Àwọn Ìwé Mímọ́
Mọ́mọ́nì 3


Orí 3

Mọ́mọ́nì nkígbe ìrònúpìwàdà sí àwọn ará Nífáì—Wọn ri ìṣẹ́gun nla gbà, wọ́n sì yangàn nínú agbára ara wọn—Mọ́mọ́nì kọ̀ láti darí wọn, àdúrà rẹ̀ fún wọn sì wà ní àìnígbàgbọ́—Ìwé ti Mọ́mọ́nì npè àwọn ẹ̀yà mejila ìdílé Ísraẹlì láti gbà ìhìn-rere nã gbọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 360 sí 362 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 O sì ṣe tí àwọn ará Lámánì kò tún wá bá àwọn ará Nífáì jagun títí ọdún mẹ́wã tún fi kọjá lọ. Ẹ sì kíyèsĩ, mo sì ti mú kí àwọn ènìyàn mi, àwọn ara Nífáì, kí wọn ó múrasílẹ̀ nínú ilẹ̀ wọn àti àwọn ohun ìjà wọn dè ìgbà ogun.

2 Ó sì ṣe tí Olúwa wí fún mi pe: kígbe sí àwọn ènìyàn yĩ—Ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí ẹ sì ṣe ìrìbọmi, kí ẹ sì padà tún ìjọ mi kọ́, á ó sì dá yin sí.

3 Èmi sì kígbe sí àwọn ènìyàn yĩ, sùgbọ́n lásán ni; wọ́n kò sì rí i pé Olúwa ní ó dá àwọn sí, tí ó sì fún wọ́n ní ãyè fun ìrònúpìwada. Ẹ sì kíyèsĩ wọn sé ọkàn wọn le sí Olúwa Ọlọ́run wọn.

4 O sì ṣe lẹ́hìn tí ọdún kẹwa yĩ ti kojá lọ, lápapọ̀ tí ó jẹ ọ̀tà lé lọ̃dúnrún ọdún láti ìgbà tí Krístì ti wá, ọba àwọn ara Lámánì fí èpístélì kan ránṣẹ́ sí mi, èyítí ó sọ ọ́ di mímọ̀ fún mi pé wọn nṣe ìmúrasílẹ̀ láti tún padà wá íbá wa jagun.

5 O sì ṣe tí emí mú kí àwọn ènìyàn mi kó ara wọn jọ nínú ilẹ̀ Ibi-Ahoro, sí inú ìlú-nlá kan tí ó wà ní ãlà, ní ẹ̀bá ọ̀nà tõró nnì èyítí ó já sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù.

6 Níbẹ̀ ni àwa si kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa sí, kí àwa ó lè dá àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lamanì dúró, kí wọn ó má lè mú èyíkéyi nínú àwọn ilẹ̀ wa; nítorínã nì àwa mọ́ odi mọ́ wọn pẹlú gbogbo àwọn ọmọ ogun wa.

7 O sì ṣe nínú ọ̀tà lé lọ̃dúnrún ọdún àti ọdún àkọ́kọ́ àwọn ará Lámánì sì sọ̀kalẹ̀ sínú ìlú-nlá Ibi-Ahoro láti bá wa jagun; ó sì ṣe nínú ọdún nã tí àwa sì lù wọ́n, tóbẹ̃ tí wọ́n tún padà sínú ilẹ̀ wọn.

8 Nínú ọdún ọ̀tà lé lọ̃dunrun àti ọdún kéjì ni wọ́n sì tún ṣọ̀kalẹ̀ wá bá wa jagun. Àwa sì tún lù wọ́n, a sì pa púpọ̀ nínú wọn, a sì kó àwọn òkú wọn jù sínú òkun.

9 Àti nísisìyí, nítorí ohun nla yĩ ti àwọn ènìyàn mi, àwọn ará Nífáì, ti ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀sí yangàn nínú agbára ara wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí fí àwọn ọ̀run búra pé àwọn yíò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn arákùnrin wọn tí àwọn ọ̀tá wọ́n ti pa.

10 Wọn sì fí àwọn ọ̀run búra, àti pẹ̀lú ìtẹ́ Ọlọ́run, pé àwọn yíò gòkè lọ bá áwọn ọ̀tá wọn jagun, tí wọn yíò sì ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ nã.

11 Ó sì ṣe tí emí, Mọ́mọ́nì, sì kọ̀ jálẹ̀ láti àkókò yĩ lọ láti jẹ́ olùdarí àti olórí àwọn ènìyàn yĩ, nítorí ìwà búburú àti ìwà ẽrí wọn.

12 Ẹ kíyèsĩ, emí ti síwájú wọn, l’áìṣírò ìwà búburú wọn, èmi ti síwájú wọn ní ọpọ̀lọpọ̀ ìgba lọ́ sí ogun, mo sì ti fẹ́ràn wọn, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ Ọlọ́run èyítí ngbé ínú mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; mo sì ti gbádúrà tọkàn-tọkàn sí Ọlọ́run mi ní gbogbo ọjọ nitori wọn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, o jẹ áìní ìgbàgbọ́, nitori sísé tí wọ́n sé ọkàn wọn le.

13 Ìgbà mẹta ni èmi sì ti gbà wọ́n kuro lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, tí wọn kò sì ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

14 Nígbàtí wọ́n sí ti búra pẹ̀lú gbogbo àwọn ohun ti Olúwa wa àti Olùgbàlà Jésù Krístì ti kà léewọ̀ fún wọn, pé àwọn yíò gòkè tọ̀ àwọn ọ̀tá wọn lọ ni ogun, tí wọn yíò sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn arákùnrin wọn, ẹ kíyèsĩ ohùn Olúwa tọ̀ mí wa, tí ó wípé:

15 Tèmi ni ẹ̀san, ẹmí yíò gbèsan; àti nítorípé àwọn ènìyàn yĩ kò ronúpìwàdà lẹ́hintí mo ti gbà wọ́n, ẹ kíyèsí i, a ó ke wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé.

16 O sì ṣe tí èmi kọ̀ jálẹ̀ láti gòke lọ láti kọlũ àwọn ọ́tá mi; emí sì ṣe àní gẹ́gẹ́bí Olúwa ti pa á láṣẹ fun mi; emí sì dúró bí ẹlẹ́rĩ aláìniṣẹ́ láti fi àwọn ohun tí èmi rí àti tí èmi gbọ́ hàn fún aráyé, ní ìbámu pẹ̀lú ìfihàn ti Ẹ̀mí èyítí ó ti jẹ́rĩ nipa àwọn ohun tí mbọ̀wá.

17 Nitorinã ni emí ṣe kọ̀wé sí yín, ẹyin Kèfèri, àti sí yín, ẹ̀yin ìdílé Isráẹ́lì, nígbàtí iṣẹ́ nã yíò bèrẹ̀, ti ẹ̀yin yíò ṣetán láti múrasílẹ̀ láti padà lọ sí ilẹ̀ ìní yin;

18 Bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ, emí kọ̀wé sí gbogbo ìkangun ayé; bẹ̃ni, síi yin, ẹ̀yin ẹ̀yà méjìlá Isráẹ́lì, tí a ó ṣe ìdájọ́ yín gẹ́gẹ́bí àwọn iṣẹ́ yín láti ọ́wọ́ àwọn mejìlá nnì tí Jésù yàn láti jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù.

19 Emí sì kọwé sí ìyókù àwọn ènìyàn yĩ pẹ̀lú, tí a ó ṣe ìdájọ́ fún pẹ̀lú nípasẹ̀ àwọn méjìlá nnì tí Jésù yàn nínú ilẹ̀ yĩ; a o sì se ìdájọ́ fún wọn nípasẹ̀ àwọn méjìlá kejì tí Jésù yàn nínú ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù.

20 Àwọn ohun wọ̀nyí sì ni Ẹmí fi hàn sí mi; nitorinã ni èmi sì kọ̀wé sí gbogbo yín. Àti nítorínã ni emí ṣe kọ̀wé si yín, kí ẹyin ó lè mọ̀ pé gbogbo yín gbọ́dọ̀ dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì, bẹ̃ni, gbogbo ọkàn tí í ṣe ti ènìyàn ìdílé Ádámù; ẹ̀yin sì gbọ́dọ̀ dúró láti gba ìdájọ́ lórí iṣẹ́ yín, bóyá rere ni wọn í ṣe tàbí ibi;

21 Àti pẹ̀lú pé kí ẹ̀yin ó lè gbà ìhìn-rere Jésù Krístì gbọ́, èyítí ẹ̀yin yíò ní lãrín yín; àti pẹ̀lú pé kí àwọn Jũ, àwọn ènìyàn májẹ̀mú Olúwa, ó lè ní ẹ̀rí míràn yàtọ̀ sí ẹnití wọ́n rí tí wọ́n sì gbọ́, pé Jésù, ẹ́nití wọn pa, ni Krístì kannã àti Ọlọ́run kannã.

22 Emí sì ní ìfẹ́ láti rọ̀ gbogbo ẹ̀yin ìkangun ayé láti ronúpìwàdà kí ẹ sì múrasílẹ̀ láti dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì.