Àwọn Ìwé Mímọ́
Jákọ́bù 7


Orí 7

Ṣẹ́rẹ́mù sẹ́ Krístì, ó bá Jákọ́bù jà, ó bẽrè fún àmì, Ọlọ́run sì kọlũ—Gbogbo àwọn wòlĩ ti sọ̀rọ̀ nípa Krístì àti ètùtù rẹ̀—Àwọn ará Nífáì gbé ìgbé ayé nwọn gẹ́gẹ́bí alárìnkiri, a bí wọn nínú lãlã, àwọn ará Lámánì sì korira wọn. Ní ìwọ̀n ọdún 544 sí 421 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, ó sì ṣe lẹ́hìn tí ọdún díẹ̀ ti kọjá lọ, ọkùnrin kan sì jáde wá ní ãrín àwọn ará Nífáì tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Ṣẹ́rẹ́mù.

2 Ó sì ṣe tí, ó bẹ̀rẹ̀sí wãsù ní ãrín àwọn ènìyàn nã, àti láti kéde fún nwọn wípé kò yẹ kí Krístì wà. Ó sì wãsù ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun ẹ̀tàn sí àwọn ènìyàn nã; èyí ni ó sì ṣe kí ó lè bi ẹ̀kọ́ Krístì ṣubú.

3 Ó sì ṣe lãlã taratara kí ó lè darí ọkàn àwọn ènìyàn nã kúrò, tóbẹ̃ tí ó darí ọkàn púpọ̀ kúrò; tí òun sì mọ̀ wípé èmi, Jákọ́bù, ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì ẹnítí ó nbọ̀, ó wá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà láti tọ̀ mí wá.

4 Ó sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n, tí ó fi ní ìmọ̀ pípé nínú èdè àwọn ènìyàn nã; nítorí-èyi ó lè lo ẹ̀tàn púpọ̀, àti agbára ọ̀rọ̀ sísọ, gẹ́gẹ́bí ti agbára àrékérekè èṣù.

5 Ó sì ní ìrètí láti yí ọkàn mi padà kúrò nínú ìgbàgbọ́ nã l’áìṣírò fún àwọn ìfihàn àti àwọn ohun púpọ̀ tí mo ti rí nípa àwọn nkan wọ̀nyí; nítorítí èmi ti rí àwọn ángẹ́lì nítòọ́tọ́, nwọ́n sì ti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún mi. Àti pẹ̀lú, mo ti gbọ́ ohùn Olúwa tí ó sì nbá mi sọ̀rọ̀ ní pàtó ọ̀rọ̀, láti ìgbà dé ìgbà; nítorí-èyi, ọkàn mi kò lè yí padà.

6 Ó sì ṣe, tí ó tọ̀ mí wá, báyĩ ni ó sì bá mi sọ̀rọ̀, pé: Arákùnrin Jákọ́bù, èmi ti wá ãyè láti bá ọ sọ̀rọ̀; nítorítí èmi ti gbọ́ mo sì mọ̀ pẹ̀lú pé ìwọ nkãkiri lọ́pọ̀lọpọ̀, o nwãsù nípa èyítí ò npè ní ìhìn-rere, tàbí ẹ̀kọ́ Krístì.

7 Ìwọ sì ti darí púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí kí wọn lè lòdì sí ọ̀nà òtítọ́ Ọlọ́run, kí wọn má sì pa òfin Mósè mọ́ èyítí ó jẹ́ ọ̀nà tí ó tọ́; kí wọn sì yí òfin Mósè padà sí sísin ẹ̀dá kan èyítí ìwọ sọ wípé ó nbọ̀wá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọgọ̃rún ọdún sí àkókò yí. Àti nísisìyí, kíyèsĩ èmi, Ṣẹ́rẹ́mù, sọ fún ọ wípé ọ̀rọ̀ àìtọ́ ni èyí; nítorítí ẹnìkan kò mọ̀ nípa ohun bẹ̃; nítorítí kò lè sọ nípa àwọn ohun tí ó nbọ̀wá. Báyĩ sì ni Ṣẹ́rẹ́mù gbógun tì mí.

8 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Olúwa Ọlọ́run tú Ẹ̀mí rẹ̀ jáde sínú ọkàn mi, tóbẹ̃gẹ́ tí mo fi dãmú rẹ̀ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀.

9 Èmi sì wí fún un: Ìwọ ha nsẹ́ Krístì èyítí ó nbọ̀? Ó sì wípé: Tí Krístì kan yíò bá wà èmi kò ní sẹ́ẹ; ṣùgbọ́n èmi mọ̀ wípé kò sí Krístì kankan, bẹ̃ni kò sí rí, kò sì lè sí láéláé.

10 Èmi sì wí fún un: Njẹ́ ìwọ gba àwọn ìwé-mímọ́ gbọ́? Òun sì wípé, bẹ̃ni.

11 Èmi sì wí fún un: Nígbànã nwọn kò yé ọ; nítorítí nwọ́n jẹ́rĩ sí Jésù Krístì nítòọ́tọ́. Kíyèsĩ, mo wí fún ọ pé kò sí nínú àwọn wòlĩ tí ó ti kọ tàbí tí ó sọ tẹ́lẹ̀ bíkòṣepé nwọ́n ti sọ nípa Krístì yĩ.

12 Èyí nìkan sì kọ́—a ti fíi hàn mí, nítorítí mo ti gbọ́ mo sì ti ri; a sì ti fíi hàn mí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́; nítorí-èyi, èmi mọ̀ pé tí kò bá sí ètùtù, gbogbo aráyé ni yíò ṣègbé.

13 Ó sì ṣe tí, ó wí fún mi pé: Fi àmì kan hàn mí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́ yìi nípasẹ̀ ẹnití ìwọ ní ìmọ̀ púpọ̀.

14 Èmi sì sọ fún un: Kíni èmi tí èmi yíò dán Ọlọ́run wò pé kí ó fi àmi kan hàn ọ́ nínú ohun tí ìwọ mọ̀ pé òtítọ́ ni? Síbẹ̀, ìwọ yíò sẹ́ ẹ, nítorípé ìwọ jẹ́ ti èṣù. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, kĩ ṣe ìfẹ́ mi ni kí a ṣe; ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run yíò bá kọlũ ọ́, kí èyí jẹ́ àmì fún ọ wípé ó ní agbára, ní ọ̀run àti ní ayé; àti pé, Krístì yíò wá. Àti pé, ìfẹ́ tìrẹ, A! Olúwa, ni kí a ṣe, kĩ sĩ ṣe tèmi.

15 Ó sì ṣe, pé nígbàtí èmi, Jákọ́bù, ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, agbára Olúwa wá sórí rẹ̀, tó bẹ̃gẹ́ tí ó ṣubú lulẹ̀. Ó sì ṣe tí a bọ́ ọ fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀.

16 Ó sì ṣe tí ó sì sọ fún àwọn ènìyàn nã, wípé: Ẹ péjọ ní ọ̀la, nítorítí èmi yíò kú; nítorí-èyi, mo ní ìfẹ́ láti bá àwọn ènìyàn nã sọ̀rọ̀ kí èmi ó tó kú.

17 Ó sì ṣe pé ní ọjọ́ kejì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ pọ̀; ó sì bá nwọn sọ̀rọ̀ ní kedere, ó sì kọ̀ àwọn nkan wọnnì tí ó ti kọ́ nwọn, ó sì jẹ́rĩ Krístì nã, àti agbára Ẹ̀mí Mímọ́, àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì.

18 Ó sì bá nwọn sọ̀rọ̀ ní kedere, wípé a ti ṣi òun lọ́nà nípasẹ̀ agbára èṣù. Ó sì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run àpãdì, àti ayérayé àti ìyà ayérayé.

19 Ó sì wípé: Mo bẹ̀rù pé kí èmi ó ma ti dá ẹ̀ṣẹ̀ àìnídàríjì nnì, nítorítí mo ti purọ́ mọ́ Ọlọ́run; nítorítí mo sẹ́ Krístì, mo sì sọ wípé mo ti gba àwọn ìwé-mímọ́ nã gbọ́; bẹ̃ nwọn jẹ́rĩ rẹ̀ nítoótọ́. Àti nítorípé èmi ti purọ́ báyĩ sí Ọlọ́run, mo bẹ̀rù lọ́pọ̀lọpọ̀ kí ọ̀rọ̀ mi ma bã burú jọjọ; ṣùgbọ́n èmi jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run.

20 Ó sì ṣe, nígbàtí ó ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ yí, kò lè sọ̀rọ̀ mọ́ ó sì jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.

21 Nígbàtí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nã ti ríi wípé ó sọ àwọn nkan wọ̀nyí ní kété tí ó fẹ́rẹ̀ kú, ẹnu yà nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀; tó bẹ̃gẹ̃ tí agbára Ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ sórí nwọn, ó sì borí nwọn tóbẹ̃ tí nwọ́n ṣubú lulẹ̀.

22 Nísisìyí, ìṣẹ̀lẹ̀ yĩ dùnmọ́ èmi, Jákọ́bù, nítorítí mo ti bẽrè bẹ̃ lọ́wọ́ Bàbá mi tí nbẹ ní ọ́run; nítorítí ó gbọ́ igbe mi, ó sì dáhùn àdúrà mi.

23 Ó sì ṣe tí àlãfíà àti ìfẹ́ Ọlọ́run padà sãrin àwọn ènìyàn nã; nwọ́n sì wádĩ àwọn ìwé mímọ́, nwọ́n kò sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ọkùnrin búburú yĩ mọ́.

24 Ó sì ṣe, tí a lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà láti mú àwọn ará Lámánì padà sí ípò ìmọ̀ òtítọ́; ṣùgbọ́n asán ni ó já sí, nítorítí nwọn ní inúdídun nínú ogun àti ìtàjẹ̀sílẹ̀, nwọ́n sì ní ìkórìrà àilópin sí wa, àwọn arákùnrin nwọn. Nwọ́n sì nwá ọ̀nà nípa agbára ohun ìjà nwọn, láti pa wá run láìdẹ́kun.

25 Nítorí-èyi, àwọn ará Nífáì gbáradì dè nwọ́n pẹ̀lú àwọn ohun ìjà nwọn, àti pẹ̀lú gbogbo agbára nwọn, ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run àti àpáta ìgbàlà nwọn; nítorí-èyi, nwọ́n di aṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá nwọn.

26 Ó sì ṣe, tí èmi, Jákọ́kù, bẹ̀rẹ̀sí darúgbó; tí a sì nṣe àkọsílẹ̀ ìwé ìrántí àwọn ènìyàn wọ̀nyí lórí àwo Nífáì míràn, nítorí-èyi, mo parí ìwé ìrántí yĩ, mo sì nsọ wípé mo ti kọọ́ gẹ́gẹ́bí ìmọ mi tí ó dárajùlọ, nípa sísọ pé àsìkò ti kọjá lọ pẹ̀lú wa, àti pé ìgbà ayé wa kọjá lọ bí ẹni wípé àwa nlá àlá, nítorípé a sì jẹ́ aláìlárá àti ọlọ́wọ̀ ènìyàn, alárìnkiri, ẹnití a lé jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù, tí a bí nínú ìpọ́njú, nínú aginjù, tí àwọn arákùnrin wa sì koríra wa, èyítí ó fa àwọn ogun àti àwọn ìjà; nítorí-èyi àwa ṣọ̀fọ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.

27 Ati èmi, Jákọ́bù, sì ríi pé nkò ní pẹ́ lọ sí isà òkú; nítorí-èyi, mo wí fún ọmọkùnrin mi, Énọ́sì, pé: Gba àwọn àwo wọ̀nyí. Èmi sì sọ àwọn ohun tí Nífáì arákùnrin mi ti pa láṣẹ fún mi, ó sì ṣèlérí ìgbọràn sí àwọn àṣẹ nã. Mo sì dẹ́kun ìwé kíkọ sórí àwọn àwo wọ̀nyí, ìwé kíkọ èyítí ó kéré; si akàwé, mo kí ọ pé ó dìgbóṣe, ní ìrètí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn arákùnrin mi yíò ka àwọn ọ̀rọ̀ mi. Ẹ̀yin arákùnrin, ó dìgbóṣe.