2021
Páùlù Ronúpìwàdà
Oṣù Kéje 2021


“Páùlù Ronúpìwàdà,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kéje 2021

“Páùlù Ronúpìwàdà”

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, ,Oṣù Kéje (Agẹmọ) 2021

Páùlù Ronúpìwàdà

Àwọn Iṣe Àpóstélì 9:1–22; 13:9

Àwòrán
Páùlù nkígbe mọ́ ọkùnrin

Lẹ́hìn tí Jésù kú, àwọn ọmọẹ̀hìn tẹramọ́ kíkọ́ àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo ènìyàn ní ó fẹ́ràn ohun tí wọ́n kọ́ni. Ọkùnrin kan tí a pè ní Páùlù burú sí àwọn ẹni tí ó ntẹ̀lé Jésù.

Àwòrán
Ìmọ́lẹ̀ tàn sí orí Páùlù

Ní ọjọ́ kan nígbàtí Páùlù nrin ìrìnàjò, ó rí ìmọ́lẹ̀ dídán láti ọ̀run. Ó gbọ́ ohùn Jésù! Jésù wí fún Páùlù kí ó ronúpìwàdà kí ó sì tẹ̀lé Òun.

Àwòrán
Páùlù bo àwọn ojú rẹ̀

Ìmọ́lẹ́ dídán náà mú kí Páùlù fójú. Ọkùnrin mímọ́ kan tí a pè ní Ananias wo àwọn ojú Páùlù sàn. Páùlù yàn láti ṣe ìrìbọmi.

Àwòrán
Páùlù wàásù sí àwọn èrò

Lẹ́hìn ìyẹn, Páùlù kọ́ àwọn ènìyàn nípa Jésù Krístì. Ó jẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere, olùkọ́ni, àti olórí nlá nínú Ìjọ Krístì.

Àwòrán
ọmọdébìnrin ntu ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú

Mo lè yàn láti jẹ́ onínúrere dípò jíjẹ́ ẹni búburú. Mo lè fi ìgbàgbogbo yàn láti tẹ̀lé Jésù.

Kíkùn Ojú-ewé

Páùlù Ti Wo Jésù

Àwòrán
Páùlù nwo Jésù

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott