Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Ìjọba Ológo
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


Àwọn Ìjọba Ológo

A ní olùfẹ́ni Baba Ọ̀run tí yíò ri pe a gba gbogbo ìbùkún àti gbogbo ohun dídára tí àwọn ìfẹ́ àti àṣàyàn wa fi ààyè gbà.

Àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn nbèèrè lemọ́lemọ́ pé, “Báwo ni ìjọ rẹ̀ ti yàtọ̀ sí àwọn ìjọ Krìstẹ́nì míràn?” Ní àárín àwọn ìdáhùn tí a fúnni ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípa ẹ̀kọ́ Jésù Krístì. Ìṣíwájú jùlọ ní àárín ẹ̀kọ́ náà ni òtítọ́ pé Baba wa Ọ̀run fẹ́ràn gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ gan tí Ó fi nfẹ́ kí gbogbo wa gbé nínú ìjọba ológo kan títiláé. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ó nfẹ́ kí a gbé pẹ̀lú Òun àti Jésù Krístì, ní ayérayé. Ètò rẹ̀ fún wa ní àwọn ìkọ́ni àti ànfàní láti ṣe àwọn àṣàyàn tí yíò mu àyànmọ́ àti ayé tí a yàn dá wa lójú.

1.

Látinú ìfihàn òdé òní a mọ̀ pé òpin àyànmọ́ gbogbo àwọn ẹni tí ó gbé lórí ilẹ̀ ayé kìí ṣe èrò ọ̀run tí kò tó fún òdodo àti ìjìyà ayèrayé ti ọ̀run-àpáàdì fún àwọn ìyókù. Ètò ìfẹ́ni Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀ pẹ̀lú òdodo tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Olùgbàlà, Jésù Krístì: “Nínú ilé Baba mi ọ̀pọ̀ ibùgbé ló wà.”1

Ẹ̀kọ́ tí ìmúpadàbọ̀sípò ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí a fihàn pé gbogbo ọmọ Ọlọ́run—pẹ̀lú ìyọkúrò tí ó dínkù bákannáà láti yẹ̀wò nihin—nígbẹ̀hìn yíò jogún ọ̀kan lára àwọn ìjọba ológo, àní èyí tí ó kéréjù tí ó “kọjá gbogbo òye.”2 Lẹ́hìn àkókò kan nínú èyí tí aláìgbọ́ran ó jìyà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ìjìyà èyí tí yíò múra wọn sílẹ̀ fún ohun tí yíò tẹ̀le, gbogbo ènìyàn yíò jínde wọn ó sì tẹ̀síwájú sí Ìdájọ́ Ìgbẹ̀hìn ti Olúwa Jésù Krístì. Níbẹ̀, olùfẹ́ni olùgbàlà wa, ẹnití, a kọ́ wa pé, “ó ṣe Baba lógo, ó sì gba gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ là,”3 yíò rán gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ sí àwọn ìjọba ológo wọ̀nyí gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ tí wọ́n fihàn nípasẹ̀ àwọn àṣàyàn wọn.

Ẹ̀kọ́ míràn tí kò láfiwé nípa ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ ni àwọn òfin tí a fihàn àti àwọn májẹ̀mú tí ó fún gbogbo ọmọ Ọlọ́run ní ànfàní mímọ́ láti yege fún ipele ògo gígajùlọ nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà. Òpin àjò gígajùlọ náà—ìgbéga nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà—ni ìfojúsùn Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.

Látinú ìfihàn òde-òní, àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní òyè àìláfiwé ti ètò ìdùnnú Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Ètò náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ayé wa bí àwọn ẹ̀mí ṣíwájú kí a tó bí wa, ó sì fi èrèdí àti àwọn ipò ti yíyàn ìrìnàjò wa nínú ayé ikú àti àyànmọ́ tí a fẹ́ lẹ́hìnwá hàn.

ll.

A mọ̀ látinú ìfihàn òde-òní pé “gbogbo àwọn ìjọba ní òfin tí a fúnni”4 àti pé ìjọba ológo tí a gbà ní Ìdájọ́ Ìgbẹ̀hìn ní a pinnu nípa àwọn àṣẹ tí a yàn láti tẹ̀lé nínú ìrìnàjò ayé ikú wa. Lábẹ́ ètò ìfẹ́ni náà, àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjọba wà—ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibùgbé—kí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run lè jogún ìjọba ológo àwọn àṣẹ èyítí wọ́n lè “gbé dáadáa.”

Bí a ti júwe àbínibí àti àwọn ìnílò ti ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìjọba mẹta nínú ètò Baba, a bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gígajùlọ, èyí tí ó jẹ́ àfojúsùn àwọn òfin ọ̀rùn àti àwọn ìlànà tí Ọlọ́run ti fihàn nípasẹ̀ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Nínú ògo “sẹ̀lẹ́stíà”5 àwọn ipele mẹ́ta ló wà,6 nínú èyí tí gígajùlọ jẹ́ ìgbéga nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà. Èyí ni ibùgbé ti àwọn wọnnì “tí wọ́n ti gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀, àti ti ògo rẹ̀,” nítorínáà, “wọ́n jẹ́ àwọn ọlọ́run, àní àwọn ọmọkùnrin [àti ọmọbìnrin] Ọlọ́run”7 wọ́n sì “ngbé níwájú Ọlọ́run àti Krístì rẹ̀ láé àti títíláéláé.”8 Nípa ìfihàn Ọlọ́run ti fi àwọn àṣẹ, ìlànà, àti májẹ̀mú ayérayé hàn tí a gbọ́dọ̀ ṣe àkíyèsí láti gbèrú àwọn ìhùwàsí tọ̀run tí ó pandandan láti dá agbára ọ̀run yí mọ̀. Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn fojúsùn lórí ìwọ̀nyí nítorípé èrèdí Ìjọ tí a múpadàbọ̀sípò yí ni láti múra àwọn ọmọ Ọlọ́run sílẹ̀ fún ìgbàlà nínú ògo ti sẹ̀lẹ́stíà àti, ní pàtàkì jùlọ, fún ìgbéga nínú ìpele rẹ̀ gíga jùlọ.

Ètò Ọlọ́run tí a gbékalẹ̀ lórí òtítọ́ ayérayé, nílò ìgbéga tí a lè dé nípasẹ̀ òdodo sí àwọn májẹ̀mú ti ìgbeyàwó ayérayé ní àárín ọkùnrin kan àti obìnrin kan nínú tẹ́mpìlì mímọ́ nìkan,9 ìgbéyàwó èyí tí yíò wà fún gbogbo àwọn olótítọ́ nígbẹ̀hìn. Èyí ni ìdí ti a fi nkọ́ni pé “lákọ-lábo jẹ́ kókó ìwàolúkúlùkù ti ìṣíwájú ayé, ayé-ikú, àti ìdánimọ̀ ayérayé àti èrèdí.”16

Ìkọ́ni oníyì kan láti ràn wa lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ fún ìgbéga ni ìkéde 1995 lórí ẹbí.11 Ìkéde rẹ̀ fihàn kedere pé àwọn ìnílò sẹ̀lẹ́stíà tí ó nmúra wa sílẹ̀ láti gbé pẹ̀lú Ọlọ́run Baba àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Àwọn tí wọn kò ní òye kíkún nípa ètò ìfẹ́ni ti Baba fún àwọn ọmọ Rẹ̀ le rí ìkéde ẹbí yi bíi ohun tí kò ju ọ̀rọ̀ ìlànà tó ṣeé yí padà kan lọ. Ní ìdàkejì, A fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìkéde ẹbí, tí a dá sílẹ̀ lórí ẹ̀kọ́ tí kò lé parẹ́, ṣe ìtumọ̀ irú àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí níbití abala pàtàkì jùlọ ti ìdàgbàsókè ayérayé wa ti le wáyé.

Àpóstélì Paul ṣe ìjúwe àwọn ipele mẹ́ta ògo, ó fi wọ́n wé àwọn ògo oòrùn, òṣùpá, àti ìràwọ̀.13 Ó dárúkọ èyí tó gajùlọ “sẹ̀lẹ́stíà” àti ìkejì “tẹ̀rrẹ́stíríà.”14 Kò dárúkọ èyí tó kéréjùlọ, ṣùgbọ́n ìfihàn kan sí Joseph Smith fi orúkọ rẹ̀ kun: “tẹ̀lẹ́stíà.”15 Bákannáà ìfihàn míràn júwe ìwà-ẹ̀dá ti àwọn ẹni tí a níláti yàn sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìjọba ológo wọ̀nyí. Àwọn tí kò bá yàn “láti gbé àṣẹ ìjọba sẹ̀lẹ́stíà”16 yíò jogún ìjọba ológo míràn, tí ó kéré ju sẹ̀lẹ́stíà ṣùgbọ́n tí ó dára fún àwọn àṣẹ tí wọn ti yàn tí wọ́n sì lè “gbé.” Ọ̀rọ̀ náà gbé, wọ́pọ̀ nínú àwọn ìwé mímọ́, ó túmọ̀ sí fífi sí ibi ààbò.17 Fún ápẹrẹ, àwọn wọnnì nínú ìjọba tẹ̀rrẹ́stíà—ní àfiwé sí èrò òkìkí ti ọ̀run—“ni àwọn tí wọ́n gbà ní ọ̀dọ̀ Ọmọ, ṣùgbọ́n kìí ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ti Baba.”18 Àwọn ni “àwọn ènìyàn ọlọ́lá ilẹ̀ ayé, tí a fọ́ lójú nípa ẹ̀tàn àwọn ènìyàn,”19 ṣùgbọ́n “wọn kìí ṣe akọni nínú ẹ̀rí Jésù.”20

Ìjúwe tí a fihàn nípa àwọn tí a yàn sí àwọn ìjọba kíkéréjùlọ lára àwọn ìjọba ológo, tẹ̀lẹ́stíà, ni “ẹni tí kò lè gbé … ògo tẹ̀rrẹ́stíà.”21 Èyí júwe àwọn wọnnì tí wọ́n kọ Olùgbàlà tí wọn kò sì ṣe àkíyèsí òpin tọ̀run fún ìwà wọn. Èyí ni ìjọba níbi tí àwọn búburú ngbé, lẹ́hìn tí wọ́n bá ti jìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ìwọ̀nyí ni a júwe nínú ìfihàn òde-òní bí “àwọn tí kò gba ìhìnrere Krístì, tàbí ẹ̀rí Jésù. …

“Ìwọ̀nyí ni àwọn òpùrọ́, àti oṣó, àti panṣágà, àti alágbèrè, àti ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ràn tí ó sì npa irọ́.”22

Sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ìjọba ológo mẹ́ta pẹ̀lú ìran ti wòlíì rẹ̀, Àarẹ Russell M. Nelson láìpẹ́ kọ pé: “Àkokò ìgbé-ayé ikú ni ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ìṣẹ́jú-akàn tí a bá fiwé àìlópin. Ṣùgbọ́n irú ìṣẹ́jú akàn pàtàkì tí ó jẹ́! Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ yẹ bí ó ti nṣiṣẹ́ wò: Ní ìgbà ayé ikú ẹ ó yan àwọn àṣẹ èyí tí wọ́n nfẹ́ láti gbọ́ran sí—àwọn ti ìjọba sẹ̀lẹ́tíà, tàbí tẹ̀rrẹ́stíà, tàbí tẹ̀lẹ́stíà—àti pé, nítorínáà, nínú ìjọba ológo tí ẹ ó gbé títíláé. Irú ètò kan! Ó jẹ́ ètò kan tí ó nbu ọlá fún agbára òmìnira wa pátápátá.”23

lll.

Àpótélì Paul kọ́ni pé àwọn ìkọ́ni àti òfin Olúwa ni a fúnni kí a lè dé gbogbo “ìwọ̀n ìdàgbà ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Krístì.”24 Ìṣètò yí gbà ju gbígba ìmọ lọ. Àní kò tó láti gba ìdánilójú ìhìnrere; a gbọ́dọ̀ ṣe ìṣe kí a sì ronú kí a yípadà nípa rẹ̀. Ní ìdàkejì sí ìwàásù míràn, èyí tí ó kọ́ wa láti mọ ohunkan, kí ìhìnrere Jésù Krístì pèwáníjà láti da ohunkan.

Látinú irú àwọn ìkọ́ni bẹ́ẹ̀ a parí pé Ìdájọ́ Ìkẹhìn kìí wulẹ̀ ṣe àyẹ̀wò ti àròpọ̀ àwọn ìṣe rere àti búburú nìkan—ó jẹ́ ohun tí a ti ṣe. Ó dá lórí àbájáde ìkẹhìn ti àwọn ìṣe àti àwọn èrò inú wa—ohun tí a ti A nyege fún ìyè ayérayé nípasẹ̀ ìṣetò ti ìyípadà. Bí a ti lòó nihin, ọ̀rọ̀ ti ìtumọ̀ púpọ̀ yí fi ìyípadà jíjinlẹ̀ hàn nípa ìwà-ẹ̀dá. Kò tó fún ẹnikẹ́ni láti kàn lọ nínú àwọn ìṣípòpadà. Àwọn òfin, ìlànà, àti májẹ̀mú ìhìnrere kìí ṣe ìtòsílẹ̀ ìfipamọ́ tí a nílò láti ṣe nínú àwọn àkọsílẹ̀ tọ̀run kan. Ìhìnrere Jésù Krístì ni ètò kan tí ó fi bí a ó ti da ohun tí Baba Ọ̀run nfẹ́ kí a dà.25

IV.

Nítorí Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀, nígbàtí a bá kùnà nínú ayé yí, a lé ronúpìwàdà kí a sì tún ipa ọ̀nà májẹ̀mú tí ó darí sí ohun tí Baba Ọ̀run nfẹ́ fún wa wọ̀.

Ìwé ti Mọ́mọ́nì kọ́ni pé “ayé yí” àkókò fún [wa] láti múrasílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run.”26 Ṣùgbọ́n ìdínkù ti pípeniníjà sí “ayé yí” ni a fún ní ọ̀rọ̀ ìrètí (ó kéréjù dé ibìkan fún àwọn ẹni díẹ̀) nípa ohun tí Olúwa ti fihàn sí Ààrẹ Joseph F. Smith, tí a kọsílẹ̀ nísisìyí nínú Ìpín 138 ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú. Wòlíì kọ pé “Mo rí, ”pé, “àwọn alàgbà olotítọ́ ti àkokò ìríjú yí, nígbàtí wọ́n kúrò ní ayé ikú, tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ wọn ní wíwàásù ìhìnrere ti ìrònúpìwàdà àti ìràpadà, nípasẹ̀ ìrúbọ Ọmọ Bíbí Nìkanṣoṣo ti Ọlọ́run, ní àárín àwọn ẹni tí ó wà nínú òkùnkùn àti lábẹ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀ nínú ayé nlá ti àwọn ẹ̀mí tí wọ́n ti kù.

“Àwọn okú tí wọn bá ronúpìwàdà ni a ó ràpadà, nípasẹ̀ ìgbọràn sí àwọn ìlànà ti ilé Ọlọ́run,

“Àti lẹ́hìn tí wọ́n bá ti jìyà fún àwọn ìrékọjá wọn, àti tí a wẹ̀ wọ́n mọ́, wọn yíò gba èrè kan ní ìbamu sí àwọn iṣẹ́ wọn, nítorí wọn jẹ́ ajogún ìgbàlà.”

Ní àfikún, a mọ̀ pé mìlẹ́níùm, ẹgbẹ̀rún ọdún tí ó tẹ̀lé Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olùgbàlà, yíò jẹ́ àkókò láti ṣe àwọn ìlànà tí a nílò fún àwọn wọnnì tí wọn kò tíì gba wọ́n ní ayé ikú wọn.28

Ọ̀pọ̀ wa tí a kò mọ̀ nípa kókó àwọn àkókò mẹ́tà nínú ètò ìgbàlà: (1) ìṣíwájú ayé ẹ̀mí, (2) ayé ikú, àti (3) ayé tó nbọ̀, àti ìbáṣepọ̀ sí ara wa. Ṣùgbọ́n a mọ àwọn òtítọ́ ayèrayé wọ̀nyí: “Ìgbàlà ni ọ̀ràn ẹnìkọ̀ọ̀kan, ṣùgbọ́n ìgbéga ni ọ̀ràn ẹbí.”29 A ní olùfẹ́ni Baba Ọ̀run tí yíò ri pe a gba gbogbo ìbùkún àti gbogbo ohun dídára tí àwọn ìfẹ́ àti àṣàyàn wa fi ààyè gbà. Bákannáà a mọ̀ pé Oùn kò ní fì ipá mú ẹnìkankan sínú èdìdí ìbàṣepọ̀ ní ìlòdì sí ìfẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin nàà. Àwọn ìbùkún èdìdí ìbáṣepọ̀ ni a mú dájú fún gbogbo àwọn ẹni tí wọ́n bá pa májẹ̀mú wọn mọ́ ṣùgbọ́n kìí ṣe nípa fífi ipá ṣe èdìdí ìbáṣepọ̀ lórí ẹlòmíràn tí kò yẹ tàbí tí kò fẹ́.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, mo jẹri nípa òtítọ́ àwọn ohun wọ̀nyí. Mo jẹ́ ẹ̀rí nípa Olúwa wa Jésù Krístì, “olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ [wa],”30 ẹnití Ètùtù rẹ̀, lábẹ́ ètò Baba wa ní Ọ̀run, nmú kí gbogbo rẹ̀ ṣeéṣe, ní orúkọ Jésù, àmín.