Àwọn Ìwé Mímọ́
Mọ́mọ́nì 7


Orí 7

Mọ́mọ́nì pè àwọn ará Lámánì ti ọjọ́ ìkẹhìn láti gbà Krístì gbọ́, gbà ìhìn-rere rẹ̀, kí wọn ó sì rí ìgbàlà—Gbogbo ẹniti ó gba Bíbélì gbọ́ ni yíò gba Ìwé ti Mọ́mónì gbọ́ pẹ̀lú. Ní ìwọ̀n ọdún 385 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, emí yíò bá ìyókù àwọn ènìyàn yĩ tí a dásí sọ àwọn ohun díẹ̀, bí o bá ri bẹ̃ pe Ọlọ́run yíò fi àwọn ọ̀rọ̀ mi fún wọn, kí wọ́n ó lè mọ̀ nípà àwọn ohun àwọn baba wọn; bẹ̃ni, mo nbá yín sọ̀rọ̀, ẹyin ìyókù ìdílé Isráẹ́lì; ìwọ̀nyì sì ni ọ̀rọ̀ ti èmí sọ:

2 Kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé ìdílé Isráẹ́lì ni ẹ̀yin í ṣe.

3 Kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé ẹ níláti wa sí ìrònúpìwàdà, bí kò bá rí bẹ̃ ẹ kò lè rí ìgbàlà.

4 Kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé ẹ níláti gbé ohun-ìjà ogun yín lélẹ́, kí ẹ̀yin ó má sì ní inú dídùn mọ́ sí ìtàjẹ̀sílẹ̀, kí ẹ̀yin ó má sì gbe wọn mọ, àfi bí Ọlọ́run bá pa á láṣẹ fún yin.

5 Kí ẹyin kí ó mọ̀ pe ẹ níláti ní irú ìmọ̀ èyítí àwọn baba yín ni, kí ẹ sì ronúpìwàdà kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn àìṣedẽdé yín, kí ẹ sì gba Jésù Krístì gbọ́, pé oun ni Ọmọ Ọlọ́run, àti pé a pa á láti ọwọ́ àwọn Jũ, àti nípasẹ̀ agbára Bàbá ó tún ti jínde, nípasẹ̀ èyítí o ti gba ìṣẹ́gun lórí isà-òkú; àti pẹ̀lú nínú rẹ̀ ni oró ikú di gbígbémì.

6 Ó sì mú ajinde òkú ṣẹ, nípasẹ̀ èyítí a ó gbé ènìyàn dìde láti dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀.

7 Ó sì ti mú ìràpadà ayé ṣẹ, nípasẹ̀ èyítí ẹnikẹ́ni tí à bá rí láìlẹ́bi ní iwájú rẹ̀ ní ojọ́ ìdájọ́, ni a ó fi fún láti gbe ni ọdọ Ọlọ́run nínú ìjọba rẹ̀, láti máa kọrin ìyìn ní àìdánudúró pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ akọrin tí ó wá lókè ọ̀run, sí Bàbá, àti sí Ọmọ, àti sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí wọn í ṣe Ọlọ́run kan, nínú ipò ayọ̀ èyítí kò ní òpin.

8 Nitorinã, ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì ṣe ìrìbọmí ní orúkọ Jésù, kí ẹ sì dì ìhìn-rere Krístì mú, èyítí a ó gbe síwájú yín, kì í ṣe nínú àkọsílẹ̀ yĩ nìkan, ṣùgbọ́n nínú àkọsílẹ̀ èyítí yíò wá sí ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí láti ọ̀dọ̀ àwọn Jũ pẹ̀lú, àkọsílẹ̀ èyítí yíò wá láti ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí sí ọ̀dọ̀ yín.

9 Nítorí ẹ kíyèsĩ, a kọ eleyĩ kí ẹ́yin ó lè gbà èyí nnì gbọ́; bí ẹ̀yin bá sì gbà èyí nnì gbọ́ ẹ̀yin yíò gba èyí gbọ pẹ̀lú; bí ẹ̀yin bá sì gba èyí gbọ ẹyin yíò mọ́ nipa àwọn baba yin, àti àwọn iṣẹ tí ó yanilẹ́nu ti a ṣe nípa agbara Ọlọ́run lãrín wọn.

10 Ẹ̀yin yíò sì mọ̀ pẹ̀lú pé ìyókù irú-ọmọ Jákọ́bù ni ẹ̀yin í ṣe; nitorinã ní a ṣe kà yín mọ́ àwọn ènìyàn ti májẹ̀mú àkọ́kọ́; bí o ba si ri bẹ̃ pe ẹ̀yin gbà Krístì gbọ́, tí a sì ṣe ìrìbọmí fun yín, ní àkọ́kọ́ pẹ̀lú omi, àti lẹhin eyi pẹ̀lú ina àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, ní títẹ̀lé àpẹrẹ Olùgbàlà wa, gẹ́gẹ́bí èyítí ó ti pa láṣẹ fún wa, yíò sì dara fún yín ní ọjọ ìdájọ́. Amin.