayé. Ó na ọwọ́ ìpè ti araẹni sí wa láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ kí a sì fa nínú àwọn ìbùkún ìyanu ti Ètùtù Rẹ̀.22

Jíjẹ́ ti araẹni ní àdánidá ti Ètùtù Krístì ndi òtítọ́ síi àní bí a ti nṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àpẹrẹ àwọn ọ̀kùnrin àti òbìnrin tí wọn kò wọ́pọ̀ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ní ààrin wọn ni Enọ́sì, Almà, Sísírómù, Ọba Lámónì àti ìyàwó rẹ̀, àti àwọn ènìyàn Ọba Bẹ́njámínì. Àwọn ìtàn ìyípadà àti àwọn akíkanjú ẹ̀rí wọn npèsè ẹ̀rí ààyè nípa bí a ti le yí ọkàn wa padà tí ìgbé ayé wa yío sì di ọ̀tun nípasẹ̀ ìṣerere àti àánú àìlópin ti Olúwa.23

Wòlíì Álmà bèèrè ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ gbígbónà yí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀. Wòlíì Almà bi àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìbéèrè gbígbóná yi: “Bí ẹyin bá ti ní ìrírí ọkàn yíyípadà, àti bí ẹ̀yin bá ti ní ìmọ̀lára láti kọ orin ìràpadà ti ìfẹ́, ẹmi béèrè, njẹ́ ẹ̀yin le ní ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ nísisìyí?“24 Ìbéèrè yí ṣe pàtàkì lónìí, nítorípé bíi ọmọlẹ́hìn Olúwa, agbára ìràpadà Rẹ̀ nílati wà pẹ̀lú wa, mí sí wa, kí ó sì yí wa padà ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àti gbogbo ọjọ́.

Ìbéèrè Almà le di títúnṣe bákannáà láti bèèrè pé, nígbàwo ni o ní ìmọ̀lára ipá dídùn ti Ètùtù Olùgbàla gbẹ̀hìn nínú ayé rẹ? Èyí nṣẹlẹ̀ nígbàtí ẹ bá ní ìmọ̀lára ayọ̀ “rírẹwà àti dídùn” kan25 tí ó wá sí ara yín èyítí ó jẹ́ ẹ̀rí sí ọkàn yín pé a ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì; tàbí nígbàtí, ní òjijì, àwọn ìpèníjà onírora bá di fífúyẹ́ láti gbé; tàbí nígbàtí ọkàn yín bá rọ̀ tí ẹ sì le sọ ọ̀rọ̀ àforíjì sí ẹnìkan tí ó ti ṣẹ̀ yín. Tàbí ó le jẹ́ àkókò kọ̀ọ̀kan tí ẹ bá wòye pé agbára yín láti fẹ́ràn àti lati sin àwọn ẹlòmíràn ti pọ̀ síi, tàbí pé àwọn ìgbésẹ̀ ìyàsímímọ́ nsọ yín di ènìyàn ọ̀tọ̀, tí ó nṣe ètò ní àpẹrẹ ti Olùgbàlà.26

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé gbogbo àwọn ìrírí wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́, wọ́n sì jẹ́ àmì pé a le yí ìgbé ayé padà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀. Ìwé ti Mọ́mọ́nì ṣe àsọyé àti ìmúgbòrò ìmọ̀ wa nípa ẹ̀bún yíyanilẹ́nu yi. Bí ẹ ti nṣe àṣàrò ìwé yi, ẹ ó gbọ́ ohùn Krístì alààyè tí ó npè yín láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Mo ṣe ìlérí pé bí ẹ bá gba ìpè yí tí ẹ sì ṣe ètò ayé yín ní àtẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀, ipá agbanilà Rẹ̀ yío wá sí inú ayé yín. Nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mimọ́, Olùgbàlà yío sọ yín di ọ̀tun ní ọjọ́ dé ọjọ́ “titi di ọjọ́ tí ó pé náà”27 nígbàtí ẹ ó, bí Ó ti kéde, ẹ ó “rí ojú mi ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni.”27 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.