Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Pípa Ohùn Àwọn Ènìyàn Májẹ̀mú Mọ́ nínú Ìran tí ó Ndìde
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


Pípa Ohùn Àwọn Ènìyàn Májẹ̀mú Mọ́ nínú Ìran tí ó Ndìde

Ọ̀kan nínú àwọn ojúṣe wa mímọ́ jùlọ ni láti ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ láti mọ̀ jinlẹ̀-jinlẹ̀ àti ní pàtó pé Jésù ni Krístì náà.

Ọkan nínú àwọn àkókò tó wọnilára jùlọ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni àbẹ̀wò ti Olùgbàlà tó jínde sí àwọn ènìyàn ní tẹ́mpìlì ní ilẹ̀ Ibi-ọ̀pọ̀. Lẹ́hìn ọjọ́ kan ti kíkọ́ni, wíwòsàn, àti mímú ìgbàgbọ́ dàgbà, Jésù darí àkíyèsí àwọn ènìyàn sí àwọn ìran tí ó ndìde: “Ó pàṣẹ pé kí wọn ó gbé àwọn ọmọdé wọn wá.”1 Ó gbàdúrà fún wọn Ó sì súre fún wọn ní ọkọ̀ọ̀kan. Ìrírí náà múnilára tóbẹ́ẹ̀ tí Olùgbàlà Fúnrarẹ̀ sunkún ní ìgbà púpọ̀.

Lẹ́hìnnáà, ní bíbá àwọn ọ̀pọ̀ èrò náà sọ̀rọ̀, Jésù wí pé:

“Ẹ wo àwọn ọmọdé yín.”

ˇBí wọn sì ti wò … , wọ́n ríi tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, wọ́n sì rí àwọn ángẹ́lì tí wọn nsọ̀kalẹ̀ jáde láti ọ̀run,” tí wọ́n nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ọmọ wọn.2

Mo ti fi ìgbàkũgbà ronú nípa ìrírí yi. Ó gbọ́dọ̀ ti yọ́ ọkan olukúlùkù ènìyàn! Wọ́n rí Olùgbàlà. Wọ́n ní ìmọ̀lára Rẹ̀. Wọ́n mọ̀ Ọ́. Ó kọ́ wọn. Ó súre fún wọn. Ó sì fẹ́ràn wọn. Kò yanilẹ́nu pé lẹ́hìn ìṣẹ̀lẹ̀ mímọ́ yi, àwọn ọmọdé wọ̀nyí dàgbà sókè láti ṣe ìrànwọ́ ṣe àgbékalẹ̀ àwùjọ àláfíà, ìṣe-rere, àti ìfẹ́ Bíi-ti-Krístì tí ó wà títí fún àwọn ìrandíran.3

Njẹ́ kì yío ha jẹ́ ìyanu bí àwọn ọmọ wa bá le ní irú àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jésù Krístì—ohun kan tí yío so ọkàn wọn mọ́ Ọ! Ó pè wá, bí Ó ti pe àwọn òbí inú Ìwé ti Mọ́mọ́nì wọnnì, láti gbé àwọn ọmọdé wa wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. A lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ Olùgbàlà àti Olùràpadà wọn ní ọ̀nà bí àwọn ọmọdé wọ̀nyí ti ṣe. A le fi hàn wọ́n bí a ti le rí Olùgbàlà nínú àwọn ìwé mímọ́ kí wọn ó sì kọ́ ìpìlẹ̀ wọn lé orí Rẹ̀.4

Ní àìpẹ́ yí, ọ̀rẹ́ dáradára kan kọ́ mi ní ohun kan tí èmi kò fiyèsí tẹ́lẹ̀ nípa òwe ọlọ́gbọ́n ènìyàn tí ó kọ́ ilé rẹ sí orí àpáta. Gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ inú Lúkù, bí ọlọ́gbọn ènìyàn náà ti fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ilé rẹ̀, ó “gbẹ́ ilẹ̀ jìn.”5 Kìí ṣe ìdáwọ́lé kan lásán tàbí tí ó rọrùn—ó gba aápọn!

Láti gbé ìgbé ayé wa le orí Àpáta ti Olùràpadà wa, Jésù Krístì, a nílò láti gbẹ́ ilẹ̀ jìn. A mú ohunkóhun tí ó bá ní yanrìn tàbí tí ó léélẹ̀ nínú ayé wa kúrò. A tẹ̀síwájú nínu gbígbẹ́ ilẹ̀ títí tí a fi rí I. A sì kọ́ àwọn ọmọ wa láti so ara wọn mọ́ Ọ nípasẹ̀ àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú mímọ́, kí ó le jẹ́ pé nígbàtí àtakò àwọn ìjì àti àwọn ìkún omi bá dé, bí wọn ó ti ṣe dájúdájú, wọn ó ní ipá kékeré lórí wọn ˇnítorí àpáta náà ní orí èyí tí a kọ́ [wọn] lé.”6

Okun bíi irú èyí kìí dédé ṣẹlẹ̀. Kì í ṣe àtọwọ́dọ́wọ́ sí ìran tí ó kàn bíi ogún ìní ti ẹ̀mí. Olukúlùkù ènìyàn gbọ́dọ̀ gbẹ́ ilẹ̀ jìn láti rí Àpáta náà.

A kọ́ ẹ̀kọ́ yi láti inú àkọsílẹ̀ míràn nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Nígbàtí Ọba Bẹ́njámínì sọ ọ̀rọ̀ ìparí rẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, wọ́n péjọ bíi àwọn ẹbí láti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀.7 Ọba Bẹ́njámínì sọ ẹ̀rí tó lágbára nípa Jésù Krístì, àwọn ènìyàn náà sì ní ìmọ̀lára jìnlẹ̀ nípa ìjẹ́ri rẹ̀. Wọ́n wí pé:

“Ẹ̀mí náà … ti ṣe àyípadà nlá kan nínú wa, tàbí nínú ọkàn wa. …

“Àwa sì fẹ́ láti wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run wa láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ … ní gbogbo ìyókù àwọn ọjọ́ wa.”8

A le ní ìrètí pé àwọn ọmọdé pẹ̀lú irú àwọn òbí tí wọ́n ní ìyípadà ọkàn jíjinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ yío di yíyí lọ́kàn padà lẹ́hìnwá tí wọn ó sì dá àwọn májẹ̀mú funra ara wọn. Ṣùgbọ́n síbẹ̀, fún àwọn ìdí kan tí a kò mẹ́nubà nínú àkọsílẹ̀ náà, májẹ̀mú tí àwọn òbí dá kò ní ipá pẹ̀lú díẹ̀ nínú àwọn ọmọ wọn. Ní àwọn ọdún púpọ̀ lẹ́hìnwá, “ọ̀pọ̀ wà nínú àwọn ìran tí ó ndìde tí wọn kò le ní òye àwọn ọ̀rọ̀ ọba Bẹ́njámínì, nítorítí wọ́n jẹ́ ọmọdé ní àkókò tí ó bá àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀; wọn kò sì gba àṣà àwọn baba wọn gbọ́.

“Wọn kò sì gba ohun tí a ti sọ gbọ́ nípa àjĩnde àwọn òkú, bẹ́ẹ̀ni wọn kò sì gbàgbọ́ nípa bíbọ̀ Krístì.

“Wọn kò sì ṣe ìrìbọmi, bẹ́ẹ̀ni wọn kò darapọ̀ mọ́ ìjọ. Wọ́n sì jẹ́ àwọn ènìyàn ọ̀tọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wọn.”9

Irú èrò ìfarabàlẹ̀ wo! Fún ìran tí ó ndìde, kò tó fún ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì láti jẹ́ “àṣà awọn baba wọn.” Wọ́n nílò láti ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì fún àwọn tikara wọn. Bí àwọn ènìyàn májẹ̀mú Ọlọ́run, báwo ni a ti le fi ìfẹ́ láti dá àti láti pa àwọn májẹ̀mú mọ́ sínú ọkàn àwọn ọmọ wa?

A le bẹ̀rẹ̀ nípa títẹ̀lé àpẹrẹ Néfì: “A nsọ̀rọ̀ nípa Krístì, a nyọ̀ nínú Krístì, a nwãsù nípa Krístì, a nsọ-tẹ́lẹ̀ nípa Krístì, a sì nkọ̀wé ní ìbámu sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wa, kí àwọn ọmọ wa lè mọ orísun èwo ni àwọn lè wò fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀sẹ̀ wọn.”10 Àwọn ọ̀rọ̀ Néfì tọ́ka sí aápọn léraléra, títẹ̀síwájú kan láti kọ́ àwọn ọmọ wa nípa Krístì. A le ríi dájú pé ohùn àwọn ènìyàn májẹ̀mú kò dákẹ́ ní etí àwọn ìran tí ó ndìde àti pé Jésù kìí ṣe àkòrí fún Ọjọ́ Ìsinmi-nìkan.11

Ohùn àwọn ènìyàn májẹ̀mú ni a rí nínú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀rí tiwa. A rí i nínú àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì alààyè. A sì pa á mọ́ pẹ̀lú agbára nínú àwọn ìwé mímọ́. Níbẹ̀ ni àwọn ọmọ wa yío wá láti mọ Jésù àti láti rí àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọn. Níbẹ̀ ni wọn yío ti kọ́ ẹ̀kọ́ ti Krístì fún ara wọn. Níbẹ̀ ni wọn yío ti rí ìrètí. Èyí yío múra wọn sílẹ̀ fún wíwá òtítọ́ àti gbígbé ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú ní ọjọ́ ayé.

Mo fẹ́ràn ìmọ̀ràn yí láti ọ̀dọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson:

“Níbo ni a lọ láti gbọ́ Tirẹ̀?

“A lè lọ sínú àwọn íwé mímọ́. Wọ́n kọ́ wa nípa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀, ọlánlá Ètùtù Rẹ̀, àti ètò ìdùnnú àti ìràpadà nlá ti Baba wa. Rírì ara ẹni sínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lojoojúmọ́ ṣe pàtàkì fún ìwà láàyè ti ẹ̀mí, nípàtàkì ní àwọn ọjọ́ wàhàlà púpọ̀si wọ̀nyí. Bí a ti nṣe àpèjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì lójoojúmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ Krístì yíò sọ fún wa bí a ó ṣe dáhùn sí àwọn ìṣòrò tí a kò rò pé a lè dojúkọ.”12

Nítorínáà báwo ni ó ti rí láti ṣe àpèjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì kí a sì gbọ́ Tirẹ̀? Ó dára, ó ri bíi ohunkóhun tí ó bá ṣiṣẹ́ dárajùlọ fún ọ! Ó le jẹ́ kíkórajọ pẹ̀lú ẹbí rẹ láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Ẹmí Mímọ́ kọ́ yín nínú àṣàrò ìwé mímọ́ yín ní lílo Wá, Tẹ̀lé Mi. Ó le jẹ́ kíkórajọ ní ojoojúmọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ láti ka àwọn ẹsẹ díẹ̀ láti inú àwọn ìwé mímọ́ àti nígbànáà wíwò fún àwọn ànfààní láti jọ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ẹ kọ́ bí ẹ ti lo àkókò papọ̀, Ṣá wá ohun tí ó ṣiṣẹ́ fún ìwọ àti ẹbí rẹ; lẹ́hìnnáà gbìyànjú láti ṣe dárajù díẹ̀ síi ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

Gba àfiyèsí yí rò láti inú Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà: “Bí a bá ṣe é bí ẹnìkọ̀ọ̀kan, ìpàdé ẹbí ìrọ̀lé nílé kan, abala àṣàrò ìwé mímọ́, tàbí ìbánisọ̀rọ̀ ìhìnrere le má dàbí pé ó nní àṣeyọrí púpọ̀. Ṣùgbọ́n àkójọpọ̀ àwọn aápọn kékèké, rírọrùn, ní àṣetúnṣe léraléra fún àkókò pípẹ́, le lágbára kí ó sì fúnnilókun púpọ̀ jú ẹ̀kọ́ ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan bíi ìrántí tàbí àpẹrẹ lọ. … Nítorínáà máṣe rẹ̀wẹ̀sì, má sì ṣe dààmú nípa ṣíṣe àṣeyọrí ohun nlá ní gbogbo ìgbà. Ṣá ti ṣe déédé nínú àwọn aápọn rẹ.”13

Ọ̀kan nínú àwọn ojúṣe wa mímọ́ jùlọ ni láti ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ láti mọ̀ jinlẹ̀-jinlẹ̀ àti ní pàtó pé Jésù ni Krístì náà, Ọmọ Ọlọ́run Alààyè, Olùgbàlà àti Olùràpadà ara-ẹni wọn, ẹnití ó dúró ní orí Ijọ Rẹ̀! A kò le fi ààyè gba ohùn májẹ̀mú wa láti di àìgbọ́ tàbí jẹ́ẹ́jẹ́ nígbàtí ó bá kan Òun.

O le ní ìmọ̀lára àìkún ojú òsùnwọ̀n nínú ojúṣe yí, ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ ní ìmọ̀lára ànìkanwà. Fún àpẹrẹ, àwọn ìgbìmọ̀ wọ́ọ̀dù ni a fún láṣẹ láti ṣètò àwọn ìpàdé ìgbìmọ̀ olùkọ́ni fún àwọn òbí. Nínú àwọn ìpàdé ẹ̀ẹ̀kan-lóṣù-mẹ́ta wọ̀nyí, àwọn òbí le kórajọ láti kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ìrírí ara wọn, jọ sọ̀rọ̀ nípa bí wọn ti nfún àwọn ẹbí wọn lókun, kí wọn ó sì kọ́ nípa kókó àwọn ìpìlẹ̀ ìkọ́ni bíi-ti-Kristì. Ìpàdé yí níláti jẹ́ ṣíṣe ní àkókò wákàtí kejì ti ijọ.14 A ndarí rẹ̀ nípasẹ̀ ọmọ ijọ kan ní wọ́ọ̀dù tí a yàn láti ọwọ́ bíṣọ́pù, ó sì ntẹ̀lé ìlànà àwọn ìpàdé ìgbìmọ̀ olùkọ́ni, ní lílo Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà bíi kókó ohun èlò.15 Ẹyin bíṣọ́pù, bí wọ́ọ̀dù yín kò bá tíì máa ṣe àwọn ìpàdé ìgbìmọ̀ olùkọ́ni lọ́wọ́lọ́wọ́ fún àwọn òbí, ẹ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ààrẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi àti ìgbìmọ̀ wọ́ọ̀dù yín láti ṣètò ara yín.16

Ẹyin ọ̀rẹ́ mi nínú Krístì, ẹ nṣe dáradára púpọ̀ ju bí ẹ ti rò lọ. Ẹ ṣá tẹ̀síwájú ní ṣíṣe iṣẹ́ lórí rẹ̀. Àwọn ọmọ yín nwò, wọ́n ntẹ́tísílẹ̀, wọ́n sì nkọ́ ẹ̀kọ́. Bí ẹ ti nkọ́ wọn ẹ ó mọ àdánidá wọn tòótọ́ bii àyànfẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run. Àwọn le gbàgbé Olùgbàlà fún sáà kan, ṣùgbọ́n mo ṣe ìlérí fún yín, Òun kì yío gbàgbé wọn láé! Àwọn àkókò wọnnì nígbàtí Ẹmí Mímọ́ máa nbá wọn sọ̀rọ̀ yío tẹ̀síwájú nínú ọkàn àti inú wọn. Àti pé ní ọjọ́ kan àwọn ọmọ yín yío ṣe àtúnwí ẹ̀rí Énọ́sì pé: “Èmi mọ̀ pé àwọn òbí mi jẹ́ ẹni tí ó tọ́—nítorítí [wọ́n] kọ́ mi nínú ìtọ́jú àti ìkìlọ̀ Olúwa—ìbùkún sì ni fún orúkọ Ọlọ́run mi fún èyí.”17

Ẹ jẹ́kí a gba ìpè Olùgbàlà kí a sì mú àwọn ọmọ wa wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Bí a ti nṣe bẹ́ẹ̀, àwọn yíò rí I. Wọ́n ó ní ìmọ̀lára Rẹ̀. Wọ́n ó mọ̀ Ọ́. Òun ó kọ́ wọn. Òun ó súre fún wọn. Àti pé, áà, Òun ó ti fẹ́ràn wọn tó. Àti pé, áà, èmi ti fẹ́ràn Rẹ̀ tó. Ní orúkọ mímọ́ Rẹ̀, Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. 3 Néfì 17:11.

  2. 2 Néfì 17:23–24; bákannáà wo 3 Néfì 17:11–22.

  3. Wo 4 Néfì 1:1–22.

  4. Wo Lúku 6:47-49; Hẹ́lámánì 5:12.

  5. Lúkù 6:48.

  6. Hẹ́lámánì 5:12.

  7. Wo Mòsíàh 2:5.

  8. Mòsíàh 5:2, 5 Kíyèsíi pé “kò sí ẹnì kan, àfi àwọn ọmọdé, tí kò tĩ wọ inú májẹ̀mú nã àti tí kò gba orúkọ Krístì sí ara wọn” (Mòsíàh 6:2).

  9. Mosiah 26:1-2, 4.

  10. 2 Néfì 25:26.

  11. “Àwọn ohun púpọ̀ wà láti kọ́ni nípa wọn nínú ìhìnrere ti Jésù Krístì tí a mú padàbọ̀ sípò—àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀, àwọn òfin, àwọn àsọtẹ́lẹ̀, àti àwọn ìtàn ìwé mímọ́. Ṣùgbọ́n gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ẹ̀ka ti igi kannáà, nítorítí gbogbo wọn ní èrò kan: láti ran gbogbo àwọn ènìyàn lọ́wọ́ wá sí ọ̀dọ̀ Krístì kí wọn ó sì di pípé nínú Rẹ̀ (wo Járómù 1:11; Mórónì 10:32). Nítorínáà ohunkóhun tó jẹ́ tí ẹ nkọ́ni, ẹ rántí pé ẹ nkọ́ni nípa Jésù Krístì nítòótọ́ àti bí a ṣe le dàbí Rẹ̀” (Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà: Fún Gbogbo Àwọn tó Nkọni Nílé àti nínú Ìjọ [2022], 6).

  12. Russell M. Nelson, “Gbọ́ Tirẹ̀,” Làìhónà, Oṣù Kárún 2020, 89.

  13. Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà,31.

  14. Àwọn ìgbàmọ́ra pàtàkì le jẹ́ ṣíṣe fún àwọn òbí tí wọ́n nkọ́ni ní Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, bíi irú pípàdé ní ìgbà ogún-ìṣẹ́jú àkókò orin kíkọ Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tàbí síṣe ìpàdé kan lọ́tọ̀ ní àkókò míràn (wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 17.4, Ibi Ìkàwé Ìhìnrere).

  15. Àwọn ọmọ Ìjọ àti àwọn olùdarí le béèrè fún Kíkọ́ni ní Ọ̀nà Olùgbàlà nípasẹ̀ Distribution Services. Ó wa ní àrọ́wọ́tó bákannáà ní Ibi ìkàwé Ìhìnrere.

  16. Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò,13.5.

  17. Ẹ́nọ́sì 1:1 Ẹ rántí pé ní ààrin àwọn ìran tí ó ndìde ti àwọn aláìgbàgbọ́ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni Álmà Kékeré àti àwọn ọmọkùnrin Mòsíàh wà. Nígbàtí Álmà Kékeré nígbẹ̀hìn rí ìnílò rẹ̀ láti yí ìgbé ayé rẹ̀ padà, ó rántí ohun tí baba rẹ̀ tí kọ́ni nípa Jésù Krístì—àwọn ìkọ́ni tí Álmà ti patì ní àtẹ̀hìnwá. Ṣùgbọ́n ìrántí rẹ̀ dúró, ìrántí náà sì gba Álmà là ní ti ẹ̀mí (wo Álmà 36:17–20).