Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìmọ́lẹ̀ Pípé ti Ìrètí Kan
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Ìmọ́lẹ̀ Pípé ti Ìrètí Kan

Nítorí Ìmúpadàbọ̀sípò tún ìpìlẹ̀ òtítọ́ sọ pé Ọlọ́run nṣiṣẹ́ ní ayé, a lè nírètí, àní nígbàtí a bá dojúkọ àwọn àtakò àìlèkojú jùlọ.

Ní Oṣù Kẹwàá, Ààrẹ Russell M. Nelson pè wá láti wò iwájú sí ìpàdé àpapọ̀ ti Oṣù Kẹ́rin 2020 yi bí ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà tiwa ní wíwò ẹ̀hìn láti rí ọlánlá ọwọ́ Ọlọ́run ní mímú ìhìnrere Jésù Kristì bọ̀sípò. Arábìnrin Holland àti èmi mú ipè ti wòlíì yi ní ọ̀kúnkúndùn. A ronu ìgbé-ayé arawa ní ìṣíwájú 1800, wíwo ìgbàgbọ́ ẹlẹ́sìn ní ọjọ́ náà. Nínú ìrònú náà, a bèèrè fúnrawa, “Kíni ó sọnù nihin? Kinni ìbá wù wá pé a ní? Kinni a ní ìrètí pé Ọlọ́run yío pèsè ní ìdáhùn sí àwọn ìpongbẹ wa ti ẹ̀mí?”

Ó dára, fún ohun kan, a ríi pé ní ọgọ́run-ọdún méjì sẹ́hìn àwa ibá ti ní ìrètí fún ìmúpadàbọ̀sípò ti èrò Ọlọ́run tí ó jẹ́ òtítọ́ síi dáadáa, tí ó jẹ́ mímọ́ síi ju èyítí pùpọ̀ ti gbà níjọ́ náà, ní fífi ara sin bí Òun ti máa nfi ìgbà gbogbo dàbí ẹnipé ó wà ní ẹ̀hìn àwọn ọgọ́ọ̀rún ọdún àṣìṣe ẹkọ́ ẹ̀sìn àti èdè àìyédè. Láti yá ọ̀rọ̀ kan lò láti ọwọ́ William Ellery Channing, gbajúmọ̀ ẹlẹ́sìn kan ní ìgbà náà, àwa ìbá ti wá “ìwà jíjẹ́ òbí ti Ọlọ́run,” èyítí Channing rò sí “ẹ̀kọ́ nlá àkọ́kọ́ ti jíjẹ́ Krístíanì.”1 Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ yío ti rí Ọlọ́run bíi olùfẹ́ni Baba ní Ọrun kan, dípò onídajọ́ líle tí ó nfi àìṣègbè líle fúnni tàbí onílé tí kò sí nílé ẹnití ó ti fi ìgbà kan rí ṣiṣẹ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ayé ṣùgbọ́n nísisìyí tí ó ṣe àníyàn ní ibòmíràn kan ní àgbáyé.

Bẹ́ẹ̀ni, àwọn ìrètí wa ni 1820 ìbá ti jẹ́ láti rí Ọlọ́run tí ó nsọ̀rọ̀ àti tí ó ntọ́wasọ́nà ní gbangba ní ìsisìyí bí Ó ti ṣe ní ìgbà tí ó kọjá, Bàbá òtítọ́ kan, ní èrò ọ̀rọ̀ náà. Dájúdájú Òun kì yío jẹ́ ẹni tútù, apàṣẹ wàá tí ó yan àwọn díẹ̀ tó ní àyànmọ́ fún ìgbàlà àti nígbànáà fi ìdílé ìyókù ẹ̀dá ènìyàn sí ìdálẹ́bi. Rárá, Òun yío jẹ́ ẹnìkan tí gbogbo ìṣe rẹ̀, nípa ìkéde àtọ̀runwá, yío jẹ́ “fún ànfààní ti ayé; nítorí ó fẹ́ràn ayé”2 àti gbogbo olùgbé inú rẹ̀. Ìfẹ́ náà ni yío jẹ́ èrèdí Rẹ̀ tí ó ga jùlọ fún rírán Jésù Krístì, Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Kanṣoṣo, sí ilẹ̀ ayé.3

Ní sísọ ọ̀rọ̀ nípa Jésù, ìbá jẹ́ pé a ti wà ní ayé nínú àwọn ọdún àkọ́kọ́ wọnnì ti sẹ́ntíúrì kọkàndínlógún, àwa ìbá ti mọ̀ pẹ̀lú ìyàlẹ́nu nlá pé àwọn iyèméjì nípa jíjẹ́ òtítọ́ ti ìyè àti Àjínde Olùgbàlà ti nbẹ̀rẹ̀ láti múlẹ̀ gidigidi ní ààrin Agbo Ìgbàgbọ́. Nítorínáà, àwa ìbá ti retí fún ẹ̀rí láti wá sí gbogbo ayé tí yío fi ẹsẹ̀ ẹ̀rí ti bíbélì múlẹ̀ pé Jésù ni Krístì náà, Ọmọ Ọlọ́run gãn, Álfà àti Ómégà, àti Olùgbàlà kanṣoṣo ti ayé tí a mọ̀. Ìbá ti wà nínú àwọn ìrètí wa ọ̀wọ́n jùlọ pé kí a mú àmì míràn ti inú ìwé mímọ́ wá síwájú, ohun kan tí yío jẹ́ bíi ẹ̀rí míràn ti Jésù Krístì, tí yío ṣe ìmúgbòrò àti àtúnṣe ìmọ̀ wa nípa ìbí yíyanilẹ́nu, iṣẹ́ ìránṣẹ́ yíyanilẹ́nu, ètùtù ẹbọ ọrẹ, àti Àjínde ológo Rẹ̀. Nítõtọ́ irú ìwé bẹ́ẹ̀ yío jẹ́ “òdodo [tí a rán] sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run; àti òtítọ́ [tí a rán] jáde láti orí ilẹ̀ ayé.”4

Ní wíwòye ayé Krístiẹnì ní ìgbà náà, àwa ìbá ti retí láti rí ẹnikan tí a fi àṣẹ fún láti ọwọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú àṣẹ oyè àlùfáà tõtọ́ ẹnití yío le rì wá bọmi, fi ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí Mímọ́ fúnni, àti tí yío ṣe ìpínfúnni gbogbo àwọn ìlànà ìhìnrere tí ó ṣe dandan fún ìgbéga. Ní 1820, àwa ìbá ti retí lati rí kí ó wá sí ìmúṣẹ àwọn ìlérí ti Isaiah, Míkà, àti àwọn wòlíì àtijọ́ miràn nípa ìpadàbọ̀ ilé ọlọ́lá ti Olúwa.5 Ìbá ti dùn mọ́wa láti rí ògo àwọn tẹ́mpìlì mímọ́ ní gbígbékalẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi, pẹ̀lú Ẹ̀mí, àwọn ìlànà, agbára, àti àṣẹ láti kọ́ni ní àwọn òtítọ́ ayérayé, láti wo àwọn ọgbẹ́ ti ara ẹni sàn, àti láti so àwọ̀n ẹbí papọ̀ títí láé. Èmi ìbá ti wo ibikíbi àti ibi gbogbo láti rí ẹnìkan tí a fi àṣẹ fún lati sọ fún èmi àti Patricia mi ọ̀wọ́n pé ìgbéyàwó wa nínú irú àgbékalẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni a fi èdidi dì fún ìgbà kan àti gbogbo ayérayé, kí a máṣe gbọ́ láé tàbí kí wọn ó fi ègún mọ́nigbàgbé nì lé wa lórí pé “títí ikú yío fi yà yín.” Mo mọ̀ pé “nínú ilé Baba [wa] ọ̀pọ̀ ibùgbé ni ó wà,”6 ṣùgbọ́n ní sísọ ọ̀rọ̀ ti ara ẹni, bí mo bá ṣe orí ire tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè jogún ọ̀kan nínú wọn, kò le jẹ́ sími ju bíi ahéré kan tí ó ti nbàjẹ́ bi Pat àti àwọn ọmọ wa kò bá sí pẹ̀lú mi láti pín ogún ìní náà. Àti fún àwọn aṣáájú wa, tí díẹ̀ nínú wọn ti gbé tí wọ́n sì ti kú ní ìgba àtijọ́ àní láì gbọ́ orúkọ Jésù Krístì, àwa ìbá ti retí fún àwọn èrò inú bíbélì tí ó tọ́ tí ó sì kún fún àánú láti jẹ́ mímúpadàbọ̀ sípò—ìṣe kí alààyè ó máa dúró àwọn ìlànà ìgbanilà ní ìgbẹnusọ fún àwọn ìbátan wọn tí wọ́n ti kú.7 Kò sí ìṣe kan tí mo le fi ojú inú wò tí ó le ṣe àpèjúwe, pẹ̀lú títóbi tí ó ju èyí lọ, àníyàn Ọlọ́run olùfẹ́ni kan fún olukúlùkù àwọn ọmọ Rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé, ibi yíówù tí wọ́n gbé tàbí ibi tí wọ́n kú sí.

Ó dára, títòsílẹ̀ àwọn ìrètí wa ní 1820 le máa lọ bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n bóyá ọ̀rọ̀ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ní ti Ìmúpadàbọ̀ sípò ni pé irú àwọn ìrètí bẹ́ẹ̀ ìbá já sí asán. Bẹ̀rẹ̀ nínú Ọgbà Igi Mímọ́ náà tí ó sì tẹ̀síwájú títí di òní yi, àwọn ìfẹ́ inú wọ̀nyí ti bẹ̀rẹ̀ sí wọ aṣọ òtítọ́ àti pé, bí Paulù Apóstélì àti àwọn ẹlòmíràn ti kọni, wọ́n ti di ìdákọ̀ró òtítọ́ sí ọkàn, tí ó dájú tí ó sì dúróṣinṣin.8 Ohun tí a fi ìgbà kan rí ní ìrètí rẹ̀ lásán ti wá di ìtàn nísisìyí.

Báyi ni wíwò sẹ́hìn sí igba ọdún ti ìwàrere Ọlọ́run sí ayé. Ṣùgbọ́n báwo ní wíwò wa sí iwájú? A ṣì ní àwọn ìrètí tí wọn tíì wá sí ìmúṣẹ síbẹ̀ Àní bí a ṣe nsọ̀rọ̀, a njà ní “gbogbo ọwọ́ lórí iṣẹ́“ ogun pẹ̀lú COVID-19, ìrántí ọ̀wọ̀ pé ààrùn tí ó kéré ju hóró erùpẹ̀ kan9 lọ lọ́nà ẹgbẹ̀rún lè mú gbogbo ènìyàn àti ọ̀rọ̀ ajé àgbáyé lọ sórí eékún wọn. A gbàdúrà fún àwọn tí ó ti pàdánù olólùfẹ́ wọn nínú àjàkálẹ̀ ààrùn ìgbàlódé, bákannáà fún àwọn tí wọ́n ní ààrùn lọ́wọ́lọ́wọ́ tàbí to lè ni. Dájúdájú a gbàdúrà fún àwọn tí wọ́n nfúnni ní ìtọ́jú ìlera títóbí bẹ́ẹ̀. Nígbàtí a bá ti ṣẹ́gun èyí—a ó—lè fara sí mímú aye\ ní òmìnira ní ìdọ́gba látinú ààrùn ebi, mú òmìnira bá aladugbo àti orilẹ̀-èdè kúrò nínú ààrùn ọ̀ṣì. Njẹ́ kí a nírètí fún àwọn ilé-ìwé níbití a ti nkọ́ àwọn akẹkọ—láìbẹ̀rù pé a ma yìn wọn— àti fún ẹ̀bùn iyì araẹni fún gbogbo ọmọ Ọlọ́run, láìfarapa nípasẹ̀ iru ẹ̀yà, èdè, tàbí ẹ̀tanú ẹlẹ́sìn kankan, Ní títọ́jú gbogbo èyí ni àìsọ̀rètínù ìretí fún ìfọkànsìn títóbijùlọ sí àwọn òfin nlá méjì nì: láti fẹ́ Ọlọ́run nípa pípa ìmọ̀ràn Rẹ̀ mọ́ àti láti fẹ́ àwọn ẹnìkejì wa nípa fífi inúrere àti ìyọ́nú, sùúrù àti ìdáríjì hàn.9 Àwọn ìdarí àtọ̀runwá méjì wọ̀nyí ṣì ni—àti pé títí láé ni wọn ó máà jẹ́—ìrètí òtítọ́ kanṣoṣo tí a ní fún fífún àwọn ọmọ wa ní ayé kan tí ó dárajù tayọ èyí tí wọ́n mọ̀ nísisìyí.10

Ní àfikún sí àwọn ìfẹ́ inú ti àgbáyé wọ̀nyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ìpéjọpọ̀ yi lóni ní àwọn ìrètí jíjinlẹ̀ ti ara ẹni: ìrètí fún ìgbeyàwó kan láti dára síi, tàbí nígbàmíràn ìrètí fún ìgbeyàwó kan ṣá, ìrètí fún bárakú kan láti borí, ìrètí fún ọmọ aláìmọ̀ọ́ṣe kan láti padà wá; ìrètí fún ìrora àfojúrí àti ẹ̀dùn ọkàn onirúurú bí ọgọ́rũn kan láti dáwọ́ dúró. Nítorí Ìmúpadàbọ̀sípò ṣe àtẹnumọ́ ìpìlẹ̀ òtítọ́ pé Ọlọ́run nṣiṣẹ́ ní ayé yí, a le nírètí, a gbọ́dọ̀ nírètí, àní nígbàtí a bá dojúkọ àwọn àtàko àìlèkojú jùlọ. Èyí ni ohun tí ìwé mímọ́ túmọ̀ sí nígbàtí ó ṣeéṣe fún Abrahamù láti ní ìrètí tako ìrètí11—èyí ni pé, ó ṣeéṣe fún un láti gbàgbọ́ àní pẹ̀lú gbogbo èrèdí láti máṣe gbàgbọ́—pé òun àti Sáràh le ní oyún ọmọ kan nígbàtí èyíinì dàbí ohun tí kò ṣeéṣe pátápátá. Nítorínáà, mo bèèrè, “Bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìrètí wa ti 1820 bá le bẹ̀rẹ̀ sí di mímúṣẹ pẹ̀lú títàn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá kan sí ọmọkùnrin kan ṣá tí ó kúnlẹ̀ nínú gbàgede àwọn igi ní agbègbè New York, kínní ṣe tí àwa kò ní retí pé àwọn ìfẹ́ inú òdodo àti àwọn ìpòngbẹ Bíi ti Jésù ṣì le di dídáhùn pẹ̀lú ìyanilẹ́nu, pẹ̀lú ìyanu láti ọwọ́ Ọlọ́run gbogbo ìrètí?” Gbogbo wa nílò láti gbàgbọ́ pé ohun tí a fẹ́ nínú òdodo le di tiwa síbẹ̀ ní ọjọ́ kan, ní ọ̀nà kan, bí ó ti wù kí ó rí.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, a mọ̀ ohun tí ó jẹ́ díẹ̀ lára àwọn àlébù ẹ̀sìn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́run-ọdún kọkàndínlógún. Síwájú síi, a mọ ohun kan nípa àwọn àìlera ẹ̀sìn ti òní tí ó ṣì fi ebi àti ìrètí àwọn kan sílẹ̀ ní aìmúṣẹ síbẹ̀. A mọ̀ pé onírúurú àwọn àìsí ìtẹ́lọ́rùn wọnnì ndarí iye àwọn ènìyàn tí ó npọ̀ síi kúrò nínú àwọn àgbékalẹ̀ àṣà ti ijọ. Bákannáà ni a mọ̀, bí ònkọ̀wé onínúbíbàjẹ́ kan ti kọ, pé “púpọ̀ àwọn olórí ẹ̀sìn [ti ode òní] dàbí ẹni tí kò ní ìmọ̀” ní kíkojú ìfàsẹ́hìn yi, wọ́n a sọ ní ìdáhùn “ohun ìbẹ̀rù kan bíi òriṣà àkanṣe ìtọ́jú, àmì kíkópa tí kò ní iye lórí, ìyapa tí a fi yéni pẹ̀lú ọgbọ́n, [tàbí nígbàmíràn] ariwo lásán láìní ìmísí”12àti gbogbo rẹ̀ ní àkókò tí ayé nílò púpọ̀ tobẹ́ẹ̀ síi, nígbàtí àwọn ìran tí ndìde yẹ fún púpọ̀ tobẹ́ẹ̀ síi, àti nígbàtí, ní ìgbà ti Jésù Ó fi púpọ̀ tobẹ́ẹ̀ lẹ́lẹ̀ síi. Bíi ọmọlẹ́hìn Krístì, ní ìgbà tiwa a le dìde tayọ àwọn ará Israelì àtijọ́ wọnnì tí wọ́n kérora, “Àwọn egungun wa ti gbẹ, ìrètí wa sì ti sọnù.”13 Nítòótọ́, bí a bá sọ ìrètí nù nígbẹ̀hìn, a sọ agbéniró ìní wa ìkẹhìn nù. Ní orí ẹnu ọ̀nà ọ̀run apãdì gãn ni Dante kọ ìkìlọ kan sí gbogbo àwọn arìnrìnàjò nípasẹ̀ Divina Commedia rẹ̀: “Ẹ fi gbogbo ìrètí sílẹ̀,” ní ó sọ, “ẹ̀yin tí ẹ bá wọ ìhín yí wá.”14 Nítòótọ́, nígbàtí ìrètí bá ti lọ, ohun tí ó kù fún wa ni ẹ̀là iná ti iná jíjó náà tí ó ní agbára ní gbogbo ìhà.

Nítorínáà, nígbàtí a bá kọ ẹ̀hìn wa sí ògiri àtí, bí orin náà ti sọ, “tí àwọn olùrànlọ́wọ́ miràn kùnà tí ìtùnú sì sálọ,”15 ní ààrin àwọn ìyì wa tí ó ṣe kókó jùlọ ni ẹ̀bùn iyebíye ti ìrètí yí sopọ̀ láìle yapa mọ́ ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ wa sí àwọn ẹlòmíràn, yío wà.

Ní àjọ̀dún igba ọdún yi, nígbàtí a wo ẹ̀hìn láti rí gbogbo ohun tí a ti fifún wa tí a sì yọ̀ ní mímọ̀ ti ọ̀pọ̀ àwọn ìrètí tí wọ́n ti wá sí ìmúṣẹ, mo ṣe àtúnsọ ìmọ̀lára ọ̀dọ́ arẹwa arábìnrin oníṣẹ́ ìránṣẹ kan tí ó ti padà, ẹnití ó sọ fúnwa ní Johannesburg ní oṣù díẹ̀ sẹ́hìn pé, “[Àwa] kò wá ní pípẹ́tó báyi láti wá pípẹ́ tó báyi nìkan.”16

Ní síṣe àkékúrú ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ ìdágbére tí ó ní ìmísí jùlọ tí a ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú ìwé mímọ́, mo sọ pẹ̀lú wolíì Néfì àti ọ̀dọ́ arábìnrin náà pé:

“Ẹyin arákùnrin [ati arábìnrin] mi àyànfẹ́, lẹ́hìn ti ẹ̀yin [ti gba àwọn èso àkọ́kọ́ ti Ìmúpadàbọ̀ sípò], ẹ̀mi yíò bèrè bí a bá ti ṣe gbogbo nkan? Kíyèsíi, mo wí fún yín, Rárá. …

“… Ẹ̀yin gbọdọ̀ tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú Krístì, kí ẹ ní ìmọ́lẹ̀ pípé ti ìrètí, àti ìfẹ́ ti Ọlọ́run àti ti gbogbo ènìyàn. … Bí ẹ̀nyin bá[,] … ni Baba wí: Ẹ̀nyin yío ní ìyè ayérayé.”17

Mo dúpẹ́ fún gbogbo ohun tí a ti fifún wa ní ìgbà ìkẹhìn àti títóbijù, ìgbà ìmúpadàbọ̀ ìhìnrere ti Jésù Krístì. Àwọn ẹ̀bùn tí ó ṣàn látinú ìhìnrere náà túmọ̀ sí ohungbogbo sí mi—ohungbogbo—nítorínáà nínú ìtiraka láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Bàbá ní Ọ̀run fún wọn, mo ṣe “ìlérí láti pa, àwọn máìlì lọ kí ntó lọ sùn, àti àwọn máìlì láti lọ kí ntó lọ sùn mọ́.” Njẹ́ kí a tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìfẹ́ nínú ọkàn wa, rírìn nínú “ìmọ́lẹ̀ ti ìrètí”19 tí ó ntan ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà ìfojúsọ́nà tí a ti wà fún igba ọdun báyi. Mo jẹ́rí pé ìgbà tí nbọ̀ yío wà bíi kíkún fún iṣẹ́-ìyanu àti alábùnkúnfún lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ìgbà ìṣaájú ti rí. A ní gbogbo èrèdí láti ní ìrètí fún àwọn ìbùkún àní tí ó tóbi ju àwọn wọnnì tí a ti gbà lọ, nítorípé èyí ni iṣẹ́ Ọlọ́run Alágbára Jùlọ, èyí ni Ìjọ ìfihàn títẹ̀síwájú, èyí sì ni ìhìnrere oore-ọ̀fẹ́ àti ìyọ́nú tí kò ní òdiwọ̀n. Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ sí gbogbo òtítọ́ wọ̀nyí àti púpọ̀ síi ní orúkọ̀ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ráńpẹ́

  1. “Àkójá Ẹ̀sìn Krístẹ́nì,” in The Works of William E. Channing (1888), 1004.

  2. 2 Néfì 26:24

  3. Wo Jòhánnù 3:16-17

  4. Mósè 7:62

  5. See Isaiah 2:1–3; Èsékíẹ́lì 37:26; Míkà 4:1–3; Málákì 3:1.

  6. Jòhánnù14:2

  7. See 1 Kọ́ríntì 15:29; Doctrine and Covenants 128:15–17.

  8. See Hébérù 6:19; Étérì 12:4.

  9. Wo Na Zhu and others, “A Novel Coronavirus from Patients with Pneumonia in China, 2019,” New England Journal of Medicine, Feb. 20, 2020, 727–33.

  10. Wo “Examination and Description of Soil Profiles,” in Soil Survey Manual, ed. C. Ditzler, K. Scheffe, and H. C. Monger (2017), nrcs.usda.gov.

  11. Wo Mattéù 22:36–40; Marku 12:29–33; bákannáà wo Léfítíkù 19:18; Deuteronomi 6:1–6.

  12. Wo Eteri 12:4.

  13. Wo Rómù 4:18.

  14. R. J. Snell, “Quiet Hope: A New Year’s Resolution,” Public Discourse: The Journal of the Witherspoon Institute, Dec. 31, 2019, thepublicdiscourse.com/2019/12/59322/.

  15. Esekieli 37–11.

  16. Èyí ni ọ̀rọ̀ náà bí wọ́n ti sáábà ṣe àyípadà rẹ̀. However, the more literal translation is “All hope abandon, ye who enter here” (Dante Alighieri, “The Vision of Hell,“ in Divine Comedy, trans. Henry Francis Cary [1892], canto III, line 9).

  17. “Wa Bá Mi Gbé!” Àwọn orin, no. 166.

  18. Judith Mahlangu (ìpàdé àpapọ̀ èèkàn nítòsí Johannesburg, South Africa, Nov. 10, 2019), in Sydney Walker, “Elder Holland Visits Southeast Africa during ‘Remarkable Time of Growth,’” Church News, Nov. 27, 2019.

  19. 2 Néfì 31:19-20; àfikún àtẹnumọ́.

  20. “Stopping by Woods on a Snowy Evening,” lines 14–16, in The Poetry of Robert Frost: The Collected Poems, ed. Edward Connery Lathem (1969), 225.

  21. 2 Nefì 31:20.