2010–2019
Ari nípa Agbára ti Ìwé Mọ́mọ́nì
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Ari nípa Agbára ti Ìwé Mọ́mọ́nì

Gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ ní ìrírí kí a sì rí wọn nípa agbára àwọn òtítọ́ nínú Ìwé Mọ́mọ́nì.

Nígbàtí à nbẹ ilé wọn wò, ọ̀kan lára àwọn ìbèèrè tí mò fẹ́ràn láti bèèrè lọ́wọ́ àwọn olùyípadà lemọ́lemọ́ ni bí àwọn àti ẹbí wọn ṣe kọ́ nípa Ìjọ àti bí wọ́n ti wá ṣe ìrìbomi. Kò já mọ́ nkankan tí ẹni náà ní àkokò náà bá jẹ́ ọmọ ìjọ tó ṣe déédé tàbí tí kò lọ ìjọ déédé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Ìdáhùn náà njẹ́ ọ̀kannáà nígbàgbogbo: pẹ̀lú ẹ̀rín àti ìwò wọn tó ntàn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí nsọ ìtàn bí a ṣe rí wọn. Lotitọ́, ó dàbí pé ìtàn ti ìyípadà nígbàgbogbo ni ìtàn bí wọ́n ti rí wa.

Jésù Krístì Fúnrarẹ̀ ni Olúwa àwọn ohun tó ti sọnù. Ó nṣètọ́jú fún àwọn ohun tó sọnù. Dájúdájù ìyẹn ni ìdí tí Ó fi kọ́ àwọn òwe mẹta tí a rí ní orí mẹẹdogun ti Lúkùthe Orí Kẹẹdogun ti Lúkù: òwe ti àgùtàn tí ó nù, edewó tó nù, àti, níparí, ọmọ oninakuna. Gbogbo ìtàn wọ̀nyí ní ohunkan tó wọ́pọ̀: Kò já mọ́ nkankan ìdí tí wọ́n fi sọnu. Kò já mọ́ nkankan àní tí wọ́n bá nìfura pé wọ́n sọnù. Ìmọ̀lára ti ayọ̀ ọlọ́lá tó jọba paruwo pé, “Ẹ bá mi yọ; nítorí mo ri [ohun] tó sọnù.”1 Ní òpin, kò sí ohun tó sọnu fún Un lotitọ2

Ẹ gbà mí láyè láti ṣe àbápín ọ̀kan lára àwọn ohun iyebíye jù sí mi pẹ̀lú yín ní ọ̀sán yí—ìtàn bí a ṣe rí èmi fúnrami.

Kété kí ntó pé ọdún mẹẹdogun, ọnkú mi Manuel Bustos pè mí, láti wá lo àkokò díẹ̀ pẹ̀lú òun àti ẹbí rẹ̀ ní United States. Èyí yíò jẹ́ ànfàní nla fún mi láti kọ́ Èdè gẹ̀ẹ́sì díẹ̀. Ọnkú mi ti yípada sí Ìjọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, ó sì ní ẹ̀mí iṣẹ́ ìhìnrere nlá. Bóyá ìdí ni èyí tí ìyá mi, láìmọ̀ sí mi, fi ba sọ̀rọ̀ tí ó sì wí fun pé òun ó gba ìfipè náà ní ipò kan: pé kò ní gbìyànjú láti mú mi di ọmọ Ìjọ rẹ. A jẹ́ Catholic, a sì ti jẹ́ bẹ́ẹ̀ fún ìran púpọ̀, kò sì sí ìdí láti yípadà. Ọnkú mi fi taratara gbà bẹ́ẹ̀ ó sì pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́ dé àmì àní tí kò fi fẹ́ dáhùn àwọn ìbèèrè jẹ́jẹ́ nípa Ìjọ.

Bẹ́ẹ̀ni, ohun tí ọnkú mi àti ìyàwó rẹ̀ dídára, Marjorie, kò lè yẹra fún ni wíwà ní ẹni tí wọ́n jẹ́.3

Wọ́n fún mi ní yàrá kan tí a ṣe ibi ìkójọ àwọn ìwé nlá sí. Mo lè ri pé ibi ìkójọ ìwé yí ni bíi igba ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní oríṣiríṣi èdè wà, ogun wọ́n ní Spanish.

Níjọ kan, nínú fífẹ́látimọ̀, mo mú ẹ̀dá Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan ní Spanish sílẹ̀.

Àwòrán
Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní Spanish

Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dà pẹ̀lú àwọ ìbora rẹ́súrẹ́sú, pẹ̀lú àwòrán ángẹ́lì Mórónì ní iwájú. Ní ṣíṣíi, ní ojú ewé ìkínní ni a kọ àwọn ìlérí wọ̀nyí sí: “Àti nígbatí ẹ̀yin yíò sì rí àwọn ohun wọ̀nyí gbà, èmi gbà yín níyànjú pé kí ẹ bẽrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, ní orukọ Krístí, bí àwọn ohun wọ̀nyí kò bá íṣe òtítọ́; bí ẹ̀yin yíò bá sì bẽrè, tọkàn-tọkàn pẹ̀lú gbogbo ìfẹ́ inú yín, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Krístì, yíò fi òtítọ́ inú rẹ̀ hàn sí yín, nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ̀.”

Nígbànáà ó sì fikun pé: “Nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ lè mọ òtítọ́ ohun gbogbo.”5

Ó ṣòrò láti ṣàlàyé ipá tí awọn ìwé mímọ́ wọ̀nyí ní nínú àti ọkàn mi. Ní òtítọ́, èmi kò wá “òtítọ́ náà.” Mo ṣì wà ní èwe, ní ìdùnnú pẹ̀lú ayé rẹ̀, gbígbádùn ọ̀làjú titun yí.

Bí ó tilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, pẹ̀lú ìlérí náà nínú mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí ka ìwé náà níkọ̀kọ̀. Bí mo ṣe nkàá si, mo ní ìmọ̀ pé tí mo bá fi òdodo nifẹ láti rí ohunkóhun nínú èyí, kí nyáà tètè bẹ̀rẹ̀ láti gbàdúrà. A sì mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbàtí ẹ bá pinnu kìí ṣe láti kàá nìkan ṣùgbọ́n láti gbàdúrà bákannáà nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ó dára, ohun tó ṣẹ̀lẹ̀ sí mi gan nìyẹn. Ó jẹ́ ohunkan tó ṣe pàtàkì tó jẹ́ araọ̀tọ̀—bẹ́ẹ̀ni, bi ohun kannáà tó ṣẹlẹ̀ sí míllíọ̀nù àwọn míràn káàkiri ayé. Mo wá láti mọ̀ nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́ pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ òtítọ́.

Lẹ́hìnnáà mo lọ bá ọnkú mi láti ṣàlàyé síi ohun tó ṣẹlẹ̀ àti pé mo ṣetán láti ṣèrìbọmi. Ọnkú kò lè gba ìyàlẹ́nu rẹ̀ mọ́ra. Ó wọnú ọkọ̀ rẹ̀, wakọ̀ lọ sí ojúkọ̀ òfúrufú, ó sì padàdé pẹ̀lú ìwé ìrìnnà ọkọ̀ òfúrufú mi láti fò padà sílé, pẹ̀lú àkọsílẹ̀ ránpẹ́ sí ìyá mi tí ó kan wípé, “Èmi kò ní ohunkóhun íṣe pẹ̀lú èyí!”

Ní ọ̀nà kan ó jẹ́ òótọ́. A ti rí mi tààrà nípasẹ̀ agbára Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ lè wà tí wọ́n a ti rí nipa ìyanu àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere yíká ayé, ní gbogbo ọ̀ràn nípa àṣwọn ọ̀ọn oníyanu. Tàbí bóyá wọ́n a ti rí wọn nípasẹ̀ ọ̀rẹ́ tí Ọlọ́run mọ́ọ́mọ̀ fi sí ipá ọ̀nà wa. Àní ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé a ti rí wọn nípasẹ̀ ẹnìkan látinú ìran yí tàbí nìpasẹ̀ ọ̀kan lára àwọn bàbánlá wọn.5 Eyikeyi ọ̀ràn náà, ní èrò láti ní ìlọsíwájú sí ìyípadà araẹni òtítọ́, láìpẹ́ sànju lẹ̀hìnnáà, gbogbo wọn gbọ́dọ̀ ní ìrírí kí a sì rí wọn nípasẹ̀ agbára àwọn òtítọ́ tí ó wà nínú Ìwé ti Mọ́mọ́ni. Ní ìgbà kannáà, wọ́n gbọ́dọ̀ pinnu ní ara wọn láti ṣe ìfarasìn líle sí Ọlọ́run pé wọn yóò tiraka láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.

Ní pípadà sí Buenos Aires, ìyá mi damọ̀ pé mo fẹ́ láti ṣe ìribọmi lotitọ́. Látìgbà ti mo ti ní ẹ̀mí oríkunkun bákan, dípò títakò mí, ó fọgbọ́n faramọ́ mi. Àti pé láì mọ̀, ó ṣe ìfọrọ̀wánilẹ́nuwò ìrìbọmi mi fúnrarẹ̀. Lódodo, àní mo gbàgbọ́ pé ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò rẹ̀ jinlẹ̀ ju ti àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wọnnì nṣe. Ó wí fún mi pé: “Tí ó bá fẹ́ ṣe ìrìbọmi, èmi ó ṣe àtìlẹhìn rẹ̀. Ṣùgbọ́n èmi ó bi ọ́ ni àwọn ìbèèrè kan èmi ó sì fẹ kí ó ronú jinlẹ̀ dáadáa kí o fi òtìtọ́ dà mi lóhùn. Ṣé o gbà láti lọ sí ilé-ìjọsìn ni gbogbo ọjọ́ ìsinmi?

Mo wí fun pé, “Bẹ́ẹ̀ni, bẹ́ẹ̀ni, èmi ó ṣe ìyẹn.”

“Ṣé o ní èrò bí ilé ìjọsin ṣe jìnnà sí?”

Bẹ́ẹ̀ni, mo mọ̀,” ni mo wí.

Ó fèsì, “Ó dára, tí ó bá ṣe ìrìbọmi, èmi ó ri dájú pé o lọ ibẹ̀.” Lẹ́hìnnáà ó béèrè tí èmi bá nifẹ láti máṣe mu ọtí líle tàbí musìgá.

Mo da lóhùn pé, bẹ́ẹ̀ni, bẹ́ẹ̀ni, èmi ó ṣe ìyẹn bákannáà.”

Sí èyí tí ó fikun pe, “Tí ìwọ bá ṣe ìrìbọmi, èmi ó mu dájú pé ìyẹn rí bẹ́ẹ̀. Ó sì tẹ̀síwájú lórí rẹ̀ ní ọ̀nà náà pẹ̀lú gbogbo òfin.

Ọnkú mi ti pe ìyá mi láti sọ fun pé kò má dàmú, pé èmi o yanjú gbogbo èyí láìpẹ́. Ọdún mẹrin lẹ́hìnnáà, nígbàtí mo gba ìpè láti sìn ní ibi Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Uruguay Montevideo, ìyá mi pe ọnkú mi láti bií ìgbàtí ẹ̀mi ó yanjú gbogbo èyí. Òtitọ́ ìbẹ̀ ni pé látìgbà tí mo ti ṣe ìrìbọmi, òun ti di iyá onídùnnú si.

Mo wá mọ̀ pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì ṣe kókó nínú ètò ìyípadà nípasẹ níní ìrírí ìlérí náà lọ́wọ́kan pé “ènìyàn yíò súnmọ́ Ọlọ́run si ní gbígbé nípa àwọn ìgbìrò rẹ̀.”3

Néfì ṣàlàyé gbùngbun èrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní ọ̀nà yí:

“Nítorí a ṣiṣẹ́ láìsinmi láti kọ̀wé, láti yí àwọn ọmọ wa lọkàn padà, àti àwọn arákùnrin wa pẹ̀lú, láti gbàgbọ́ nínú Krístì, àti láti Ọlọ́run làjà. ...

“[Nítorínáà] a sì nsọ̀rọ̀ nípa Krístì, a nyọ̀ nínú Krístì, a nwãsù nípa Krístì, a nsọtẹ́lẹ̀ nípa Krístì, a sì nkọ̀wé gẹ́gẹ́bí àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ wa, kí àwọn ọmọ wa lè mọ́ orísun èwo ni àwọn lè wò fún ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ wọn.”4

Gbogbo Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni ó wà pẹ̀lú àwọn èrò mímọ́ kannáà.

Fún ìdí èyí, olùkàwé kankan yíò farasí àṣàrò rẹ̀ lódodo, pẹ̀lú ẹ̀mí àdúràr, kò ní kọ́ nípa Krístì nìkan ṣùgbọ́n yíò kọ́ látọ̀dọ̀ Krístì—nípàtàkì tí wọ́n bá ṣe ìpinnu láti “gbìyànjú ìwàrere ọ̀rọ̀ náà”8 tí wọn kò sì kọ ọ́ láìpé-ọjọ́ nítorí àìgbàgbọ́9 npasẹ̀ ohun tí àwọn míràn sọ nípa àwọn ohun ti wọn kò kà rí..

Ààrẹ Rusell M. Nelson ròó pé: “Nígbàtí mo ronú nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì, mo ronú nípa ọ̀rọ̀ agbára náà. Àwọn òtítọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní agbára láti wòsàn, tùnínú, múpadàbọ̀sípò, tùlára, fúnlókun, pẹ̀tùsí, àti mú ìyárí bá ẹ̀mí.”7

Ìfipè mi ní ọ̀sán yí sí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, láìka bí a ṣe jẹ́ ọmọ Ìjọ pẹ́ sí, ni láti fàyè gba agbára àwọn òtítọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì láti rí wa àti láti dìmọ́wá lẹ́ẹ̀kan si, àti ní ọjọ́ sí ọjọ́ kí a fi taratara wá ìfihàn araẹni. Yíò ṣe bẹ́ẹ̀ tí a bá fàyè gbà á.

Mo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere Jésù Krístì nínú àti pé Ẹ̀mí Mímọ́ yíò fi ìdí òtítọ́ rẹ̀ múlẹ̀ nígbàkan sí ìgbàkan sí ẹnikẹ́ni tí, ó bá nwá ìmọ̀ sí ìgbàlà ẹ̀mí wọn, pẹ̀lú ọkàn òdodo.8 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Luke 15:6bákannáà wo àwọn ẹsẹ 9, 32.

  2. Ní ọgbọ́ gbígbòòrò rẹ̀, àkọsílẹ̀ àwọn ìwé mímọ́ fún àsọtẹ́lẹ̀ tí ó sọ̀rọ̀ nípa ìkojọ ti àwọn ẹ̀yà Isráẹ́lì tó sọnù (woRussell M. Nelson, “The Gathering of Scattered Israel,” Liahona, Nov. 2006, 79–82). Àní bíotilẹjẹ́pé wọ́n sọnù, wọn kò sọnù síi (wo 3 Nephi 17:4). Bákannáà, ó dùmọ́ni láti ṣàkíyèsí pé wọn kò damọ̀ pé wọn sọnù títí ìgbà tí a ó rí wọn, nípàtàkì nígbàtí wọ́n gba ìbùkùn bàbánlé wọn.

  3. Alàgbà Dieter F. Uchtdorf quoted Saint Francis of Assisi when he said, “Preach the gospel at all times and if necessary, use words” (“Waiting on the Road to Damascus,” Liahona, May 2011, 77; see also William Fay and Linda Evans Shepherd, Share Jesus without Fear [1999], 22).

  4. Mórónì 10:4–5.

  5. Ìtàn ìyípadà ti bàbánlá wa ni ìtàn wa bákannáà Alàgbà William R. Walker taught, “It would be a wonderful thing if every Latter-day Saint knew the conversion stories of their forefathers” (“Live True to the Faith,” Liahona, May 2014, 97). Nígbànáà, gbogbo wa ní ọ̀nà kan ni a ti rí tààrà tàbí nípa àwọn bàbánla, ọpẹ́ fún Bàbá wa Ọ̀run, ẹni tí ó mọ òpin láti ìbẹ̀rẹ̀ (wo Abraham 2:8).

  6. Ìfihàn sí Ìwé ti Mọ́mọ́nì; bákannáà wo Álmà 31:5.

  7. 2 Nephi 25:23, 26.

  8. Álmà 31:5.

  9. Wo Álmà 32:28.

  10. Russell M. Nelson, “The Book of Mormon: What Would Your Life Be Like without It?Liahona, Nov. 2017, 62.

  11. Wo 3 Nífáì 5:20.