Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìdá Kan Dídára Síi
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Ìdá Kan Dídára Síi

Ítiraka kọ̀ọ̀kan láti yípadà tí a ṣe—bíótiwù kí ó lè dàbí ó kéré tó sí wa—kàn lè ṣe ìyàtọ̀ títóbijùlọ nínú ayé wa.

Fún jíju sẹ́ntúrì kan, àwọn ẹgbẹ́ eré-ìje kẹ̀kẹ́ orílẹ̀-èdè ti Great Britain ti jẹ́ ẹlẹ́yà ti yíyí-kẹ̀kẹ́ àgbáyé. Kíkún fún àbọ̀dé, àwọn olùyí-kẹ̀kẹ́ British ti tiraka láti gba àwọn mẹ́dàlì wúrà díẹ̀ ní ọgọ́ọ̀rún ọdún ti àwọn ìdíje Òlímpíkì wọ́n sì ti rẹlẹ̀ síi nínú ìṣẹ̀lẹ̀ marquee yíyí-kẹ̀kẹ́, ìrusókè náà, Ìrìnká ti France gígùn ọlọ́sẹ̀-mẹ́ta—níbití kò sí olùyí-kẹ̀kẹ́ British tí ó yege ní àádọ́fà ọdún. Ìkáàánú gidi ni èrògbà àwọn olùyí-kẹ̀kẹ́ British tí olùrọkẹ̀kẹ́ olókìkí kan fi kọ̀ láti ta àwọn kẹ̀kẹ́ fún àwọn Bírítì, ní ìbẹ̀rù pé yíò ba ipò tí ilé-iṣẹ́ wọn ti ní pẹ̀lu iṣẹ́-àṣekára jẹ́. Bíótilẹ̀jẹ́pé wọ́n fi àwọn ohun-èlò tìtóbi-púpọ̀ sí dídébí ìgbàlódé àti gbogbo idanilẹkọ ìjọba ìgbà-ọ̀tun, kò sí ohunkóhun tó ṣiṣẹ́.

Àwòrán
Àwọn olùyíkẹ̀kẹ́ British

Kò sí ohunkohun, tí ó jẹ́, títí 2003, nígbàtí ìyípadà àìkíyèsí títóbi kékeré kan ṣẹlẹ̀ tí yíò yí ìtọpa yíyí-kẹ̀kẹ́ ti British padà títíláé. Ìyípadà náà ní ìyanjú bákannáà yíò fi ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ ayérayé hàn—pẹ̀lú ìlérí kan—ní ìkàsí wa tí ó nlọ lọ́wọ́ àti ìwákiri ayé-àìkú ìpayà ìgbàkugbà láti mú arawa dárasi. Nítorínáà kíni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní yíyí-kẹ̀kẹ́ British tí ó lè ní ìlò sí ìlépa araẹni wa láti jẹ́ àwọn ọmọbìnrin àti ọmọkùnrin dídárasi Ọlọ́run?

Ní 2003, Arákùnrin Dave Brailsford ni a gbà síṣẹ́. Yàtọ̀ sí àwọn olùkọ́ni-ìdárayá tẹ́lẹ̀ tí wọ́n tiraka, ní wíwá ìyípadà lọ́gán, Arákùnrin Dave Brailsford dìpòbẹ́ẹ̀ dọ́gbọ́n ètè tí ó tọ́kasí “ìdàgbà ààlà àwọn èrè.” Èyí mú ṣíṣe àwọn ìgbèrú kékèké nínú ohungbogbo. Ìyẹn túmọ̀sí wíwọn iye àwọn ìṣirò lemọ́lemọ́ àti idanilẹkọ kíkojú kókó àwọn àìlera.

Ó jẹ́ bákan sí wòlíì Samuel ti èrò Lámánáítì nípa “rí[rìn] pẹ̀lú àkíyèsí.”1 Èrò gbígbòòrò, mímọ́jù síi yí nyẹra fún pàkúté ti fífi àìmọ̀ tẹjúmọ́ wàhálà tó hàn síni tàbí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà lọ́wọ́lọ́wọ́ nìkan. Brailsford ti wí pé, “Gbogbo ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ náà wá látinú àwọn èrò pé bí a bá fọ́ gbogbo ohun tí ó rọ̀mọ́ yíyí-kẹ̀kẹ́ sílẹ̀, tí a sì gbèrú rẹ̀ nípa ìdá kan, ẹ ó gba pàtàkì púpọ̀si nígbàtí ẹ bá kó gbogbo wọn papọ̀.”3

Ọ̀nà rẹ̀ farahàn láti ní ìbámu dáadáa pẹ̀lú ti Olúwa, tí ó kọ́ wa ní pàtàkì ìdá kan—àní ní àìbìkítà fún ìdá ọ̀kàndínlọ́gọ́ọ̀rún. Bẹ́ẹ̀ni, Òun nkọ́ni ní ìhìnrere tí kò falẹ̀ láti wá àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àìní jáde. Ṣùgbọ́n bí a bá lo irú ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ kannáà sí ìwuni ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ kejì ìhìnrere, ìrònúpìwàdà nkọ́? Nítorínáà, ṣe dípò jíjẹ́ bíbàjẹ́ nípa ìrúkèrúdò àti ìyára ìyíká ní àárín ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrònúpìwàdà, bí ó bá jẹ́ pé ọ̀nà wa ni láti mú ìdojúkọ wá kérési—àní bí a ti nmu gboòrò nkọ́? Dípò gbígbìyànjú láti mu ohungbogbo di pípé, bí a bá kojú ohun kanṣoṣo nkọ́?

Fún àpẹrẹ, bí ẹ bá ṣe ìwárí pé ẹ ti pa kíka Ìwé ti Mọ́mọ́nì ojojúmọ́ ti, nínú ìfura igun-ìgbòòrò titun yín nkọ́? Ó dára, dípò fífi-ìtara kà yíká gbogbo àwọn ojú-ewé ọgọrun-marun àti mọ́kànlélọ́gbọ̀n ní alẹ́ kan, tí a bá sì farasìn dípò kí a kàn ka ìdá kan rẹ̀ lásán—tí ó kàn jẹ́ ojú-ewé marun peré ni ọjọ́ kan—tàbí ṣíṣàkósó àfojúsùn míràn fún ipò yín? Ṣe ìdàgbà kékèké ṣùgbọ́n déédé ààlà àwọn èrè inú ayé wa ní òpin tí yíò jẹ́ ọ̀nà sí ìṣẹ́gun àní lórí àwọn àìṣedééde pírẹ́sìkì jùlọ araẹni wa bí? Njẹ́ ọ̀nà ìwọ̀n-díẹ̀ sí kíkojú àwọn àbàwọ́n wa nṣiṣẹ́ lódodo?

Ó dára, ẹnimímọ̀ olùkọ̀wé James Clear wípé ète yí mú ìṣirò náà wà ní ọọgba ní ìbọlá fún wa. Ó tẹnumọ pé “àwọn ìhùwà jẹ́ ‘ìfẹ́ àyíká ti ìgbèrú araẹni.’ Bí ẹ bá lè gba ìdá kan dídárasi nínú ohunkan ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ní òpin ọdún kan … ẹ ó ti dárasi ní ìgbà mẹ́tàdínlógóòjì.”3

Àwọn èrè Brailsford kékèké bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìfarahàn, bí irú irinṣẹ́, ohun-èlò àwọn aṣọ, àti àwọn àwòṣe idanilẹkọ. Ṣùgbọ́n ẹgbẹ́ rẹ̀ kò dúró níbẹ̀. Wọ́n tẹ̀síwájú láti rí àwọn ìgbèrú ìdá kan ní ìfojúfò àti àwọn agbègbè àìlerò bí irú oúnjẹ àní àti àwọn rírunú ìtúnṣe kẹ̀kẹ́. Ní ìgbà pípẹ́, áímòye wọ̀nyí nípa àwọn dídárasi kékèké dàgbà sínú àwọn èsì yíyanilẹ́nu, èyí tí ó wá kíákíá ju tí ẹnikẹ́ni lè rò lọ. Lotitọ, wọ́n wà ní ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ayérayé nínú ìṣe ti “ìlà lórí ìlà, ìlànà lórí ìlànà, díẹ̀ nihin àti díẹ̀ lọhun.”8

Ṣé àwọn àtúnṣe náà yíò mú “ìyípadà títóbi”5 tí ẹ nifẹ wá? Tí a bá muṣe dáadáa, ó dá mi lójú ní ìdá mọ́kàndínlọ́gọ́ọ̀rún pé yíò jẹ́ bẹ́ẹ̀! Ṣùgbọ́n káfítì kan pẹ̀lú ọ̀nà yí ni pé fún àwọn èrè kékèké láti dàgbà, ìgbìyànjú léraléra, ọjọ́ sí ọjọ́ gbọ́dọ̀ wà. Bíótilẹ̀jẹ́pé ó lè dabí a kò di-pípé, a gbọ́dọ̀ ní ìpinnu láti di sùúrù wa mú pẹ̀lú ìtẹramọ́. Ẹ ṣe ìyẹn, àwọn èrè adùn ti òdodo púpọ̀si yíò sì mú ayọ̀ àti àlááfíà tí ẹ̀ nlépa wá. Bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni: “Kò sí ohunkóhun tó ntúnisílẹ̀ si, níyì si, tàbí ṣe pàtàkì sí ìlọsíwájú ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ju ìdojúkọ lórí ìrònúpìwàdà ojoojúmọ́ wa, ti ṣe déédé sí. Ìronúpìwàdà kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ kan; ó jẹ́ ètò kan. Ó ṣe kókó sí ìdùnnú àti àlááfíà ọkàn. Nígbàtí a bá fikún ìgbàgbọ́, ìrònúpìwàdà nṣí ààyè wa sí agbára Ètùtù Jésù Krístì.”9

Àwòrán
Wóró Mọ́stádì
Àwòrán
Igi Mọ́stádì

Bíi ti ìrònúpìwàdà ohun-àmúyẹ ti ìgbàgbọ, àwọn ìwé-mímọ́ hàn kedere. Gbogbo ohun tí a nílò tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ jẹ́ “èérún ìgbàgbọ́ lásán.”10 Tí a bá sì lè yọ̀ọ̀da “hóró mústádì yí”11 níti ọpọlọ, àwa, bákannáà, le ro àwọn ìgbèrú àìlerò àti títayọ nínú ayé wa. Ṣùgbọ́n rántí, bí a kò ti ní gbìdánwò láti lọ ní jíjẹ́ Atilla ti Hun sí Ìyá Teresa lọ́jọ́kan péré, bákánnáà ni a níláti tún ìgbèrú àwọn àwòṣe wa ṣe ní púpọ̀si. Àní bí àwọn àyípadà tí ẹ nílò nínú ayé yín bá jẹ́ ọ̀pọ̀-ọjà, bẹ̀rẹ̀ ní ìwọ̀n kékeré. Ìyẹn nípàtàkì jẹ́ òtítọ́ bí ẹ bá nímọ̀lára ìbonimọ́lẹ̀ tàbí bíbàjẹ́ nípa ìrònúpìwàdà.

Ẹ rántí pé ètò yí ni a kìí ṣeyọrí nígbàgbogbo nínú ẹ̀ṣọ́ láínì kan. Àní ní àárín àwọn onípinnu jùlọ àwọn ìfàsẹ́hìn lè wà. Níní ìrírí ìbàjẹ́ nípa èyí ní ìgbé-ayé tèmi, mo mọ̀ pé ó lè dàbí ẹnipé a nímọ̀lára ìdá kan síwájú àti ìdá mejì sẹ́hìn nígbàmíràn. Síbẹ̀síbẹ̀ bí a bá dúró láìmikàn nínú ìpinnu wa láti mú àwọn èrè ìdá kan kúrò, Òun tí ó ti “gbé àwọn ìbànújẹ́ wa”12 yíò gbé wa dájúdájú.

Ní ìfarahàn, bí a bá wà nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ líle, Olúwa fihàn ó sì wà kedere; a nílò láti dúró, gba ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ bíṣọ́ọ̀pù, kí a sì yí kúrò nínú irú àwọn ìṣe bẹ́ẹ̀ lọ́gán. Ṣùgbọ́n bí Alagbà David A. Bednar ti kọ́ni: “Ìgbèrú ti-ẹ̀mí, díẹ̀díẹ̀, déédé ni àwọn ìṣísẹ̀ tí Olúwa yíò fẹ́ kí a gbé. Mímúrasílẹ̀ láti rìn láìlẹ́bi níwájú Ọlọ́run ni ọ̀kan lára kókó àwọn èrò ayé-ikú àti ìlépa ti ìgbé-ayé; kìí jáde látinú ìṣẹ̀lẹ̀ gìràgìrà ti ìṣe líle ti-ẹ̀mí.”13

Àwòrán
Àwọn olùyíkẹ̀kẹ́ British

Nítorínáà, ṣe ọ̀nà ìwọ̀n-àpò yí sí ìronúpìwàdà àti ìyípadà òdodo nṣiṣẹ́ lódodo? Njẹ́ ẹ̀rí náà wà nínú yíyísíwájú, kí a sọ bẹ́ẹ̀? Yẹ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Yíyí-kẹ̀kẹ́ British ní díkédì méjì tó kọjá látìgbà ìmúṣẹ ìmọ̀ yí. Àwọn ayíkọ̀-kẹ̀kẹ́ British báyìí ti borí ìtàn Irìn-àjò ti France ní ìgbà mẹ́fà yíyanilẹ́nu. Ní ìgbà Eré Òlímpíkì mẹ́rin tó kọjá, Great Britain ti jẹ́ orílẹ̀-èdè aláṣeyege jùlọ ní gbogbo iṣẹ́ Yíyí-kẹ̀kẹ́. Àti nínú Òlímpíkì Tokyo tí ó parí láìpẹ́, UK yege si nínú àwọn mẹ́dálì wúrà nínú yíyí-kẹ́kẹ̀ ju orílẹ̀-èdè kankan míràn lọ.

Àwòrán
Àwọn olùborí Òlímpíkì

Àwọn fótò olùyíkẹ̀kẹ́ British láti (ìyídà láti òkè apá òsìn) Friedemann Vogel, John Giles, àti Greg Baker/àwọn Àwòrán Getty Images

Ṣùgbọ́n àní èyí tó dáraju fàdákà àti wúrà lọ, ìlérí oníyebíye wa ní òpópónà wa sí àwọn ayérayé ni pé nítoọ́tọ́ a ó “borí nínú Krístì.”15 Àti bí a ti farajìn láti ṣe àwọn ìgbèrú kékèké ṣùgbọ́n déédé, a ní ìlérí “adé ògo tí kò ní ṣá kúrò.”16 Pẹ̀lú yíyan nínú ìgboyà ìjúwọ́sí àìṣókùnkùn , mo pé yín láti yẹ ìgbé-ayé yín wò kí ẹ sì rí ohun tí ó dúró-lójúkan tàbí nmú yín rẹlẹ̀ lórí ipa-ọ̀nà májẹ̀mú. Nígbànáà ẹ wòó ní ìgbòòrò. Ẹ lépa ìdọ́gba ṣùgbọ́n àwọn àtúnṣe tó ṣeéṣe nínú ayé yín tí ó lè jáde nínú adùn ayọ̀ ti jíjẹ́ dídára díẹ̀ si.

Rántí, David lo òkúta kékeré kan péré láti mú alágbára tí ó dàbí àìlèrí balẹ̀. Ṣùgbọ́n ó ní okúta mẹ́rin míràn dání. Bákannáà, ìwà ìkà àti àyànmọ́ ayérayé Álmà Kékeré ni a yípadà nípa èrò pàtàkì, jẹ́jẹ́ kan—ìrántí ìkọ́ni baba rẹ̀ nípa àwọn oore-ọ̀fẹ́ ìgbàlà Jésù Krístì. Bẹ́ẹ̀náà ni ó rí pẹ̀lú Olùgbàlà, ẹnití, bíótilẹ̀jẹ́pé kò lẹ́ṣẹ̀, “kò gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n ó tẹ̀síwájú látinú oore-ọ̀fẹ́ sí oore-ọ̀fẹ́, títí tí ó fi gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”17

Àwòrán
Jésù Krístì

Òun ni ẹnití ó mọ̀ ìgbàtí ẹyẹ wọ̀ bákannáà tí ó lè dojúkọ ìṣẹ́jú bíiti àwọn àkokò pàtàkì náà nínú ayé wa àti ẹnití ó ṣetán nísisìyí láti tìyín lẹ́hìn nínú ohunkóhun tí ìwákiri ìdá kan yín tí ó máa jáde nínú ìpàdé àpapọ̀ yí lè jẹ́. Nítorí ìtiraka kọ̀ọ̀kan láti yípadà tí a ṣe—bíótiwù kí ó dàbí ó kéré sí wa—kàn lè ṣe ìyàtọ̀ títóbijùlọ nínú ayé wa.

Ní òpin èyí, Alàgbà Neal A. Maxwell kọ́ni, “Ìtẹnumọ́ kọ̀ọ̀kan ti ìfẹ́ olódodo, àti ìṣe iṣẹ́-ìsìn kọ̀ọ̀kan, àti ìṣe ìjọ́sìn kọ̀ọ̀kan, bí ó ti kéré tó àti pupọ̀si, nfikún àkokò pàtàkì ti-ẹ̀mí wa.”18 Lotitọ, ó jẹ́ nípa kékeré, jẹ́jẹ́, àti, bẹ́ẹ̀ni, àní ìdá kan péré ni àwọn ohun nlá lè wá sí ìmúṣẹ.19 Ìṣẹ́gun ìgbẹ̀hìn ní ìdá ọgọrun dídájú, “lẹ́hìn gbogbo-ohun tí a lè ṣe,”16 nípa okun, èrè, àti àánú Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ ti Jésù Krístì, àmín.