Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Njẹ́ A Kì Yío Ha Tẹ̀síwájú ninu Iṣẹ́ Nlá Yi?
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Njẹ́ A Kì Yío Ha Tẹ̀síwájú ninu Iṣẹ́ Nlá Yi?

A gbọ́dọ̀ rantí oye tí Joseph àti Hyrum Smith san nígbàgbogbo, lẹgbẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé olóòtítọ́ míràn, láti gbé Ìjọ kalẹ̀.

Ẹ ṣé púpọ̀, Ààrẹ, fún irú ìbẹ̀rẹ̀ oníyanu. Ní okòó lé nígba o din márun ọdún sẹ́hìn, ọmọkùnrin kékeré kan ni a bí fún Joseph àti Lucy Mack Smith ní Vermont ní agbègbè kan tí a mọ̀ sí New England ní ihà àríwá ìlà oòrun Amẹ́ríkà.

Joseph and Lucy Mack gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, wọ́n ṣe àṣàrò nínú àwọn ìwé mímọ́, wọ́n gbàdúrà nítòótọ́, wọ́n sì rìn pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.

Wọ́n sọ orúkọ ọmọkùnrin wọn tuntun ní Joseph Smith Kékeré.

Ní ti ẹbí Smith, Brigham Young sọ pé: “Olúwa fi ojú rẹ̀ sí ara [Joseph Smith], àti sí ara bàbá rẹ̀, àti sí ara bàbá bàbà rẹ̀, àti sí ara àwọn aṣaájú wọn ní kedere padà sí ọ̀dọ̀ Abraham, àti lati Abraham sí ìkún omi, láti ìkún omi sí Ẹnọ́kù àti láti Enọ́kù sí Adámù. Òun ti ṣọ́ ẹbí náà àti ẹ̀jẹ̀ náà bí ó ti tàn kákiri láti orísun rẹ̀ títí dé ìbí ọkùnrin náà [Joseph Smith] ni a ti yàn tẹ́lẹ̀ ní ayérayé.”1

Ní jíjẹ́ olólùfẹ́ ẹbí rẹ̀, ní pàtàkì Joseph Kékeré súnmọ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin àgbà Hyrum, ẹnití ó jẹ́ ọdún mẹ́fà ní ọjọ́ orí nígbàtí a bí Joseph.

Ní Oṣù Kẹwàá tí ó kọjá, mo jókòó ní ẹ̀bá okúta ibi idáná tí ó wà ní ibùgbé kékeré àwọn Smith ní Sharon, Vermont, níbití a ti bí Joseph. Mo ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Hyrum fún Joseph mo sì rò nípa rẹ̀ bí ó ti gbe ọmọdé arákùnrin rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì nkọ́ ọ bí yío ti rìn.

Bàbá àti Ìyá Smíth ní ìrírí ìfàsẹ́hìn tí ara ẹni, tí ó fi ipá mú wọn láti kó ẹbí wọn kiri ní ìgbà púpọ̀ kí wọn ó tó fi ìsinmi sí orí New England, tí wọ́n sì fi ìgboyà ṣe ìpinnu láti sún jìnnà sí ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìpínlẹ̀ New York.

Nítorípé ẹbí náà wà ní ìṣọkan, nwọ́n fi ara da àwọn ìpèníjà wọ̀nyí àti pé ní àpapọ̀ wọ́n dojúkọ iṣẹ́ bíbanilẹ́rù ti síṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi lórii ọgọ́rũn éékà (0.4 km2) ilẹ̀ agbègbè onígi ní Manchester, nítòsí Palmyra, New York.

Kò dámi lójú pé púpọ̀ nínú wa mọ àwọn ìdojúkọ ìmí ẹ̀dùn àti àfojúrí tí síṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ gbé sí iwájú ẹbí Smith—síṣán ilẹ̀, gbígbin àwọn igi àti àwọn pápá oko, kíkọ́ ibùgbé onígi kan àti àwọn ile oko miràn, fífi ara ẹni yá bíi òṣìṣẹ́ ojúmọ́, àti síṣe àwọn ohun èlò inú ilé fún títà ní ìgboro.

Ní àkókò tí ẹbí náà dé sí ìwọ̀ oòrùn New York, agbègbè náà ti njó bíi iná pẹ̀lú ìtara ẹ̀sìn—tí a mọ̀ sí Ìtanijí Nlá Ẹẹ̀kejì.

Ní àkókò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ àti wàhálà láàrin àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀lẹ́sìn, Joseph ní ìrírí ìran yíyanilẹ́nu kan, tí a mọ̀ sí Ìran Àkọ́kọ́ loni. A di alábùkúnfún láti ní àwọn kókó àkọsílẹ̀ mẹ́rin látinú èyí tí èmi ó ti mú.

Joseph ṣe àkọsílẹ̀ pé: “Ní àkókò ìtara nlá ti [ẹ̀sìn] yí a pe ọkàn mi sókè sí ìrònú jíjinlẹ̀ àti àìbalẹ̀ ara nlá; ṣùgbọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìmọ̀lára mi jìnlẹ̀ tí ó sì nfi ìgbà gbogbo ní ìmí-ẹ̀dùn, síbẹ̀ mo mú ara mi jìnnà sí gbogbo àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo nwà ní ibi púpọ̀ àwọn ìpàdé wọn ní gbogbo ìgbà tí ààyè bá wà. … [Síbẹ̀] líle tó bẹ́ẹ̀ ni ìdàrúdàpọ̀ àti ìjà ní ààrin oríṣiríṣi àwọn ẹgbẹ́ náà, tí kò fi ṣeéṣe fún ẹnìkan tí ó jẹ́ ọ̀dọ́ bíi èmi ti wà, tí kò sì mọ púpọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn àti àwọn nkan, láti wá sí ìpinnu kan tí ó dájú nípa ẹnití ó tọ́ àti ẹnití kò tọ́.”3

Joseph kọjú sí Bíbélì láti wá àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè rẹ̀ ó sì ka Jákọ́bù 1:5: “Bí ó bá ku ọgbọ́n fún ẹnikẹ́ni nínú yín, kí ó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹnití nfi fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí kìí sì bá-ni-wí; a ó sì fi fún un.”4

Ó ṣe àkíyèsí pé: “Kò sí kan rí tí ẹsẹ ìwé mímọ́ wá pẹ̀lú agbára nlá sí ọkàn ènìyàn ju bí èyí ti ṣe ní àkókò yí sí tèmi. Ó dàbí pé ó wọlé pẹ̀lú ipá nlá sí inú gbogbo ìmọ̀lára ọkàn mi. Mo ronú jinlẹ̀ ní orí rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi àti lẹ́ẹ̀kansíi.”5

Jóseph wá sí ìmọ̀ pé Bíbèlì kò ní gbogbo ìdáhùn nínú sí àwọn ìbéèrè ìgbé ayé; dípò bẹ́ẹ̀, ó kọ́ ọkùnrin àti obìnrin bí wọn ó ti rí àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọn nípa bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ tààrà nípasẹ̀ àdúrà.

Ó fi kún pé: “Nítorínáà, ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ìpinnu mi láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, mo lọ jìnnà sí inú igbó láti gbìyànjú. Ó jẹ́ òwúrọ̀ ọjọ́ dáradára kan, tí ó mọ́ gaara, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé ti ọdún ẹgbẹ̀rún kan ọgọ́rũn mẹ́jọ àti ogún.”6

Ní kété lẹ́hìnnáà, Joseph sọ pé “[ọ̀wọ̀n] ìmọ́lẹ̀ kan sinmi lé mi lórí mo “[sì] rí àwọn Ẹni Nlá méjì, àwọn ẹnití ìmọ́lẹ̀ àti ògo wọn ju gbogbo àpèjúwe, wọ́n ndúró ní òkè orí mi nínú afẹ́fẹ́. Ọ̀kàn lára wọn sọ̀rọ̀ sí mi, ó pè mí ní orúkọ ó sì sọ pé, ní nínawọ́ sí ẹnìkejì—“[Joseph,] Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ ti Rẹ̀!7

Nígbànáà Olùgbàlà sọ̀rọ̀: “Joseph, ọmọ mi, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́. Máa lọ ní ọ̀nà rẹ, rìn nínú àwọn ìlànà mi, kí o sì pa àwọn òfin mi mọ́. Kíyèsíi, èmi ni Olúwa ògo. A kàn mí mọ́ igi fún aráyé, pé gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú orúkọ mi le ní ìyè ayérayé.”8

Joseph fi kun, “Ní kété, nítorínáà, tí mo gba ara mi kalẹ̀, kí nlè ni agbára láti sọ̀rọ̀, ni mo béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹ̀dá Ènìyàn náà tí wọ́n dúró ní òkè orí mi nínú ìmọ́lẹ̀, èwo nínú gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ni ó tọ́.”9

Ó rántí: “Wọ́n sọ fún mi pé gbogbo ẹ̀yà ẹlẹ́sìn ngbàgbọ́ nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí kó tọ́, àti pé kò sí ìkọ̀ọ̀kan lára wọn tí Ọlọ́run gbà bí ìjọ àti ìjọba rẹ̀. Àti pé … ní ìgbàkannáà [mo] [ti] gba ìlérí kan pé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere gbọ́dọ́ wá ní ọjọ́-ọ̀la tí a ti fi hàn sí mi.“

Joseph ṣe àkíyèsí bákannáà pé, “Mo rí ọ̀pọ̀ àwọn ángẹ́lì nínú ìran yi.”11

Títẹ̀lé ìran ológo yi, Joseph kọ pé: “Ọkàn mi kún fún ìfẹ́, àti fún àwọn ọjọ́ púpọ̀ mo le yọ̀ pẹ̀lú ayọ̀ nlá. … Olúwa wà pẹ̀lú mi.”12

Ó jáde láti inú Igbó Onígi Mímọ́ náà láti bẹ̀rẹ̀ ìpalẹ̀mọ́ rẹ̀ láti di wòlíì Ọlọ́run kan,

Joseph bẹ̀rẹ̀ bákannáà láti máa kọ́ ohun tí àwọn wòlíì àtijọ́ ní ìrírí—ìkọ̀sílẹ̀, àtakò, àti inúnibíni. Joseph rántí pípín ohun tí ó ti rí àti gbọ́ pẹ̀lú ọ̀kan lára àwọn alámojútó tí ó ti wà pẹ̀lú ìtara nínú ìsọjí ẹ̀sìn:

“Ó yà mí lẹ́nu púpọ̀ ní ti ìwà rẹ̀; òun ṣe sí ìbánisọ̀rọ̀ mi náà kìí ṣe ní eréfèé nìkan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìkẹ́gàn púpọ̀, ní wíwípé ti èṣù ni gbogbo rẹ̀, pé kò sí irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀ bí àwọn ìran tàbí àwọn ìfihàn mọ́ ni àwọn ọjọ́ wọ̀nyí; pé gbogbo irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀ ti dáwọ́dúró pẹ̀lú àwọn àpóstélì, àti pé kì yío tún sí èyíkéyìí irú wọn mọ́ láé.

Kò pẹ́ ti mo ríi, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, pé bí mo ṣe sọ ìtàn náà ti mú kí ẹ̀tanú ó ru sókè takò mí lọ́pọ̀lọpọ̀ lààrin àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀sìn, òun ni ó sì dá inúnibíni nlá sílẹ̀, èyítí ó tẹ̀síwájú láti máa pọ̀ síi; … Èyí sì wọ́pọ̀ lààrin gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀sìn—gbogbo wọn parapọ̀ láti ṣe inúnibíni sí mi.13

Ní ọdún mẹ́ta lẹ́hìnnáà, ní 1823, àwọn ọ̀run ṣí lẹ́ẹ̀kansíi bí apá kan títẹ̀síwájú Ìmúpadàbọ̀ sípò ti ìhìnrere Jésù Krístì ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Joseph kíyèsíi pé ángẹ́lì kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Moronì farahàn sí i ó sì sọ “pé Ọlọ́run ní iṣẹ́ kan fún mi láti ṣe … [àti pé] ìwé kan wà tí a fi pamọ́, tí a kọ sí orí àwọn àwo wúrà” nínú èyí tí “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhìnrere àìlópin wà … bí a ṣe fifúnni láti ọwọ́ Olùgbàlà sí àwọn olùgbé àtijọ́ náà [ti àwọn Amẹríkà].”14

Ní ìgbẹ̀hìn, Joseph gbà, ó ṣe ìyírọ̀padà, ó sì ṣe àtẹ̀jáde àkọsílẹ̀ àtijọ́ náà, tí a mọ̀ lóni bíi Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

Arákùnrin rẹ̀ Hyrum, ẹnití ó ti jẹ́ alátilẹhìn rẹ̀ léraléra, pàápàá lẹ́hìn iṣẹ́ abẹ ẹsẹ̀ tí ó kún fún ìrora, ati ìdẹ́rùbà ìgbé ayé ní 1813, jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́rìí àwọn àwo wúrà náà. Bákannáà, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn mẹ́fà ọmọ Ìjọ Jésù Krístì nígbàtí wọ́n ṣe àkójọ rẹ̀ ní 1830

Ní ìgbà ayé wọn, Joseph àti Hyrum jọ dojúkọ àwọn ọ̀pọ̀ èrò àti inúnibíni papọ̀. Fún àpẹrẹ, wọ́n jẹ ìrora ní àwọn ipò tí ó burú jùlọ ní Ọgbà Ẹwọn Líberty ní Missouri fún oṣù márũn ní ìgbà òtútù ti 1838-39.

Ní Oṣù Kẹrin 1839, Joseph kọ̀wé sí ìyàwó rẹ̀ Emma ní ìjúwe ipò wọn ní ẹ̀wọ̀n Liberty: “Mo gbàgbọ́ pé nísisìyí ó ti tó oṣù márũn àti ọjọ́ mẹ́fà láti ìgbà tí èmi ti wà ní abẹ́ ìwò ẹlẹ́yà, ti ẹ̀ṣọ́ kan ní òru àti ní ọ̀sán, àti láàrin àwọn ògiri, àwọn ọgbà, àti àwọn ìlẹ̀kùn irin tí npariwo, ti ẹ̀wọ̀n ànìkanwà, dúdú, dídọ̀tí kan. … Wọn ó mú wa kúrò ní [ìhín] yí bí ó ti wù kí ó rí, àwa sì ní inú dídùn sí ohunkóhun tí ó wù kí ó ṣẹlẹ̀ sí wa. Jẹ́ kí ohun tí yíò jẹ́ tiwa, a kò lè wọnú ìhò tó burú ju èyí. … A kò ní fi ìlọ́ra jù ìfẹ́ wa nù fún Liberty ní Agbègbè Clay, Missouri láé. Awa ní ànító rẹ̀ láti wà títí ayé.”16

Ní ìdojúkọ inúnibíni, Hyrum ṣe afihàn ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Olúwa, pẹ̀lú ìdánilójú láti yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ bí ó bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nínú ìbùkún kan tí Hyrum gbà ní 1835 ní abẹ́ ọwọ́ Joseph Smith, Olúwa ṣe ìlérí fún un pé: “Ìwọ yío ní agbára láti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ. Wọn yío lépa ayé rẹ pẹ̀lú ìtara tí kìí rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ yío yọ. IBí inú rẹ bá dùn sí, tí iwọ sì fẹ́, iwọ yío ní agbára pẹ̀lú síṣetán láti fi ayé rẹ; lélẹ̀ láti yin Ọlọ́run lógo.”16

Ní Oṣù Kẹfà 1844, a gbé síwájú Hyrum pé kí ó yàn láti yè tábí láti fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ láti yin Ọlọ́run lógo àti láti “fi èdidi di ẹ̀rí rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀”—nífẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ papọ̀ pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀ ọ̀wọ́n Joseph.17

Ní ọ̀sẹ̀ kan ṣaájú ìrinajò àyànmọ́ sí Carthage, níbití wọ́n ti pa wọ́n nínú ẹ̀jẹ̀ tútù láti ọwọ́ àwọn ojo èrò tí wọ́n kun ojú ara wọn láti yẹra fún mímú, Joseph ṣe àkọsílẹ̀ pé “Mo gba arákùnrin mi Hyrum nímọ̀ràn láti mú àwọn ẹbí rẹ̀ sí orí ọkọ̀ ojú omi tí ó kàn kí ó sì lọ sí Cincinnati.”

Mo ṣì ní ìmọ̀lára ẹ̀dùn ọkàn nlá síbẹ̀ bí mo ṣe rántí ìdáhùn Hyrum: “Joseph, èmi kò le fi ọ́ sílẹ̀.18

Nítorínáà Joseph àti Hyrum lọ sí Carthage, nibití wọn ti di ajẹ́rìíkú fún iṣẹ́ àti orúkọ Kristì.

Ìpolongo gbangba ti pípani sọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Joseph Smith, Wolíì àti Aríran Olúwa, … ti mú Ìwé ti Mọ́mọ́nì jade wá, èyítí ó túmọ̀ nípasẹ̀ ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run, ó sì ti jẹ́ ọ̀nà fún títẹ̀ jáde ní orí àwọn ìpín ilẹ̀ ayé méjì; ó ti rán ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ayérayé, èyí tí ó wà nínú rẹ̀, sí àwọn ìgun mẹ́rẹ̀rin ilẹ̀ ayé; ó ti mú àwọn ìfihàn àti àwọn òfin èyítí ó wà nínú ìwé Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú yi jade wá, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé míràn ti ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́ fún ire àwọn ọmọ ènìyàn; ó kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn Enìyàn Mímọ̀ ti Ọjọ́-ìkẹ̀hìn jọ, ó tẹ ìlú nlá kan dó, ó sì fi òkìkí àti orúkọ kan sílẹ̀ tí kò ṣe é parun. … Àti bí púpọ̀ jùlọ àwọn ẹni àmì òróró Olúwa ní ìgbà àtijọ́, [Joseph] ti fi èdidi dí iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀; bẹ́ẹ̀ náà sì ni arákùnrin rẹ̀ Hyrum. Ní ìyè, wọn kò pínyà, àti ní ikú, wọn kò yà ara wọn!19

Ní àtẹ̀lé ikú ajẹ́rikú, àgọ́ ara Joseph àti Hyrum ni a gbé padà sí Nauvoo, ní wíwẹ̀ àti síṣe lọ́ṣọ̀ọ́ kí àwọn ẹbí Smith ó le rí àwọn olùfẹ́ wọn. Ìyá wọn onìyebíye rántí: “Mo ti fi ìgbà pípẹ́ de gbogbo iṣan, ta gbogbo agbára ọkàn mi jí, mo sì ké pe Ọlọ́run láti fúnmi ní okun; ṣùgbọ́n nígbàtí mo wọ inu yàrá náà, tí mo sì rí àwọn ọmọkunrin mi tí wọ́n pa ní títẹ́ sílẹ̀ àwọn méjééjì lẹ́ẹ̀kannáà ní iwájú mi, àti ti mo gbọ́ ẹkún àti ìkẹ́dùn ẹbí mi, àti ẹkún láti àwọn ètè àwọn ìyàwó, àwọn ọmọ, àwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin, ó pọ̀jù fúnmi. Mo jálulẹ̀ nínù ẹkún sí Olúwa nínú ìrora ẹ̀mí mi, ‘Ọlọ́run Mi! Ọlọ́run Mi! Kínìdí tí ẹ fi gbàgbé ẹbí yí?

Ní àkókò ìbànújẹ́ àti wàhálà náà, ó rántí pé wọ́n sọ pé, “Ìyá, máṣe sunkún nítorí wa; a ti ṣẹgun ayé nípa ìfẹ́.”21

Nítòótọ́ wọ́n ti ṣẹgun ayé. Jóseph àti Hyrum Smith, bíi ti àwọn olõtọ́ Ẹni Mímọ́ wọnnì tí a ṣe àpèjúwe wọn nínú ìwé Ìfihàn, “jáde wá láti inú ìpọ́njú nlá, wọ́n sì ti fọ àwọn ẹ̀wù wọn, wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọdọ́-agùtàn náà wọ́n [sì] … Níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, wọ́n sì nsìn ín ní ọ̀sán àti ní òru nínú tẹ́mpìlì rẹ̀: àti pé ẹni náà tí ó jókòó ní orí ìtẹ́ yío gbé ní ààrin wọn.

“Wọn kì yíò kébi mọ́, bẹ́ẹ̀ni wọn kì yíò pòùngbẹ mọ́, bẹ́ẹ̀ni òòrùn kì yíò pa wọ́n mọ́, tàbí èyíkéyi ooru.

“Nítorí Ọ̀dọ́-àgùtàn tí ó wà ní ààrin ìtẹ́ ọba yíò bọ́ wọn, yíò sì darí wọn lọ sí orísun ìyè ti àwọn omi: Ọlọ́run yíò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.”22

Bí a ti nṣe ayẹyẹ ìgbà aláyọ̀ yí, àjọ̀dún igba ọdún ti Ìran Àkọ́kọ́, a nílati máa fi ìgbà gbogbo rántí oye tí Joseph àti Hyrum Smith san, pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ àwọn míràn tí wọ́n jẹ́ olõtọ́ ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé, láti ṣe àgbékalẹ̀ Ìjọ náà kí ẹ̀yin àti èmi le gbádùn ọ̀pọ̀ àwọn ìbùkún àti àwọn òtítọ́ tí a ti fihàn tí a ní lóni. A kò gbọdọ̀ gbàgbé ìgbàgbọ́ wọn láé!

Mo ti fi ìgbà púpọ̀ ronú ìdí rẹ̀ tí Joseph àti Hyrum àti àwọn ẹbí wọn fi nílati jìyà púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ó le jẹ́ pé wọ́n mọ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìjìyà wọn ní àwọn ọ̀nà tí ìbá má ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ láìsí rẹ̀. Nípasẹ̀ rẹ̀, wọ́n ronú lórí Gethsemánì àti àgbélébu ti Olùgbàlà. Bí Paulù ti sọ, “Nítorí ní ti Krístì ẹyin ni a ti yọ̀ọ̀da fún, kìí ṣe láti gbà á gbọ́ níkan, ṣùgbọ́n láti jiyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú.”23

Ṣaájú ikú rẹ̀ ní 1844, Joseph kọ ìwé nínú ẹ̀mí sí àwọn Ẹni Mímọ́. Ó jẹ́ ìpè sí iṣẹ́, èyítí ó tẹ̀síwájú ní inú Ìjọ lóni

“Ẹyin arákùnrin [àti arábìnrin], njẹ́ a kì yío ha tẹ̀síwájú ninu iṣẹ́ nlá yi? Ẹ lọ síwájú àti pé kìí ṣe sí ẹ̀hìn. Ìgboyà, ẹ̀yin arákùnrin [àti arábìnrin]; àti síwájú, síwájú sí ìṣẹ́gun naa! …

“Nítorínáà, bí ìjọ kan àti ènìyàn kan, àti bí Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, ẹ jẹ́kí a fi ọrẹ ẹbọ kan fún Oluwa nínú òdodo.”24

Bí a ṣe nfetísílẹ̀ sí Ẹmí ní àkókò ayẹyẹ àjọ̀dún ti igba ọdún yi, ní opin ọ̀sẹ̀ yi, ẹ ronú nípa ọrẹ ẹbọ wo ni ẹ ó fi fún Oluwa nínú òdodo ní àwọn ọjọ́ tí mbọ̀. Ẹ ní ìgboyà—ẹ pín in pẹ̀lú ẹnikan tí ẹ gbgbẹ́kẹ̀lé, àti ní pàtàkì jùlọ, ẹ jọ̀wọ́ ẹ wá àkókò láti ṣe é!

Mo mọ̀ pé inú Olùgbàlà máa ndùn nígbàtí a bá fi ọrẹ ẹbọ kan fún Un láti inú ọkàn wa nínú òdodo, gẹ́gẹ́ bí Ó ti ní inú dídùn pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ ìgbàgbọ́ ti àwọn arákùnrin pàtàkì wọnnì, Joseph àti Hyrum Smith, àti gbogbo àwọn Ẹni Mímọ́ onígbàgbọ́ míràn Nípa èyí ni mo jẹ́ ẹ̀rí ni orúkọ mímọ́ Olúwa wa Jésù Krístì, àmín.