2010–2019
Bíbu Ọlá fún Orúkọ Rẹ̀
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Bíbu Ọlá fún Orúkọ Rẹ̀

Pẹ̀lú májẹ̀mú ìdánimọ̀ àti jíjẹ́ ara kan, a pè wá nípa orúkọ ti Jésù Krístì.

Bí àwọn òbí ti nfi ìtara dúró fún bíbí ọmọ kan, wọ́n ní ojúṣe ti yíyan orúkọ fún ọmọ wọn tuntun náà. Bóyá nígbàtí a bí ọ, o gba orúkọ kan tí a ti nfi fúnni nínú ẹbí rẹ láti ìrandíran. Tàbí bóyá orúkọ tí a fifún ọ jẹ́ èyítí ó gbajúmọ̀ ní ọdún tàbí ní agbègbè tí a bí ọ.

Wòlíì Hẹ́lámánì àti ìyàwó rẹ̀ fi àwọn orúkọ ẹbí tí ó nítumọ̀ fún àwọn ọmọdé-kùnrin wọn Néfì àti Léhì. Hẹ́lámánì lẹ́hìnnáà sọ fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé:

“Èmi ti fi orúkọ àwọn òbí wa àkọ́kọ́ fún yín ... pé nígbàtí ẹ̀yin bá rántí orúkọ yín ẹ̀yin yío le rántí wọn; àti nígbàtí ẹ̀yin bá rántí wọn, ẹ̀yin yio rántí àwọn iṣẹ́ wọn; ... pé a sọ ọ́, a sì kọ ọ́ bákannáà, pé wọ́n dára.”

“Nítorínáà, ẹyin ọmọ mi, èmi fẹ́ pé kí ẹ̀yin ó ṣe èyíinì tí ó dára.”1

Orúkọ ti Néfì àti ti Léhì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ràntí àwọn iṣẹ́ rere ti àwọn baba nlá wọn, ó sì wú wọn lórí láti ṣe rere bákannáà.

Ẹ̀yin arábìnrin, ibikíbi tí a ngbé, èdè tí a nsọ, tàbí bóyá a jẹ́ ẹni ọdún mẹ́jọ tàbí ọgọ́rũn ọdún ó lé mẹ́jọ, gbogbo wa ṣe àjọpín orúkọ pàtàkì kan tí ó ní irú àwọn èrò kannáà wọ̀nyí .

“Nítorí iye [àwa] tí a bá ti rì bọmi sí inú Krístì ti gbé Krístì wọ̀ ... nítorí gbogbo [wa] jẹ́ ọ̀kan nínú Krístì Jésù.”2

Bíi ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, “a kọ́kọ́ jẹ́ ẹ̀jẹ́ síṣetán wa láti gba orúkọ Krístì sí ara wa ... nípa ìlànà ìrìbọmi.”3 Nípasẹ̀ májẹ̀mú yìí, a ṣe ìlérí láti rántí Rẹ̀ nígbà gbogbo, láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, àti láti sin àwọn ẹlòmíràn. Síṣetán wa láti pa májẹ̀mú yí mọ́ ni a nsọ di ọ̀tun ní Ọjọ́ Ìsinmi kọ̀ọ̀kan nígbàtí a bá pín nínú oúnjẹ Olúwa tí a sì yọ̀ lẹ́ẹ̀kansíi nínú ìbùkún ti “rírìn nínú ọ̀tun ìyè.”4

Orúkọ tí a fifún wa ní ìgbà ìbí nfi ìdánimọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa hàn, ó sì nfún wa ní jíjẹ́ ara kan ní ààrin àwọn ẹbí wa ti ayé. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, nígbàtí a di “àtúnbí” ní ibi ìrìbọmi, a mú òye wa níti ẹnití a jẹ́ gbòòrò síi. “Nítorí májẹ̀mu tí ẹ̀yin ti dá, a ó pè yín ní ọmọ Krístì, ... nítori ẹ kíyèsíi, ... ẹ̀yin di ọmọ bíbí rẹ̀ nípa ti ẹ̀mí; nítorí ẹ̀yin wí pé ọkàn yín ti yípadà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀; nítorínáà, a bíi yín nínú rẹ̀.”5

Báyí, pẹ̀lú májẹ̀mú ìdánimọ̀ àti jíjẹ́ ara kan, a pè wá nípa orúkọ ti Jésù Krístì. Àti pé “kì yíò sí orúkọ kankan míràn tí a fifún ni, tàbí ọ̀nà míràn, tàbí ipa nípa èyítí ìgbàlà lè wá fún àwọn ọmọ ènìyàn, bíkòṣe nínú àti nípasẹ̀ orúkọ Krístì nìkan, Olúwa Olódùmarè.”6

Orúkọ Jésù jẹ́ mímọ̀ fún ìgbà pípẹ́ ṣaájú ìbí Rẹ̀. Sí Ọba Benjamin, ángẹ́lì kan sọtẹ́lẹ̀ pé, “A ó sì pè é ní Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, ... ìyá rẹ̀ ni a ó sì pè ní Màríà.”7 Iṣẹ́ Rẹ̀ ti “ìfẹ́ ìràpadà”8 ni a sọ di mímọ̀ bákannáà sí àwọn ọmọ Ọlọ́run nígbà-kugbà tí ìhìnrere ti wà ní orí ilẹ̀ ayé, láti ìgbà Adámù àti Éfà títí di ọjọ́ ìsisìyí, kí wọn ó le mọ̀ “orísun wo ni àwọn le wò fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”9

Ní ọdún tó kọjá, Ààrẹ Russell M. Nelson nawọ́ “ẹ̀bẹ̀ bíi ìsọtẹ́lẹ̀ kan” sí àwọn arábìnrin láti “tún ọjọ́ iwájú ṣe nípa síṣe ìrànlọ́wọ́ láti kó Isráẹ́lì fífọ́nka jọ.” Ó pè wá láti ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì kí a sì “ṣe àmì sí ẹsẹ kọ̀ọ̀kan tí ó sọ̀rọ̀ nípa tàbí tí ó tọ́ka sí Olùgbàlà.” Ó sọ pé kí a “jẹ́ pẹ̀lú èrò inú ní sísọ̀rọ̀ nípa Krístì, yíyọ̀ nínú Krístì, àti wíwàásù nípa Krístì pẹ̀lú ẹbí [wa] àti àwọn ọ̀rẹ́. Bóyá ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí dá àwọn èso ìlérí rẹ̀ mọ̀ pé “ẹ̀yin àti àwọn yío jẹ́ fífà súnmọ́ ọ̀dọ̀ Olùgbàlà síi. ... Àti pé àwọn ìyípadà, àní àwọn iṣẹ́-ìyanu, yíò bẹ̀rẹ̀ síí ṣẹlẹ̀.”10

Ìlérí wa láti fi ìgbà gbogbo rántí Olùgbàla nfún wa ní okun láti dúró fún òtítọ́ àti òdodo—bóyá a wà ní ààrin àwọn èrò nlá tàbí nínú àwọn ibi tí a dá nìkan wà, níbití ẹnikẹ́ni kò mọ ohun tí a nṣe bíkòṣe Ọlọ́run. Nígbàtí a bá nrántí Rẹ̀ àti Orúkọ Rẹ̀ tí a njẹ́, a kò ní ààyè fún àwọn àfiwé jíjá ara ẹni kulẹ̀ tàbí àwọn ìdájọ́ àṣejù. Pẹ̀lú ojú wa ní ara Olùgbàlà, a nrí ara wa fún ẹnití a jẹ́ gan—ọmọ Ọlọ́run kan tí a mọ rírì rẹ̀.

Rírántí májẹ̀mú wa nmú àwọn àníyàn ayé dákẹ́ jẹ́, ó nyí iyèméjì ara ẹni padà sí ìgboyà, ó sì nfúnni ní ìrètí ní àwọn àkókò àdánwò.

Àti nígbàtí a bá kọsẹ̀ tí a sì ṣubú nínú ìtẹ̀síwájú wa ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú náà, a kàn níláti rántí orúkọ Rẹ̀ àti ìfẹ́ni-àánú Rẹ̀ sí wa. “Nítorítí ó ní gbogbo agbára, gbogbo ọgbọ́n, àti gbogbo òye; ó ní ìmọ̀ ohun gbogbo, òun sì jẹ́ Ẹni alàánú ... sí àwọn wọnnì tí wọ́n bá ronúpìwàdà tí wọ́n sì gba orúkọ rẹ̀ gbọ́.”11 Dájúdájú, kò sí ìró tí ó dùn ju orúkọ Jésù lọ sí gbogbo àwọn ẹnití nlépa pẹ̀lú ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́, láti “ṣe dáradára síi àti láti di dáradára síi.”12

Ààrẹ Nelson kọ́ni pé: “Ọjọ́ náà ti lọ nígbàtí ẹ le jẹ́ Kristíẹnì dídákẹ́jẹ́ àti tí ó ní ìtura. Ẹ̀sìn yín kìí ṣe nípa fífi ara hàn fún ìjọ ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ó jẹ́ nípa fífi ara hàn bíi ọmọlẹ́hìn tòótọ́ láti àárọ̀ Ọjọ́ Ìsimi títí di alẹ́ Sátidé. ... Kò sí ohun náà bíi irú jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn Olúwa Jésù Krístì fún ‘apákan-àkókò’.”13

Síṣetán wa láti gba orúkọ Krístì sí ara wa ju síṣe pàṣípààrọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ lásán lọ. Kìí ṣe ìlérí asán tàbí àṣà dídọ́gbọ́n. Kìí ṣe ohun ìlànà láti kọjá tàbí orúkọ àkọlé tí a nso mọ́ra. Kìí ṣe ohun sísọ kan tí a kàn le gbé sí orí àgbékà tàbí fi kọ́ ara ògiri. Tirẹ̀ jẹ́ orúkọ kan tí a “nwọ̀,”14 ní kíkọ sínú ọkàn wa, àti “fífín sí àwọn ìwò ojú [wa].”15

Ọrẹ-ẹbọ ètùtu ti Olùgbàlà níláti jẹ́ rírántí, nígbà gbogbo, nípasẹ̀ àwọn èrò, àwọn ìṣe, àti àwọn ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Kìí ṣe pé Òun rántí orúkọ wa nìkan, ṣùgbọ́n Óun nrántí wa nígbà gbogbo. Olùgbàlà wí pé:

“Nítorí obìnrin ha lè gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀ bí, tí kì yíò fi ṣe ìyọ́nú sí ọmọ inú rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ni, wọ́n lè gbàgbé, síbẹ̀ èmi kì yíò gbàgbé rẹ, ilé Isráẹ́lì.

“Kíyèsíi, èmi ti fín ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi.”16

Ààrẹ George Albert Smith kọ́ni pé, “Bu ọlá fún àwọn orúkọ tí ẹ njẹ́, nítorípé ní ọjọ́ kan ẹ ó ní ànfàní àti ojúṣe ti ríròhìn ... fún Baba yín ní ọ̀run ... ohun tí ẹ ti ṣe pẹ̀lú àwọn [orúkọ wọnnì].”17

Bíi àwọn orúkọ ti Néfì àti Léhì tí a ti fi ìṣọ́ra ṣàyàn, njẹ́ a le sọ àti kọ nípa tiwa pé a jẹ́ ọmọlẹ́hìn òtítọ́ ti Olúwa Jésù Krístì? Njẹ́ a nbu ọlá fún orúkọ Jésù Krístì tí a ti fi tìfẹ́tìfẹ́ gbà sí orí ara wa? Njẹ́ a jẹ́ méjèèjì “oníṣẹ́ ìránṣẹ́ àti ẹlẹ́rìí”18 ti ìfẹ́ni-àánú Rẹ̀ àti agbára ìràpadà Rẹ̀?

Ní kò pẹ́ púpọ̀ sẹ́hìn, mo nfetísí kíkà Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ní orí tí ó gbẹ̀hìn ti 2 Néfì, mo gbọ́ tí Néfì sọ ohun kan tí èmi kò tíì ní ọ̀nà kannáà rí ṣaájú. Ní gbogbo jákèjádò àkọsílẹ̀ rẹ̀, ó kọ́ni ó sì jẹ́rìí nípa “Olùràpadà” náà, “Ẹni Mímọ́ Isráẹ́lì” náà, “Ọdọ́ Agùtàn Ọlọ́run” náà, àti “Mèssiah” náà. Ṣùgbọ́n bí ó ti párí ìtàn rẹ̀, mo gbọ́ ọ tí ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Èmi ṣògo nínú síṣe kedere; mo ṣògo nínú òtítọ́; mo ṣògo nínú Jésù mi, nítorí òun ti ra ọkàn mi padà.”19 Nígbàtí mo gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ọkàn mi yọ̀ mo sì níláti fetísíi àti tún fẹtísíi lẹ́ẹ̀kansíi. Mo dáa mọ̀ mo sì dáhùn sí ẹsẹ náà gẹ́gẹ́bí mo ti ndámọ̀ tí mo sì ndáhùn sí orúkọ tèmi.

Olúwa ti wí pé, “Bẹ́ẹ̀ni, alábùkún-fún ni àwọn ènìyàn yí, tí wọ́n ní ìfẹ́ láti jẹ́ orúkọ mi; nítorí ní orúkọ mi ni a o pè wọ́n; wọ́n sì jẹ́ tèmi.”20

Bi ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, njẹ́ kí a le fi “tayọ̀tayọ̀ [gbà sí ara wa] orúkọ Krístì”21 nípa bíbu ọlá fún orúkọ Rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́, ìfọkànsìn, àti iṣẹ́ rere. Mo Jẹ́rìí pé Òun ni “Ọ̀dọ́ Àgùtàn Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ni, àní Ọmọ Baba Ayérayé.”22 Ní orúkọ ọmọ Rẹ̀ mímọ́, Jésù Krístì, àmín.