2010–2019
Lẹ́yìn Ìdánwò Ìgbàgbọ́ Wa
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Lẹ́yìn Ìdánwò Ìgbàgbọ́ Wa

Bí a ṣe ntẹ̀lé ohun Ọlọ́run àti ipa-ọ̀nà májẹ̀mú Rẹ̀, Òun ó fún wa lókun nínú àwọn àdánwò wa.

Nígbàtí mo wà ní ọmọdé, Frank Talley, ọmọ ìjọ kan fúnwa nírànwọ́ láti gbé àwọn ẹbí mi fò nínú ọkọ̀ òfúrufú láti Puerto Rico si Ìlú nlá Salt Lake kí á lè ṣe èdìdí nínú tẹ́mpìlì, ṣùgbọ́n láìpẹ́ àwọn ìdènà bẹ̀rẹ̀sí nyọjú. Ọ̀kan lára àwọn arábìnrin mi, Marivid, bẹ̀rẹ̀ àìsàn. Láìbaralẹ̀, àwọn òbí mi gbàdúrà nípa ohun tí wọn ó ṣe àti pé síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n nímọ̀lára ìṣílétí láti rìnrìnàjò náà. Wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé gẹ́gẹ́bí bí wọ́n bá ti fi ọ̀títọ́ tẹ̀lé ìṣínilétí Olúwa láti lọ sí tẹ́mpìlì, ẹbí wa yíò gba ìtọ̀jú àti ìbùkún—a sì gbà á.

Èyíówù kí àwọn ìdènà tí a dojúkọ ní ayé jẹ́, a lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jésù Krístì yíò múra ọ̀nà kan sílẹ̀ síwájú bí a ti nrìn pẹ̀lú ìgbàgbọ́ ní ṣíṣe ifẹ́ Rẹ̀. Ọlọ́run ti ṣèlérí pé gbogbo ẹnití ó bá fi otitọ gbé gẹ́gẹ́bí àwọn májẹ̀mú tí wọ́n ti ṣe pẹ̀lú Rẹ̀ yíò, ní àkokò Rẹ̀, gba gbogbo ìlérí àwọn ìbùkún Rẹ̀. Alàgbà Holland ti kọ́ni pé, “àwọn ìbùkún kan nwá kíákíá, àwọn kan npẹ́ láti wá, àwọn kan kò ní wá títí di ọ̀run; ṣùgbọ́n fún àwọn wọnnì tí wọ́n gba ìhìnrere ti Jésù Krístì mọ́ra, wọn ó wá1

Mórónì ti kọ́ni pé “ìgbàgbọ́ jẹ́ àwọn ohun tí a ní ìrètí fún tí a kò fi ojú ri; nítorí èyí, ẹ máṣe jiyàn nítorípé ẹ̀yin kò ríi, nítorítí ẹ̀yin kì yíò ri ẹ̀rí gbà títí di lẹ́hìn tí a bá dán ìgbàgbọ́ yín wò.”2

Ìbèèrè wa ni, Kíní ohun tí a ó ṣe júlọ láti borí àwọn àdánwò tí ó bá wá sọ́nà wa?”

Nínú àwọn ọ̀rọ̀ gbangba rẹ àkọ́kọ́ bí Ààrẹ Ìjọ, Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni: “Bí Àjọ Ààrẹ titun, a fẹ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òpin ni ọkàn. Fún ìdí èyí, à nbá yín sọ̀rọ̀ ní òní láti inú tẹ́mpìlì kan. Òpin fún èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa ntiraka ni láti gba ẹ̀bùn agbára nínú ilé Olúwa, láti ní ìsopọ̀ bí ẹbí, láti jẹ́ olóòtọ́ sí àwọn májẹ̀mú tí a ṣe nínú tẹ́mpìlì tí ó mú wa yege fún ẹ̀bùn nlá ti Ọlọ́run—ti ìyè ayérayé. Àwọn ìlànà ti tẹ́mpìlì àti àwọn májẹ̀mú tí ẹ dá níbẹ̀ jẹ́ kókó sí ìfùnlókun ìgbé ayé yín, ìgbéyàwó àti ẹbí yín, àti agbára yín láti tako àwọn àtakò èṣù. Ìjọ́sìn yín nínù tẹ́mpìlì àti iṣẹ́ ìsìn yín níbẹ̀ fún àwọn bàbánlá yín yíò bùkún yín pẹ̀lú ìfihàn araẹni púpọ̀ síi àti àláfíà yíò sì dà ààbò bo ìfẹsẹ̀múlẹ̀ yín láti dúró lórí ipa ọ̀nà májẹ̀mú.”3

Bí a ṣe ntẹ̀lé ohun Ọlọ́run àti ipa-ọ̀nà májẹ̀mú Rẹ̀, Òun ó fún wa lókun nínú àwọn àdánwò wa.

Ìrìnàjò ẹbí mi sí tẹ́mpìlì ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn ṣòro, ṣùgbọ́n bí a ṣe ndé Tẹ́mpìlì Salt Lake, Utah, ìyá mi, kún fún ìgbàgbọ́, ó wípé, “À máà wà DÁADÁA; Olúwa yíò dá ààbò bò wá.” Láìpẹ́ a fi èdìdí dì wá bí ẹbí, ara arábìnrin mi sì yá. Èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́hìn àdánwò ìgbàgbọ́ àwọn òbí mi nìkan àti ní títẹ̀lé àwọn ìṣílétí Olúwa.

Àpẹrẹ àwọn òbí mi yí ṣì nnípá lórí ẹbí wa loni. Àpẹrẹ wọn kọ́wa ní ìdí ti ẹ̀kọ́ ìhìnrere àti tí ó nrànwálọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ ìtumọ̀, èrò, àti àwọn ìbùkún tí ìhìnrere nmú wá fún wa. Níní ìmọ̀ ìdí tí ìhìnrere ti Jésù Krístì fi lè rànwálọ́wọ́ bákannáà láti kojú àwọn àdánwò wa pẹ̀lú ìgbàgbọ́.

Nígbẹ̀hìn, gbogbo ohun tí Ọlọ́run pè wá sí tí ó sì pàṣẹ fún wá láti ṣe jẹ́ ìfihàn ti ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa àti ìfẹ́ Rẹ̀ láti fún wa ní gbogbo àwọn ìbùkún tí a fipamọ́ fún àwọn olotitọ. A kò lè rò pé àwọn ọmọ wa yíò kọ́ láti nifẹ ìhìnrere fúnra wọn; ó jẹ́ ojúṣe wa bí òbí láti kọ́ wọn. Bí a ṣe nran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ láti kọ́ bí wọn ó ṣe lo agbára láti yàn wọn pẹ̀lú ọgbọ́n, àpẹrẹ òdodo wa lè fún wọn ní ìmísí láti ṣe àwọn àṣàyàn òdodo tiwọn. Ìgbé ayé òdodo wọn yíò àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ lẹ́hìnwá láti mọ òtítọ́ ìhìnrere fún arawọn.

Àwọn ọdọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin, ẹ gbọ́ tí wòlíì nbáa yín sọ̀rọ̀ loni. Ẹ wá láti kọ́ òtítọ́ ti ọ̀run kí ẹ si wá ìmọ̀ ìhìnrere fúnra yín. Ààrẹ Nelson láìpẹ́ gbanilámọ̀ràn pé: “Ọgbọ́n wo ni ẹ kò ní? ... Ẹ tẹ̀lé àpẹrẹ Wòlíì. Ẹ wá ibi kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kan. ... Ẹ rẹ arayín sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run. Ẹ tú ọkàn yín jáde sí Bàbá Ọ̀run. Yípadà sí I fún àwọn ìbèèrè.”4 Bí ẹ ṣe nwá ìtọ́nisọ́nà látọ̀dọ̀ olùfẹ́nì Bàbá Ọ̀run, tí ẹ̀ nfetísílẹ̀ sí àmọ̀ràn àwọn wòlíì alààyè tí ẹ sì nwo àpẹrẹ àwọn òbí òdodo, ẹ̀yin náà lè di ìsopọ̀ alágbára ìgbàgbọ́ kan nínú ẹbí yín.

Sí àwọn òbí pẹ̀lú àwọn ọmọ tí wọ́n ti kúrò ní ipá ọ̀nà májẹ̀mú, ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ padà. Ẹ rànwọ́nlọ́wọ́ láti lóye àwọn òtítọ́ ìhìnrere. Ẹ bẹ̀rẹ̀ nísisìyí; kò ì tíì pẹ́ jù.

Àpẹrẹ ìgbé ayé òdodo lè ṣe ìyàtọ̀ nlá. Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ wípé: “Bí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn a sábà má nronú ‘ìjọ’ bí ohunkan tí o n ṣẹlẹ ní àwọn ilé ìpàdé, pẹ̀lú àtìlẹ́yìn ohun tí ó n ṣẹlẹ̀ nílé. A nílò àtúnṣe sí àwòṣe yí. Àkókò ti tó fun ìjọ gbùngbun-ilé kan, pẹ̀lú àtìlẹ́yìn ohun tí o ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ẹka wa, wọ́ọ̀dù, àti àwọn ilé èèkàn wa.”5

Ìwé mímọ́ kọ́ni pé “Tọ́ ọmọ ní ọ̀nà tí yio tọ̀: nígbàtí o sì dàgbà tán, kì yio kúrò nínú rẹ.”7

Bákannáà wọ́n wípé, “Àti nísisìyí, bí ìwãsù ọ̀rọ̀ nã ṣe ní ipa nlá láti darí àwọn ènìyàn nã sí ipa ṣíṣe èyítí ó tọ́—bẹ̃ni, ó ti ní agbára tí ó tobi jùlọ lórí ọkàn àwọn ènìyàn nã ju idà tàbí ohun míràn tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí nwọn rí—nítorínã Álmà rõ pé ó jẹ́ ohun tí ó tọ̀nà pé kí àwọn kí ó lo agbára tí ó wà nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”7

A gbọ́ ìtàn obìnrin kan ni India ẹni tí ò bínú sí ọmọ rẹ̀ wípé ó njẹ kándì pupọ. Kò sí bí o ṣe bawí to, ó túbọ̀ ntẹ́ ẹyín rẹ dídùn lọ́rùn ni. Nínú ìbàjẹ́ pátápátá, ó pinnu láti mú ọmọkùnrin rẹ̀ lọ rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n kan tí ó nbọ̀wọ̀ fún.

Ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì wípé, “Alàgbà, ọmọkùnrin mi njẹ kándì púpọ̀jù. Ṣé ẹ le bámi gbàáníyànjú kí o dẹ́kun jíjẹ rẹ?”

Ó fetísílẹ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ó sí ọmọ rẹ̀ okùnrin, “Lọ sílé kí o padà wá ní ọ̀sẹ̀ méjì.”

Obìnrin náà mú ọmọkùnrin rẹ̀ ó sì lọ sílé, ó yàálẹ́nu ìdí tí kò fi sọ fún ọmọdékùnrin náà kí ó dẹ́kun jíjẹ kándì púpọ̀.

Lẹ́hìn ọ̀sẹ̀ méjì wọ́n padà. Ọkùnrin ọlọ́gbọ́n náà tààrà sí ọmọdékùnrin ó sì wípé, “Ọmọdékùnrin, ó yẹ kí o dẹ́kun kándì púpọ̀ jíjẹ. Kò dára fún ìlera rẹ.”

Ọmọdékùnrin náà mirí ó sì ṣèlérí pé òun ó ṣeé.

Ìyá ọmọdékùnrin náà bèèrè, “Kínìdí tí ìwọ kò fi sọ ìyẹn fun ní ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́hìn?

Ọkùnrin ọlọ́gbọ́n náà rẹrin. “ Ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́hìn mo ṣì njẹ́ kándì púpọ̀ fúnra mi.”

Ọkùnrin yí gbé pẹ̀lú irú ìṣòtítọ́ pé òun mọ̀ pé àmọ̀ràn rẹ̀ yíò níagbára tí òun náà bá tẹ̀lé àmọ̀ràn ararẹ̀.

Agbára tí a ní lòrì àwọn ọmọ wa ní agbára gidi bí wọ́n ti nrí wa ní fífi òdodo rìn ní ipa-ọ̀nà májẹ̀mú. Wòlíì Jákọ́bù Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ àpẹrẹ irú òdodo bẹ́ẹ̀. Ọmọ rẹ̀ Enos kọ nípa ipá ìkọ́ni bàbá rẹ̀:

“Èmi, Énọ́sì, nínú ìmọ̀ wípé bàbá mi jẹ́ ẹni tí ó tọ́—nítorítí ó kọ́ mi nínú èdè rẹ̀, pẹ̀lú nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Olúwa—ìbùkún sì ni fún orúkọ Ọlọ́run mi fún èyí. ...

“…Àwọn ọ̀rọ̀ tí mo sábà máa ngbọ́ tí bàbá mi nsọ nípa ìyè àìnípẹ̀kun, àti ayọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, sì wọ ọkàn mi lọ.”10

Ìyá àwọn akọni ajagun Lámánáítì ngbé ìgbé ayé ìhìnrere, àti wípé àwọn ọmọ wọn kún fún ìdánilójú. Olórí wọn ròyìn:

A tí kọ́ nwọn nípasẹ̀ àwọn ìyá wọn, pé tí nwọ́n kò bá ṣiyèméjì, Ọlọ́run yíò kó nwọn yọ.

“Nwọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ àwọn ìyá wọn fún mi, wípé: Àwa kò ṣiyèméjì pé àwọn ìyá wa mọ̀ bẹ̃.”11

Énọ́sì àti àwọn akọni ajagun Lámámáítì gba okun nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ àwọn òbí wọn, èyí tí ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn àdánwò ìgbàgbọ́ tiwọn.

A di alábùkún pẹ̀lú ìmúpadàbọ̀sípò Jésù Krístì ní àwọn ọjọ́ wa, èyí tí mó ngbé wa ga nígbàtí a bá nni ìmọ̀lára ìdàmú tàbí ìjákulẹ̀. A tún gba ìdánilójú pé àwọn ìtiraka wa yíò mú èso wá ní àkokò ti Olúwa tí a bá tẹ̀síwájú nínú àwọn àdánwò ìgbàgbọ́ wa.

Ìyàwó mi àti èmi, pẹ̀lú Àjọ Ààrẹ̀ Ìkínní, láìpẹ́ sin Alàgbà David A. Bednar lọ fún ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì ti Port-au-Prince. Ọmọ wa Jorge, tí ó wá pẹ̀lú wa, sọ nípa ìrírí rẹ̀ pé: “Ìyànilẹ́nu, Pàpá! Láìpẹ́ bí Alàgbà Bednar ti bẹ̀rẹ̀ àdúrà ìyàsímímọ́, mo lè ní ìmọ̀lára ìyárí àti ìmọ́lẹ̀ tó kún inú yàrá náà. Àdúrà náà fi kún ìmọmi lọ́pọ̀lọpọ̀ nípa èrò tẹ́mpìlì. Ó jẹ́ ilé Olúwa lódodo.

Nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Nẹ́fì kọ́ni pé bí a ṣe nní ìfẹ́ láti mọ ìfẹ́ Ọlọ́run, Òun ó fún wa lókun. Ó kọ pe, “Èmi Nífáì, nítorí tí mo jẹ ọmọdé lọ́pọ̀lọpọ̀ ... àti pẹ̀lú nítorí tí mo ní ìfẹ́ nlá láti mọ̀ nípa àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, nítorí-èyi, mo kígbe pe Olúwa; sì kíyèsĩ i ó sì bẹ̀ mí wò, ó sì mú ọkàn mi rọ̀ tí mo fi gba gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ nã gbọ́, èyí tí bàbá mi ti sọ; nítorí-èyi, èmi kò ṣọ̀tẹ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin mi.”10

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ẹ jẹ́ kí a ran àwọ ọmọ wa lọ́wọ́ àti gbogbo awọn tó wa ní àyíka wa láti tẹ̀lé ipa-ọ̀nà májẹ̀mú Ọlọ́run kí Ẹ̀mí lè kọ́ wọn kí ó sì rọ̀ wọ́n lọ́kàn láti ní ìfẹ́ láti tẹ̀lé E ní gbogbo ayé wọn.

Bí mo ṣe ngbèrò àpẹrẹ àwọn òbí mi, mo damọ̀ pé ìgbàgbọ́ wa nínú Olúwa Jésù Krístì yíò fi ọ̀nà hàn wá padà sílè wa tọ̀run. ” Momọ̀ pé àwọn ìyanu nwá lẹ́hìn àdánwò ìgbàgbọ́ wa.

Mo jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krítì àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀. Mo mọ̀ pé Òhun ni Olùgbàlà àti Olùdándè wa. Òhun àti Bàbá Ọ̀run wa ní àárọ yẹn ní ìgbà ìrúwé ọdún 1820 sọ̀dọ́ Joseph Smith kékeré, wòlí Ìmúpadàbọ̀sípò. Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì ọjọ́ wa. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Jeffrey R. Holland, “An High Priest of Good Things to Come,” Liahona, Jan. 2000, 45.

  2. Étérì 12:6.

  3. Russell M. Nelson, “As We Go Forward Together,” Liahona, Apr. 2018, 7.

  4. Russell M. Nelson, “Revelation for the Church, Revelation for Our Lives;” Liahona, May 2018, 95.

  5. Russell M. Nelson, “Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀,” Liahona, Nov. 2018, 7.

  6. Ìwé Òwe 22:6.

  7. Álmà 31:5.

  8. Énọ́sì 1:1, 3.

  9. Álmà 56:47-48.

  10. 1 Nífáì 2:16.