Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Pé Kí Wọ́n Lè Ri
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Pé Kí Wọ́n Lè Rí

Wo kí o si gbàdúrà fún àwọn ànfàní lati jẹ ki ìmọ́lẹ̀ yin tàn fún àwọn ẹlòmíràn ki wọn o le ri ọ̀nà si Jésù Krístì

Ẹ̀yin arábìnrin àti arábìnrin, ọkàn wa ti di alábùkún fún a sì ti di ọ̀tun nípa ìmọ̀lara ti Ẹ̀mí ti a ti ní nínú ìpàdéàpapọ̀ yi.

Àwòrán
Òpó ìmọ́lẹ̀ kan

Igba ọdún sẹ́hìn, òpó ìmọ́lẹ̀ kan wá sí orí ọ̀dọ́mọkùnrin kan ni igbó àwọn igi. Ní ìmọ́lẹ̀ náà, Joseph Smith ri Ọlọ́run Bàbá àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Ìmọ́lẹ̀ wọn lé ẹ̀mí òkùnkùn ti o bojú ilẹ̀ ayé sẹ́hìn ó sì fi ọ̀nà síwájú han fún Joseph Smith—àti fún gbogbo wa. Nítorí ìmọ́lẹ̀ tí a fihàn ní ọjọ́ náà, a lè gba àwọn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbùkún tí o wà nípa Ètùtù Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.

Nípa agbára ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Rẹ̀, a le kún fún ìmọ́lẹ̀ Olùgbàlà wa. Síbẹ̀síbẹ̀, ìmọ́lẹ̀ náà wà fún ìwọ àti èmi nìkan. Jésù Krístì ti pè wá “ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín ó mọ́lẹ̀ tóbẹ̃ níwájú àwọn ènìyàn yĩ, kí wọn ó lè rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn ó sì máa yin Bàbá yín tí mbẹ lọ́run lógo.”1 Mo ti wá láti nifẹ gbólóhùn ọ̀rọ̀ “kí wọn ó lè rí.” Ó jẹ́ ìfipè àtọkàn wa láti ọ̀dọ̀ Olúwa ki a mọ̀ọ́mọ̀ ma ran àwọn míràn lọ́wọ́ síi láti rí ọ̀nà àti nítorínáà wá sọ́dọ̀ Krístì.

Àwòrán
Alàgbà L. Tom Perry

Nígbàtí mo wa ni ọmọ ọdún mẹwa, ẹbí wa ni ọ̀wọ̀ láti gba Alàgbà L. Tom Perry ti Iyejú Àwọn Àpóstélì Méjìlá lalejo nígbà ti o wá fún ìfúnni níṣẹ́ ṣe ní ìlú abínibí mi.

Ní ìparí ọjọ́, ẹbí wa ati àwọn Perry joko ni yàrá ìgbàlejò lati gbádùn nkan jíjẹ àpú tó dùn, bí Alàgbà Perry ṣe nsọ àwọn ìtàn nípa àwọn Ènìyàn Mímọ́ kákiri ayé. Ó yàmí lẹ́nu.

Ilẹ̀ ti fẹ́ ma ṣu nígbàti ìyá mi pèmí sí ilé ìdáná lati bèèrè ìbéèrè kékeré: “Bonnie, ṣe o fún àwọn ẹdìyẹ lóúnjẹ?”

Ọkàn mi jábọ́; Mi o tii ṣeé. Láì fẹ fi iwájú Àpóstélì Olúwa sílẹ̀, Mo daba kí àwọn ẹdìyẹ gbàwẹ̀ di òwúrọ̀.

Ìyá mi dáhùn pẹlu àsọyé kan “rárá.” Lẹ́hìnnáà, Alàgbà Perry wọ ilé-ìdáná ati pẹ̀lú ohùn onítara rẹ, bèèrè “Ṣe mo gbọ pe ẹnìkan yẹ láti fún àwọn ẹdìyẹ lóúnjẹ? Ṣé èmi àti ọmọ mi le darapọ̀ mọ́ ọ?”

Oo, kíni ayọ̀ pípé tí o dà láti fún àwọn ẹdìyẹ lóúnjẹ! Mo sáré láti lọ mú ìtànná yẹ́lò wa nla. Pẹ̀Iú ìdùnnú, Mo lọ ṣíwájú, n rékọjá lórí ọ̀nà ti o wọ̀ dáradára lọ si agbọ̀n ẹdìyẹ. Pẹ̀lú ìtànná tí o n yí lọ́wọ́ mi, a kọjá ni oko ọka a sì kọjá nínú pápá wíìtì.

Nínọwọ́ si ọ̀gbun omi ti o la ọ̀nà kọjá, Mo fo pẹ̀lú ọgbọ́n kọjá lori rẹ̀ bi mo ti ṣe ni ọ̀pọ̀ alẹ́ ṣíwájú. Mo wà láìṣe àníàní si ìtiraka Alàgbà Perry láti wa ni ọ̀na tí o ṣókùnkùn ati àìmọ̀. Ìmọ́lẹ̀ jíjó mi kò ràn án lọ́wọ́ lati ri ọ̀gbun náà. Láìsí ìmọ́lẹ̀ ti o dúró láti ríi, ó já sínú omi náà o si pariwo kíkan. Ní ìbẹ̀rù, Mo yípadà si ọ̀rẹ́ titun lati ri ti o yọ ẹsẹ̀ tútù rẹ nínu ọ̀gbun ti o si ngbọ́n omi kúrò lára bàtà wúwo aláwọ rẹ.

Pẹ̀lu bàtà yíyọ̀ tútù kan, Alàgbà Perry rànmí lọ́wọ́ láti fún àwọn ẹdìyẹ lóúnjẹ. Nígbàtí a ṣe tan, ó pàṣẹ pẹ̀lú ìfẹ́, “Bonnie, mo nílò láti rí ọ̀nà. Mo nílò ìmọ́lẹ̀ láti mọ́lẹ̀ síbi tí mo ngbà.

Mo ntan ìmọ́lẹ̀ mi ṣùgbọ́n kìí ṣe ni ọ̀nà ti o le ran Alàgbà Perry lọ́wọ́. Nísisìyí, mímọ̀ pe òun nílò ìmọ́lẹ̀ mi lati ri ọ̀nà kedere, Mo kọjú ìtànná náà síwájú àwọn ìgbésẹ̀ rẹ a si le padà sílé pẹ̀lú ìgboya.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, fún ọ̀pọ̀ ọdún Mo ti ronú lórí ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti Mo kọ́ lati ọ̀dọ̀ Alàgbà Perry. Ìpè Olúwa láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa kí o tàn tó bẹ ki i ṣe ki a tilẹ̀ máa gbé igi ìmọ́lẹ̀ wa láìletò kí á si mú ki ayé mọ́lẹ̀ si lápapọ̀. Ó wa nípa dídojú ìmọ́lẹ̀ náà kọ àwọn ẹlòmíràn ki wọn o le ri ọ̀nà si Krístì Ó jẹ́ kíkó Ísráẹ̀li jọ ní apá ìbojú yi—ní ríran àwọn míràn lọ́wọ́ lati ri ìgbésẹ̀ ti o kàn ni ṣíṣe ati pípa àwọn májẹ̀mú mọ pẹ̀lú Ọlọ́run.2

Olùgbàlà jẹri, “Ẹ kíyèsĩ èmi ni ìmọ́lẹ̀; èmi ti fi àpẹrẹ lélẹ̀ fún yín.”3 Ẹ jẹ́ kí a wo ọ̀kan lára àwọn àpẹrẹ Rẹ.

Obìnrin náà ni etí kànga jẹ́ ara Samáríà ẹni ti kò mọ Jésù Krístì ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ri bi àṣatì ni àwùjọ. Jésù pàdé rẹ o si bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ. Ó ba sọ̀rọ̀ nípa omi. Lẹ́hìnnáà ó mu lọ si ìmọ́lẹ̀ púpọ̀ si bi O ti kéde Ararẹ̀ láti jẹ́ “omi ìyè náà.”4

Krístì fi tàánútàánú mọ̀ ọ́ àti àìní rẹ̀. Ó pàdé rẹ níbì ti o wa Ó bẹrẹ nipa sísọ̀rọ̀ nipa omi, ohun kan ti o jẹ mímọ̀ tí ó sì wọ́pọ̀. Tí Ó ba dúró nibẹ, ì bá jẹ́ ìbápàdé rere. Ṣùgbọ́n ìbá ma ti jásí lílọ rẹ si ìlú lati lọ kéde, “Ẹ wa, woo … : èyí ha lè jẹ Krístì náà?”5 Díẹ̀díẹ̀, nípa ìbánisọ̀rọ̀, ó ṣe àwárí Jésù Krístì, pẹ̀lú ìwà àtẹ̀hìnwá rẹ, ó di ohun èlò ìmọ́lẹ̀, tó nmọ́lẹ̀ ni ọ̀nà fún àwọn ẹlòmíràn láti ri .6

Níbàyí ẹ jẹ́ ki a wo àwọn méjì ti o tẹle àpẹrẹ Olùgbàlà nípa pípín ìmọ́lẹ̀. Láìpẹ́ yí ọ̀rẹ́ mi Kevin joko sẹgbẹ alakoso ilé iṣẹ kan níbi oúnjẹ alẹ́. O ṣe àníyàn nipa ohun ti yio sọ fún wákàtí méjì. Títẹ̀le ìṣílétí kan, Kevin bèèrè, “Sọ fún mi nípa ẹbí rẹ. Níbo ni wọ́n ti wá?”

Arákùnrin jẹ́jẹ náà mọ díẹ̀ nínú ìjogún rẹ, Kevin si yọ ẹ̀rọ ìbáraẹnisọrọ rẹ, wípé, “Mo ni ápù kan ti o so gbogbo ènìyàn mọ àwọn ẹbí wọn. Ẹ jẹ ki a wo ohun ti a le rí.”

Lẹhin ọ̀rọ̀ púpọ̀, ọ̀rẹ́ Kevin titun bèèrè, “Kíni ìdí ti ẹbí fi ṣe pàtàkì sí ìjọ yin?”

Kevin dáhùn jẹ́jẹ́, “A gbàgbọ́ pe ao ma gbé lẹ́hìn tí a bá kú. Bí a bá mọ àwọn bàbánla wa ti a si fi àwọn orúkọ wọn lọ síbi mímọ́ ti a npe ni tẹ́mpìlì, a le ṣe àwọn ìlànà ìgbeyàwó ti yio mu ẹbí wa wà papọ̀ pàápàá lẹ́hìn ikú.”7

Kevin bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun ti òhun ati ọ̀rẹ́ rẹ ni ti o jọra. O si wa àyè kan lati jẹri ìmọ́lẹ̀ ati ìfẹ́ Olùgbàlà

Ìtàn kejì nipa Ella, ògbójú agbábọ́ọ̀lù ọlọ́wọ́. Àpẹrẹ rẹ bẹ̀rẹ̀ nígbàtí o gba ìpè míṣọ̀n rẹ nígbàtí o wa nílé ìwé. Ó yan lati ṣi ìwé ìpè rẹ lójú àwọn ẹgbẹ́ rẹ. Wọn ko mọ ohunkóhun nípa Ìjọ Jésù Krístì wọn ko si ni òye ìfẹ́ Ella láti sìn. O gbàdúrà léraléra lati mọ bi yio ṣe ṣe àlàyé ìpè míṣọ̀n rẹ ni ọ̀nà ti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ yio fi ni ìmọ̀lara ti Ẹ̀mí. Ìdáhun rẹ?

Mo ṣe sọ́kẹ́tí ògiri fun ina,”Ella sọ, “nítorí mo tutù bẹ́ẹ̀.” Ó sọ fún wọn nipa èrè ti o wa nínu sísìn nínú ọ̀kan lára àwọn míṣọ̀n irínwó o le ati kíkọ́ èdè kan. O ka àwọn ẹgbẹgbẹ̀run ìránṣẹ́ ìhìnrere ti wọn ti nsìn. Ella parí pẹ̀lú àwòrán Olùgbàlà ati ẹ̀rí ṣókí yi: “Bọ́ọ̀lu ọlọ́wọ́ jẹ ọ̀kan pàtàkì nínú ayé mi. Mo lọ kaakiri orílẹ̀ èdè mo si fi ẹbí mi sílẹ̀ láti gba fùn olùkọ́ yi ati ẹgbẹ́ yi. Àwọn ohun méjì ti o ṣe pàtàkì si mi ju bọ́ọ̀lù ọlọ́wọ́ ni ìgbàgbọ́ mi ati ẹbí mi.”8

Nísisìyí, ti ẹ ba nronú, “Ìwọnyi ni àpẹrẹ ẹgbẹ̀rún wáàtì, ṣùgbọn èmi jẹ ogún wáàtì gílóbù,” ẹ rántí pé Olùgbàlà jẹri, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ẹ̀yin yio gbé sókè.”9 O ránwa létí pe Yio mú ìmọ́lẹ̀ wa bí awa ba le tọ́ka àwọn ẹlòmíràn si I.

Ẹ̀yin àti Emi ni ìmọ́lẹ̀ ti o to pín nísisìyí. A lè tàn ìmọ́lẹ̀ si ìgbésẹ tí o kàn láti ran ẹnìkan lọ́wọ́ láti súnmọ Jésù Krístì, ati ìgbésẹ tí o kàn àti èyí tí o kàn.

Bi ara rẹ leere, “Tani o nílò ìmọ́lẹ̀ ti o ni lati le ri ọ̀nà ti wọn nílò ṣùgbọ́n ti wọn ko ri?”

Ẹ̀nyin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, kini idi ti títan ìmọ́lẹ̀ wa fi ṣe pàtàki to bẹẹ? Olúwa ti sọ fún wa pe “ọ̀pọ̀ ṣì wa síbẹ̀ ni ilẹ̀ ayé … àwọn ti a mu pamọ́ kúro fún òtítọ́ nítorí wọn ko mọ ibi ti wọn ti le ri i.”10 A lè ṣe ìrànwọ́. A le mọ̀ọ́mọ̀ tan ìmọ́lẹ̀ wa ki ẹlòmíràn le ri wọn. A lè nawọ́ ìpè.11 A le rìn ìrìnàjò pẹ̀lu àwọn ti wọn ngbé ìgbésẹ̀ sọ́dọ̀ Olùgbàlà, bi o ti wu ki o dúró. A le ko Ísráẹ́li jọ.

Mo jẹ́rí pé Olúwa yio sọ gbogbo akitiyan di nla. Ẹmí Mímọ yio tọ wa lati mọ ohun ti a o sọ ati ṣe. Irú àwọn ìgbìyànjú bẹ le mú wa kúrò nínú ibi ìtura wa, ṣùgbọ́n a le ni ìdánilójú wípé Olúwa yio jẹ ki ìmọ́lẹ̀ wa tàn.

Ìmore mi ti pọ̀tó fún ìmọ́lẹ̀ Olùgbàlà, ti o tẹ̀síwájú ní dídarí ìjọ yi nípa ìfihàn.

Àwòrán
Olùgbàlà n di ìtànna mu

Mo pe gbogbo wa lati tẹ̀lé àpẹrẹ Jésù Krístì kí a si fi tânútânú ni ìmọ̀lára àwọn ti o yi wa ka. Wo kí o si gbàdúrà fún àwọn ànfàní lati jẹ ki ìmọ́lẹ̀ yin tàn fún àwọn ẹlòmíràn ki wọn o le ri ọ̀nà si Jésù Krístì Ìlérí Rẹ̀ tóbi: “ẹni tí ó bá tẹ̀lé mi kò ní rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yíò ní ìmọ́lẹ̀ ayé.”12 Mo jẹri pé Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, ni ọ̀nà, òtítọ́, àti ìyè, àti ìfẹ́ ayé. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.