Àwọn Ìwé Mímọ́
Mósè 3


Orí 3

(Oṣù Kẹfà–Oṣù Kẹwã 1830)

Ọlọ́run dá ohun gbogbo ní ti ẹ̀mí ṣíwájú kí wọ́n ó tó wà ní àdánidá lorí ilẹ̀ ayé—Ó dá ọkùnrin, ẹran ara àkọ́kọ́, ní orí ilẹ̀ ayé—Obìnrin jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ọkùnrin.

1 Báyi ni a parí ọ̀run àti ayé, àti gbogbo ogun wọn.

2 Àti ní ọjọ́ keje èmi, Ọlọ́run, parí iṣẹ́ mi, àti ohun gbogbo èyítí èmi ti dá; mo sì sinmi ní ọjọ́ kẽje kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ mi, gbogbo ohun tí mo ti dá sì parí, èmi, Ọlọ́run, sì ríi pé wọ́n dára;

3 Èmi, Ọlọ́run, sì bùkún ọjọ́ keje, mo sì yà á sí mímọ́; nítorítí nínú rẹ̀ ni mo ti sinmi kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ mi èyítí èmi, Ọlọ́run, ti dá àti tí mo ṣe.

4 Àti nísisìyí, kíyèsíi, mo wí fún ọ, pé èyí ni àwọn ìran ti ọ̀run àti ti ilẹ̀ ayé, nígbàtí a ṣe ẹ̀dá wọn, ní ọjọ́ náà tí èmi, Olúwa Ọlọ́run, dá ọ̀run àti ayé,

5 Àti olukúlùkù ohun ọ̀gbìn ti oko ṣaájú kí ó tó wà ní ilẹ̀ ayé, àti èyíkéyìí ewéko ìgbẹ́ ṣaájú kí ó tó dàgbà. Nítorí èmi, Olúwa Ọlọ́run, dá ohun gbogbo, èyítí mo ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ní ti ẹ̀mí, ṣaájú kí wọ́n ó tó wà ní àdánidá ní orí ilẹ̀ ayé. Nítorí èmi, Olúwa Ọlọ́run, kò tíì mú kí òjò kí ó rọ̀ sí orí ilẹ̀ ayé. Èmi, Olúwa Ọlọ́run, sì ti dá gbogbo àwọn ọmọ ènìyàn; kò sì tíì sí ènìyàn kan láti ro ilẹ̀; nítorí ní ọ̀run ni èmi ti dá wọn; àti síbẹ̀ kò tíì sí ẹlẹ́ran ara ní orí ilẹ̀ ayé, tàbí nínú omi, tàbí ní ojú ọ̀run;

6 Ṣùgbọ́n èmi, Olúwa Ọlọ́run, sọ̀rọ̀, ìkũkù sì jade sókè láti ilẹ̀ ayé, ó sì bomirin gbogbo orí ilẹ̀.

7 Èmi, Olúwa Ọlọ́run, sì dá ènìyàn láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀, mo sì mí èémí ìyè sí inú ihò imú rẹ̀; ènìyàn sì di alààyè ọkàn, ẹlẹ́ran ara àkọ́kọ́ ní orí ilẹ̀ ayé, ọkùnrin àkọ́kọ́ pẹ̀lú; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ohun gbogbo ni a dá síwajú; ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí ni a dá wọn tí a sì ṣe wọ́n gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ mi.

8 Èmi, Olúwa Ọlọ́run, sì gbin ọgbà kan sí ihà ìlà oòrùn ní Édẹ́nì, níbẹ̀ ni mo sì fi ènìyàn náà sí ẹnití mo ti dá.

9 Àti láti inú ilẹ̀ ni èmi, Olúwa Ọlọ́run, ti mú kí olukúlùkù igi kí ó hù, ní àdánidá, tí ó dára ní ojú ènìyàn; àti tí ènìyàn lè rí i. Òun sì di alàyè ọkàn kan pẹ̀lú. Nítorí ti ẹ̀mí ni ní ọjọ́ tí èmi dá a; nítorí tí ó dúró ní àyídà nínú èyítí èmi, Ọlọ́run ṣe ẹ̀dá rẹ̀, bẹ́ẹ̀ni, àní ohun gbogbo tí èmi pèsè fún lílò ènìyàn; ènìyàn sì ríi pé ó dára fún oúnjẹ. Èmi, Olúwa Ọlọ́run, sì gbin igi ìyè pẹ̀lú ní ààrin ọgbà náà, àti bákannáà igi ìmọ̀ rere àti búburú.

10 Èmi, Olúwa Ọlọ́run, sì mú kí odò kan kí ó jade láti Édẹ́nì láti bomirin ọgbà náà; láti ìbẹ̀ ni ó ti pínyà, tí ó sì di ipa ọ̀nà mẹ́rin.

11 Èmi, Olúwa Ọlọ́run, sì pe orúkọ odò ti àkọ́kọ́ ní Písónì, ó sì yí ilẹ̀ Hàfílà ká pátápátá, níbití èmi, Olúwa Ọlọ́run, ti ṣe ẹ̀dá wúrà púpọ̀;

12 Wúrà ilẹ̀ náà sì dára, bídẹlíumù àti òkúta oníksì náà sì wà níbẹ̀.

13 Àti orúkọ odò kejì ni a pè ní Gíhónì; ọ̀kannáà tí ó yí ilẹ̀ Etiópíà ká pátápátá.

14 Àti orúkọ ti odò kẹta ni Híddékélì; èyítí ó lọ sí ìhà ìlà oòrùn Àssíríà. Odò kẹrin ni Eufrates náà.

15 Èmi, Olúwa Ọlọ́run, sì mú ènìyàn náà, mo sì fi òun sí inú ọgbà Édẹ́nì, láti ro ó, àti láti bójútó o.

16 Èmi, Olúwa Ọlọ́run, sì pàṣẹ fún ènìyàn, wí pé: Ní ti olukúlùkù igi inú ọgbà náà ìwọ lè jẹ ní òmìnira,

17 Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kì yíò jẹ nínú rẹ̀, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwọ lè yàn fún ara rẹ, nítorí a ti fi fún ọ; ṣùgbọ́n, rantí pé mo kàá léèwọ̀, nítorí ni ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀ ìwọ yíò kú dájúdájú.

18 Èmi, Olúwa Ọlọ́run, sì wí fún ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo, pé kò dára kí ọkùnrin kí ó nìkan wà; nítorínáà, èmi yíò ṣe olùrànlọ́wọ́ yíyẹ kan fún un.

19 Láti inú ilẹ̀ ni èmi, Olúwa Ọlọ́run, sì ti dá olukúlùkù ẹranko ìgbẹ́, àti olukúlùkù ẹyẹ ojú ọ̀run; tí mo sì pàṣẹ pé kí wọ́n ó wá sí ọ̀dọ̀ Ádámù, láti mọ ohun tí òun yíò pè wọ́n; àwọn pẹ̀lú sì jẹ́ alààyè ọkàn; nítorí èmi, Ọlọ́run, mí èémí ìyè sí inú wọn, mo sì pàṣẹ pé ohunkóhun tí Ádámù bá pè olukúlùkù ẹ̀dá alààyè, ni yíò jẹ́ orúkọ rẹ̀.

20 Ádámù sì fi àwọn orúkọ fún gbogbo ẹran ọ̀sìn, àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, àti fún olukúlùkù ẹranko ìgbẹ́; ṣùgbọ́n ní ti Ádámù, a kò rí olùrànlọ́wọ́ yíyẹ fún un.

21 Èmi, Olúwa Ọlọ́run, sì mú kí oorun àsùnwọra kí ó kun Ádámù; òun sì sùn, mo sì mú ọ̀kan nínú egungun ìhà rẹ̀ mo sì pa ẹran ara dé dípò níbẹ̀;

22 Àti pé egun ìhà èyítí èmi, Olúwa Ọlọ́run, ti mú kurò lára ọkùnrin, mo fi dá obìnrin kan, mo sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin náà.

23 Ádámù sì wípé: Èyí, mo mọ̀ nísisìyí, jẹ́ egungun ti àwọn egungun mi, àti ẹran ara ti ẹran ara mi; Obìnrin ni a ó máa pèé, nítorítí a mú un jade láti ara ọkùnrin.

24 Nítorínáà ni ọkùnrin yíò ṣe fi bàbá rẹ̀ àti ìyà rẹ̀ sílẹ̀, tí yíò sì fi ara mọ́ ìyàwó rẹ̀; wọn yíò sì di ara kan.

25 Wọ́n sì wà ní ìhòhò àwọn méjèèjì, ọkùnrin náà àti ìyàwó rẹ̀, ojú kò sì tì wọ́n.