Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Gbé Ọjọ́ náà nínú Krístì
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


Gbé Ọjọ́ náà nínú Krístì

Jésù Krístì mu ṣeéṣe fún wa láti “gbé ní ọjọ́ náa.”

Ó jẹ́ ọjọ́ tí ó kún pẹ̀lú àwọn òwe tààrà àti ìtọ́ni, àwọn ìbèère líle, àtì ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀. Lẹ́hìn fífúnni ní ìbáwí ti àwọn wọnnì tí wọ́n dàbí “ibojì funfun, tí ó dára ní òde, ṣùgbọ́n nínú wọ́n kún fún egungun òkú, àti fún ẹ̀gbin gbogbo,”1 Jésù kọ́ni ní àwọn òwé mẹ́ta si nípa ìmúrasílẹ̀ ti ẹ̀mí àti jíjẹ́ ọmọmẹ̀hìn. Ọ̀kan lára ìwọ̀nyí ni òwe àwọn wúndíá mẹwa.

“Nígbànáà ni a ó fi ìjọba ọ̀run wé àwọn wúndíá mẹwa, tí ó mú fìtílà wọn, tí wọ́n sì jáde lọ ípàdé ọkọ ìyàwó.

“Marun nínú wọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n, marun sì jẹ́ aláìgbọ́n.

“Àwọn tí ó ṣe aláìgbọ́n mú fìtílà wọn, wọn kò mú òróró lọ́wọ́:

“Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n mú òróró nínú kólóbó pẹ̀lú fìtílà wọn.

“Nígbàtí ọkọ ìyàwó pẹ́, gbogbo wọn tòògbé, wọ́n sì sùn.

“Ṣùgbọ́n laarin ọ̀gànjọ́ igbe ta sókè, wípé, Wòó, ọkọ ìyàwó nbọ̀; ẹ jáde lọ̀ ípàdé rẹ̀.

“Nígbànáà ni gbogbo àwọn wundia wọnnì dìde, wọ́n sì tún fìtílà wọn ṣe.

“Àwọn aláìgbọ́n sì wí fún àwọn ọlọ́gbọ́n pé, Fún wa nínú òróró yín; nítorí fìtílà wa nkú lọ.

“Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n dá wọn ní ohùn, wípé, Bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ó má ba ṣe aláìtó fún àwa àti ẹ̀yin: ẹ kúkú tọ àwọn tí ntà lọ, kí ẹ sì ra fún ara yín.

“Nígbà tí wọ́n sì lọ rà, ọkọ ìyàwó dé; àwọn tí ó sì múra tán bá a wọlé lọ sí ibi ìyàwó: a sì ti lẹ̀kùn.

“Ní ìkẹhìn ni àwọn wundia ìyókù sì dé, wọ́n wípé, Olúwa, Olúwa, ṣílẹ̀kùn fún wa.”8

“Ṣùgbọ̀n ó dáhùn wípé, lóòtọ́ ni mo wí fún yín, Ẹ̀yin kò mọ̀ mi.2

“Nítorínáà, ẹ má ṣọ́nà, bí ẹ̀yin kò ti mọ ọjọ́, tàbí wákàtí tí Ọmọ-ènìyàn ó dé.”3

Ààrẹ Dallin H. Oaks fi àwọn ìbèère wíwọnilọ́kàn wọ́nyí hàn ní ìbámu sí bíbọ̀ Ọkọ-ìyàwó:4 “Bí ọjọ́ bíbọ̀ Rẹ̀ bá jẹ́ ọ̀la nkọ́? Bí a bá mọ̀ pé a ó pàdé Olúwa lọ́la—nípa ikú àìtọ́jọ́ wa tàbí nípa bíbọ̀ àìròtẹ́lẹ̀ Rẹ̀—kíni a ó ṣe ní òní?”5

Èmi ti kẹkọ látinú ìrírí araẹni pé ìmúrasílẹ̀ ti ẹ̀mí fún bíbọ̀ ti Olúwa kìí ṣe pàtàkì nìkan ṣùgbọ́n ọ̀nà kanṣoṣo láti rí àláfíà tòótọ́ àti ìdùnnú.

Ó jẹ́ ọjọ́ rírún ewé kan nígbàtí mo kọ́kọ́ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ náà “O ní ààrùn jẹjẹrẹ.” Ó ya emì àti ọkọ mi lẹ́nu! Bí a ti nwakọ̀ lọ sílé ní ìdákẹ́rọ́rọ́ tí à nro ìròhìn náà, ọkàn mi yí sí àwọn ọmọkùnrin wa mẹ́ta.

Ní inú mi mo bèèrè lọ́wọ Baba Ọ̀run, “Ṣé èmi ó kú?”

Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sími létí, “Ohun gbogbo yíò dára.”

Lẹ́hìnnáà mo bèèrè, “Ṣe èmi ó yè?”

Lẹ́ẹ̀kansi, ìdáhùn náà wá, “Ohun gbogbo yíò dára.”

Mo ní ìdàmú. Kini ìdí tí mo fi gba ìdáhùn irú kannáà bóyá èmi ó yè tàbí kú?

Nígbànáà lọ́gán gbogbo orikeríke ara mi kún pẹ̀lú àláfíà pípé bí a ti rán mi létí: A kò nílò láti kánjú lọ sílé kí a sì kọ́ àwọn ọmọ wa bí wọn ó ti gbàdúrà. Wọ́n mọ̀ bí wọn ó ti gba àwọn ìdáhùn àti ìtùnú látinú àdúrà. A kò nílò láti kańjú lọ sílé kí a sì kọ́ wọn nípa àwọn ìwé-mímọ́ tàbí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì alààyè. Àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì ti jẹ́ orísùn okun mímọ́nilára àti níní ìmọ̀ kan. A kò nílò láti kánjú lọ sílé kí a sì kọ́ wọ́n nípa ìrònúpìwàdà, Àjínde, Ìmúpadàbọ̀sípò, ètò ìgbàlà, àwọn ẹbí ayérayé, tàbí ẹ̀kọ́ ti Jésù Krístì gan.

Ní àkokò náà gan gbogbo ẹ̀kọ́ ìpàdé ilé ẹbí ìrọ̀lẹ́, abala àṣàrò ìwé-mímọ́, àdúrà ìgbàgbọ́ tí a fúnni, ìbùkún tí a fúnni, ẹ̀rí tí a pín, májẹ̀mú tí a dá tí a sì pamọ́, ilé Olúwa tí a lọ, àti ọjọ́ Sabbáótì tí a kíyèsí ṣe kókó—ah, bí ó ti ṣe kókó! Ó ti pẹ́ jù láti fi òróró sí inú fìtílà wa. A nílò gbogbo ìkán kọ̀ọ̀kan, a sì nílò rẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí!

Nítorí Jésù Krístì àti ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Rẹ̀, bí mo bá kú, ẹbí mi yíò jẹ́ títùnínú, fífúnlókun, àti pé wọn ó jẹ́ mímúpadàbọ̀sípò ní ọjọ́ kan. Bí mo bá yè, èmi yíò ní ààyè sí agbára títóbi jùlọ ní orí ilẹ̀ ayé láti ṣèrànwọ́ láti tùnínú, múdúró, àti láti wò mí sàn. Ní òpin, nítorí Jésù Krístì, gbogbo rẹ̀ le dára.

A kẹkọ látinú àṣàrò pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ohun tí “o dára” dàbí:

“Àti ní ọjọ́ náà, nígbàtí Èmi ó wá nínú ògò mi, ni òwe èyí tí Èmi ti sọ nípa àwọn wúndíà mẹ́wa ó wá sí ìmúṣẹ.

“Nítorí àwọn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n tí wọ́n sì gba òtítọ́, àti tí wọ́n ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe atọ́nà wọn, tí a kò sì tíì tàn wọ́n jẹ—lootọ ni mo wí fún yín, a kì yíò ké wọn lulẹ̀ kí a sì sọ wọ́n sínú iná, ṣùgbọ́n wọn yíò gbé ní ọjọ́ náà.”7

Jésù Krístì mu ṣeéṣe fún wa láti “gbé ní ọjọ́ náa.” Dídúró ní ọjọ́ náà kò túmọ̀ sí fífikún ohun tí a níláti ṣe tí ó npọsì títíláé. Ronú nípa jígí ìmútóbí kan. Èrèdí rẹ̀ gan kìí ṣe láti mú àwọn nkan tóbí si nìkan. Bákánnáà ó lè kójọ kí ó sì dojúkọ ìmọ́lẹ̀ láti mu lágbára si. A nílò láti mú rọrùn, kí ìtiraka wa ní ìfojúsùn, kí a sì jẹ́ olùkójọ Ìmọ́lẹ̀ Jésù Krístì. A nílò àwọn ìrírí mímọ́ àti ìfihàn si.

Wíwà ní àríwá ìwọ̀-oòrùn Ísráẹ́lì, ni òkè rírẹwà ibití a máa npè ní “òkè aláwọ-ewé.” Òkè Carmel7 dúró ní àwọ̀-ewé ní gbogbo ọdún yípo púpọ̀ jùlọ ní apákan sí oye ìrì tíntín. Ṣíṣìkẹ́ nṣẹlẹ̀ lójojúmọ́. Bíiti “ìrì Carmel,”8 bí a bá wá láti ṣìkẹ́ ẹ̀mí wa “pẹ̀lú àwọn ohun tí ó rọ̀mọ́ òdodo,”9 ,”àwọn ohun jẹ́jẹ́ àti kékeré,”10 àwọn ẹ̀rí wa àti àwọn ẹ̀rí àwọn ọmọ wa yíò yè!

Nísisìyí, ẹ lè máa ronú, “Ṣùgbọ́n Arábìnrin Wright, ìwọ kò mọ ẹbí mi. À nlàkàkà gidi a kò sì rí bí èyí rárá.” O jẹ́ títọ́. Èmi kò mọ ẹbí yín. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pẹ̀lú ìfẹ́, àánú, agbára, ìmọ̀, àti ògo àìlópin mọ̀ ọ́.

Àwọn ìbèèrè tí ẹ lè máa bèèrè ni àwọn ìbèèrè ọkàn tí ó ní ìrora nínú ìjìnlẹ̀ ẹ̀mí yín. Àwọn ìbèèrè irúkannáà ni a rí nínú àwọn ìwé mímọ́:

“Olùkọ́ni, ìwọ̀ kò bìkítà pé [ẹbí mi] yóò ṣègbé?”11

“Ibo ni ìrètí mi nísisìyí?”12

“Kíni [èmi] ó ṣe, tí ìkukù tí ó ṣókùnkùn yí lè kúrò ní bíbò [mí] mọ́lẹ̀?”13

“Níbo ni a ó gbé wá ọgbọ́n rí? Níbo sì ni ibi òye?”14

“Báwo ni ó ha ṣeéṣe kí [èmi] ó ṣe di ohun gbogbo tíí ṣe rere mú?”15

“Olúwa, kíni ìwọ ó fẹ́ kí èmi ó ṣe?”16

Nígbànáà àwọn ìdáhùn dídùnmọ́ni rí gidi ni ó sì wá:

“Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ nínú agbára Krístì sí ìgbàlà bí?”17

“Olúwa ha ti pàṣẹ fún ẹnikẹ́ni pé kí wọ́n má pín nínú oore rẹ̀ bí?”18

“Ṣé ẹ̀yin gbàgbọ́ pé [Òun] lè ṣe èyí?”19

“Ẹ̀yin ha gba àwọn wòlíì gbọ́?”20

“Njẹ́ ẹ̀yin ní ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà ẹni nã tí ó dáa yín?”21

“Onídájọ́ gbogbo ayé kì yíò ha ṣe èyí tí ó tọ́?”22

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, a kò lè pín òróró wa, ṣùgbọ́n a lè pín Ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀. Òróró nínú àwọn fìtílà wa kò ní ràn wá lọ́wọ́ nìkan láti “dúró de ọjọ́ náà” ṣùgbọ́n ó lè jẹ́ ohun ìtànnán sí ipa-ọ̀nà tí ó ndarí àwọn wọnnì tí a fẹ́ràn sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà “pẹ̀lú apá ṣíṣí sílẹ̀ láti gbà” wọ́n.23

“Bayi ni Olúwa wí; Da ohùn rẹ dúró nínú ẹkún, àti ojú rẹ nínú omijé: nítorí iṣẹ́ rẹ ní èrè, … wọn ó sì padà wá láti ilẹ̀ ọ̀tá.

“Ìrètí sì nbẹ ni ìgbẹ̀hìn rẹ̀, ni Olúwa wí, pé àwọn ọmọ rẹ yíò padà sí àgbègbè wọn.”24

Jésù Krístì ni “ìrètí ní òpin yín.” Kò sí ohun kankan tí a ní tàbí tí a kò ṣe tí ó kọjá ìnawọ́tó ìrúbọ ayérayé áílópin Rẹ̀. Òun ni èrèdí ìdí tí kò fi ní jẹ́ òpin ìtàn wa láéláé.25 Nítorínáà ẹ̀ “gbọ́dọ̀ tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú Krístì, kí ẹ ní ìrètí dídán, àti ìfẹ́ ti Ọlọ́run àti ti gbogbo àwọn ènìyàn. Nítorí-èyi, bí [a] ó bá tẹ̀síwájú, tí à nṣe àpéjẹ lórí ọ̀rọ̀ Krístì, tí a sì forítì í dé òpin, kíyèsĩ i, báyĩ í ni Baba wí: [A] ó ní ìyè àìnípẹ̀kun.”26

Ìye Ayérayé ni ayọ̀ ayérayé. Ayọ̀ nínú ayé yí, lọ́wọ́lọ́wọ́ nísisìyí—kìí ṣe pẹ̀lú àwọn ìpènijà ọjọ́ wa ṣùgbọ́n nítorí ìrànlọ́wọ́ Olúwa láti kẹkọ látinú àti láti borí wọn nígbẹ̀hìn—àti ayọ̀ àìní-ìwọn ní ayé tí ó nbọ̀. Omijé yíò dá, a ó tún ọkàn ìrora ṣe, a ó rí ohun tí ó sọnù, a ó yanjú àwọn àníyàn, a ó mú àwọn ẹbí padàbọ̀sípò, gbogbo ohun ti Baba sì ní yíò di tiwa.27

Ẹ wo Jésù Krístì kí ẹ sì yè28 ni ẹ̀rí mi ní orúkọ mímọ́ ti àyànfẹ́ “Olùṣọ́-àgùtàn àti Bíṣọ́ọ̀pù ẹ̀mí [wa],”29 Jésù Krístì, àmín.