2010–2019
Agbára láti Borí Ọ̀tá
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Agbára láti Borí Ọ̀tá

Báwo ni a ṣe le rí àlàáfíà, rántí ẹnití a jẹ́, kí a sì borí àwọn “I” mẹ́ta ti ọ̀tá?

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ẹ ṣé fún gbogbo ohun tí ẹ̀ nṣe láti di, àti láti ran àwọn míràn lọ́wọ́ làti di, àtẹ̀lé òtítọ́ Jésù Krístì àti láti gbádùn àwọn ìbùkún tẹ̀mpìlì mímọ́. Ẹ ṣeun fún inúrere yín. Ẹ jẹ́ ìyanu; ẹ jẹ́ arẹwà.

Àdúrà mi ni pé a ó dá ipa fífẹsẹ̀múlẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ mọ̀ bí a ti nní òye ní kíkún pé a jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. “Ẹbí Náà: Ìkéde Kan sí Aráyé” sọ pé: “Gbogbo àwọn ẹ̀dá ènìyàn—ọkùnrin àti obìnrin—ni a dá ní àwòrán Ọlọ́run. Ẹnìkọ̀ọ̀kan jẹ́ àyànfẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin àwọn òbí ọ̀run, àti pé, bẹ́ẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìwà-àbínibí ti ọ̀run àti àyànmọ́.”1 A jẹ́ “àṣàyàn ẹ̀mí ẹnití a pa mọ́ láti jáde wá ní ìgbà kíkún àwọn àkókò láti kópa nínú fífi àwọn ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún iṣẹ́ nlá ti ọjọ́-ìkẹhìn.”2 Ààrẹ Russel M. Nelson kéde pe: “A kọ́ yín nínú ayé ẹ̀mí láti múra yín sílẹ̀ fún ohunkóhun àti ohun gbogbo tí ẹ ó dojúkọ nínú abala ìkẹhìn ti àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí (wo D&C 138:56). Ìkọ́ni náà dúró nínú yín!.”3

Ẹ jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run tí a yàn. Ẹ ní agbára láti borí ọ̀tá. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀tá náà mọ irú ẹnití ẹ jẹ́. Ó mọ ogún ìní yín àtọ̀runwá ó sì nwá láti dín ìleṣe yín tí àyé àti ti ọ̀run kúrú nípa lílo àwọn “I” mẹ́ta:

  • Ìtànjẹ

  • Ìdààmú

  • Ìrẹ̀wẹ̀sì

Ìtànjẹ

Ọtá lo irinṣẹ́ ìtànjẹ ní àwọn ọjọ́ Mósè. Olúwa kéde sí Mósè:

“Kíyèsi, ìwọ nì ọmọ mi, ...

“Èmi ní iṣẹ́ kan fún ọ, ... Ìwọ sì wà ní àwòrán Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo tèmi.”4

Ní kété lẹ́hìn ìran ológo yìí, Sátánì gbìdánwò láti tan Mósè jẹ. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lò jọni lójú: “Mósè, ọmọ ènìyàn, fi orí balẹ̀ fún mi.”5 Ìtànjẹ náà kò wà nínú ìpè láti fi orí balẹ̀ fún Sátánì nìkan ṣùgbọ́n bákannáà nínú ọ̀nà tí ó fi júwe Mósè bíi ọmọ ènìyàn. Ẹ rántí, Olúwa ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún Mósè pé ó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, tí a dá ní àfijọ ti Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo.

Ọtá náà kò dáwọ́dúró nínú ìgbìdánwò rẹ̀ láti tan Mósè, ṣùgbọ́n Mósè tàpá síi, ó wípé, “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì, nítorí Ọlọ́run kan yìí nìkan ni èmi ó fi orí balẹ̀ fún, èyítí í ṣe Ọlọ́run ògo.”6 Mósè rántí ẹnití í ṣe—ọmọ Ọlọ́run.

Àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa sí Mósè ní àmúlò sí ẹ̀yin àti sí èmi. A dá wa ní àwòrán ti Ọlọ́run, Òun sì ní iṣẹ́ kan fún wa láti ṣe. Ọtá ngbìdánwò láti tànnijẹ nípa mímú kí a gbàgbé ẹnití a jẹ́ nítòótọ́. Bí a kò bá ní òye ẹnití a jẹ́, nígbànáà yío ṣòro láti mọ ẹnití a le dà.

Ìdààmú

Ọtá ngbìdánwò bákannáà láti dáámú wa kúrò ní ọ̀dọ̀ Krístì àti ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú Rẹ̀. Alàgbà Ronald A. Rasband ṣe àbápín àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Èrò ọ̀tá ni láti dààmú wa kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí ti ẹ̀mí, nígbàqtí ìfẹ́-inú ti Olúwa jẹ́ láti fi òye yé wa kí ó sì lò wá nínú iṣẹ́ Rẹ̀.”7

Ní ọjọ́ tiwa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìdààmú ní ó wà, nínú wọn ni Twitter, Facebook, Instagram, àwọn eré ìdárayá lóríṣiríṣi, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ìpele gíga ti ìmọ̀ ẹ̀rọ wọ̀nyí jẹ́ ìyanu, ṣùgbọ́n bí a kò bá ṣọ́ra, wọ́n le dààmú wa kúrò ní síṣe ìmúṣẹ agbára àtọ̀runwá wa. Lílò wọ́n bí ó ti yẹ le mú agbára ọ̀run jáde wá, kí ó sì fún wa ní ààyè láti jẹ́rìí àwọn iṣẹ́ ìyanu bí a ti nlépa láti kó àwọn Isráẹlì fífọ́nká ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìkelè.

Ẹ jẹ́kí a ṣọ́ra kí a ma sì ṣe àìròtẹ́lẹ̀ ní bí a ti nlo ìmọ̀ ẹ̀rọ.8 Ní léraléra kí a máa lépa àwọn ọ̀nà tí ìmọ̀ ẹrọ fi le fà wá súnmọ́ ọ̀dọ̀ Olùgbàlà síi, tí yíó sì fún ní ààyè láti ṣe iṣẹ́ Rẹ̀ yọrí bí a ti nmúra fún Ìpadàbọ̀ Rẹ̀ Ẹẹ̀kejì.

Ìrẹ̀wẹ̀sì

Ní ìparí, ìfẹ́ inú ọ̀tá ni fún wa láti rẹ̀wẹ̀sì. A le ní ìrẹ̀wẹ̀sì nígbàtí a bá nfi ara wa wé àwọn ẹlòmíràn, tàbí tí a rò pé ìgbé ayé wa kò tó àwọn ìrètí, àní tiwa pàápàá.

Nígbàtí mo bẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ oyè dókítà mi, mo ní ìmọ̀lára ìrẹ̀wẹ̀sì. Ètò ẹ̀kọ́ náà gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rin péré ní ọdún náà; àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yókù sì mọ̀wé. Wọ́n ní esì ìdánrawò tí ó dárajù àti ìrírí ẹnú iṣẹ́ ní àwọn ipò ọ̀gá alámojútó, wọ́n sì ṣe àfihàn ìfọkànbalẹ̀ nínú àwọn agbára wọn. Lẹ́hìn ọ̀sẹ̀ méjì mi àkọ́kọ́ nínú ètò náà, àwọn ìmọ̀lára ìrẹ̀wẹ̀sì àti iyèméjì bẹ̀rẹ̀ sí gbá mi mú—tí ó fẹ́rẹ̀ borí mi.

Mo pinnu pé bí èmi ó bá parí ètò ọlọ́dún-mẹ́rin yìí, mo níláti parí kíkà Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní simẹ́sítà kọ̀ọ̀kan. Ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bí mo ti nkàwé, mo dá ìkéde ti Olùgbàlà mọ̀ pé Ẹ̀mí Mímọ́ yío kọ́ mi ní ohun gbogbo àti pé yío sì mú ohun gbogbo wá sí ìrántí mi.9 Ó tún fi ẹsẹ̀ ẹnití èmi í ṣe múlẹ̀ bíi ọmọ Ọlọ́run, ó rán mi létí láti máṣe fi ara mi wé àwọn ẹlòmíràn, ó sì fún mi ní ìgbẹkẹ̀lé nínú ojúṣe àtọ̀runwá mi láti yege.9

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jí ìdùnnú yín gbé Ẹ máṣe fi ara yín wé àwọn ẹlòmíràn. Ẹ jọ̀wọ́ rántí àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ni ti Olùgbàlà: “Àlàáfíà ni mo fi fún yín, àlàáfíà mi ni mo fi fún yín: kìí ṣe bí ayé ti í funni, ni èmi fi fún yín. Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ó wárìrì.”10

Nítorínáà báwo ni a ó ti ṣe? Báwo ni a ṣe le rí àlàáfíà yìí, kí a rántí ẹnití a jẹ́, kí a sì borí àwọn “I” mẹ́ta ti ọ̀tá?

Àkọ́kọ́, ẹ rántí pé ìkínní àti òfin nlá ni láti fẹ́ràn Ọlọ́run pẹ̀lú ọkàn, ipá, inú, àti agbára wa.11 Gbogbo ohun tí a nṣe níláti jẹ́ yíyánilára nípa ìfẹ́ wa fún Òun àti fún Ọmọ Rẹ̀. Bí a ṣe nmú ìfẹ́ wa gbèrú fún Wọn nípa pípa àwọn òfin Wọn mọ́, agbára wa láti fẹ́ràn ara wa àti láti fẹ́ràn àwọn ẹlòmíràn yío pọ̀ síi. A ó bẹ̀rẹ̀ láti máa sin ẹbí, àwọn ọ̀rẹ́, àti àwọn aládugbò nítorípé a ó rí wọn bí Olùgbàlà ti rí wọn—bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run.12

Ìkejì, ẹ máa gbàdúrà sí Baba ní orúkọ Jésù Krístì ní ojojúmọ́, ní ojojúmọ́, ní ojojúmọ́.13 Nípasẹ̀ àdúrà ni a ti le ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run kí a sì fi ìfẹ́ wa hàn sí I. Nípasẹ̀ àdúrà a nfi ìmoore hàn a sì nbèèrè fún okun àti ìgboyà láti fi ìfẹ́ tiwa sí inú ti Ọlọ́run, kí a sì jẹ́ títọ́ àti dídarí nínú ohun gbogbo.

Mo gbà yín níyànjú láti “gbàdúrà sí Baba pẹ̀lú gbogbo agbára ti ọkàn, pé kí a le kún yín pẹ̀lú ifẹ́ yìí, ... pé kí ẹ le di ọmọkùnrin [àti ọmọbìnrin] ti Ọlọ́run; pé nígbàtí òun yío fi ara hàn àwa ó bíi rẹ̀.”14

Ìkẹta, ẹ kà kí ẹ sì ṣe àṣàrò nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní ojojúmọ́, ní ojojúmọ́, ní ojojúmọ́.15 Àwọn àṣàrò síṣe mi nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì máa nlọ dáradára jù nígbàtí mo bá nkàá pẹ̀lú ìbéèrè kan ní inú. Bí a ti nkàá pẹ̀lú ìbéèrè kan, a le gba ìfihàn kí a sì dáamọ̀ pé Wòlíì Joseph Smith sọ òtítọ́ nígbàtí ó kéde pé, “Ìwé ti Mọ́mọ́nì [ni] ó pé ju èyíkéyí ìwé lọ ní orí ilẹ̀ ayé, ... Ọkùnrin [tàbí obìrin yíò] súnmọ́ Ọlọ́run síi nípa gbígbé nínú àwọn ìlànà rẹ̀, ju ti èyíkéyí ìwé míràn lọ.”16 Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní àwọn ọ̀rọ̀ Krístì nínú, ó sì nràn wá lọ́wọ́ láti rántí ẹnítí a jẹ́.

Ní ìparí, ẹ máa jẹ oúnjẹ Olúwa pẹ̀lú àdúrà ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú àti ìlànà oyèàlùfáà, pẹ̀lú oúnjẹ Olúwa, ni agbára ìwà-bí-Ọlọ́run ti nfi ara hàn nínú ayé wa.17 Alàgbà David A. Bednar kọ́ni pé: “ìlànà ti oúnjẹ Olúwa jẹ́ ìpé mímọ́ àti léraléra láti ronúpìwàdà nítòótọ́ àti láti jẹ́ sísọ di ọ̀tun nípa ti ẹ̀mí. Ìṣe ti jíjẹ oúnjẹ Olúwa, ní òun nìkan, kò le mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kúrò. Ṣùgbọ́n bí a ti nmúra pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tí a sì nkópa nínú ìlànà mímọ́ yìí pẹ̀lú ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́, nígbànáà ìlérí ni pé kí a lè máà fi ìgbà gbogbo ní Ẹ̀mí Olúwa láti wà pẹ̀lú wa.”18

Bí a ti nfi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa náà, a nrántí ìjìyà Rẹ̀ nínú ọgbà mímọ́ náà tí a pè ní Gẹ́tsémánì, àti ìrúbọ Rẹ̀ ní orí àgbélèbú. A fi ìmoore hàn sí Baba fún rírán Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Kanṣoṣo, Olùgbàla wa wá, à sì fi ìfẹ́ wa hàn láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ àti láti máa rántí Rẹ̀ nígbà gbogbo.19 Ìfòyeyéni wà tí ó so mọ́ oúnjẹ Olúwa—ó jẹ́ ti ara ẹni, ó ní agbára, a sì nílò rẹ̀.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, mo ṣe ìlérí pé bí a ṣe ntiraka láti fẹ́ Ọlọ́run ẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, láti gbàdúrà ní orúkọ Jésù Krístì, láti ṣe àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì, tí a sì njẹ oúnjẹ Olúwa pẹ̀lú àdúrà, a ó ní agbára, pẹ̀lú agbára ti Olúwa, láti borí àwọn ìṣe ẹlẹ́tàn ti ọ̀tá, láti ṣe àdínkù àwọn ìdààmú tí ó ké agbára àtọ̀runwá wa kúrú, àti láti tako ìrẹ̀wẹ̀sì tí ó ndín agbára wa kù láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Baba wa Ọrun àti Ọmọ Rẹ̀. A ó ní òye ni kíkún ní ti ẹnití a jẹ́ bii ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo ṣe àbápín ìfẹ́ mi pẹ̀lú yín mo sì kéde ẹ̀rí mi pé mo mọ̀ pé Bàbá Ọ̀run wà láàyè àti pé Jésù ni Krístì. Mo nifẹ Wọn. Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn jẹ́ ìjọba Ọlọ́run ní orí ilẹ̀ ayé. A ní iṣẹ́ rírán àtọ̀runwá kan láti múra ayé sílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹẹ̀kejì ti Mèsáìà náà, Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.