2022
Májẹ̀mú Àìlópin Náà
Oṣù Kẹ́wàá (Ọ̀wàwà) 2022


“Májẹ̀mú Àìlópin Náà,” Làìhónà, Oṣù Kẹwa 2022.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kẹ́wàá 2022

Májẹ̀mú Àìlópin Náà

Gbogbo àwọn tí wọ́n ti dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú Ọlọ́run ní ààyè sí irú ìfẹ́ àti àánú pàtàkì kan.

Àwòrán
àwòrán ti Jésù Krístì

Olúwa Jésù Krístì, láti ọwọ́ Del Parson

Nínú ayé yí tí àwọn ogun àti ìrọ́kẹ̀kẹ̀-ogun ti fàya, ìnílò fún òtítọ́, ìmọ́lẹ̀, àti ìfẹ́ àìlábàwọ́n ti Jésù Krístì ga jù bí ó ti wà rí láé lọ. Ìhìnrere Krìstì jẹ́ ológo, a sì ti di alábùkún láti ṣe àṣàrò rẹ̀ kí a sì gbé ìgbé ayé ní ìbámu sí àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀. A nyọ̀ nínú àwọn ànfàní wa láti pín in—láti jẹ́ ẹ̀rí nípa àwọn òtítọ́ rẹ̀ níbikíbi tí a wà.

Mo ti sọ̀rọ̀ léraléra nípa pàtákí májẹ̀mú ti Ábráhámù àti ìkójọ Ísráẹ́lì. Nígbàtí a bá tẹ́wọ́gba ìhìnrere tí a sì ṣe ìrìbọmi, à ngbé orúkọ mímọ́ Jésù Krístì lé orí ara wa. Ìrìbọmi ni ẹnu ọ̀nà tí ó darí sí dídi ajùmọ̀-ogún sí gbogbo àwọn ìlérí tí a fúnni ní àtijọ́ láti ọwọ́ Olúwa sí Ábráhámù, Isaac, Jákọ́bù, àti àtẹ̀lé wọn.1

“Májẹmú titun àti àìlópin”2 (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 132:6) àti májẹ̀mú Ábráhámù jẹ́ pàtàkì bákannáà—àwọn ọ̀nà méjì tí síṣe àkọ́pọ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run dá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin àti obìnrin ti ara-kíkú ní àwọn àkokò tó yàtọ̀.

Ẹ̀yán-ọ̀rọ̀ àìlópin fihàn pé májẹ̀mú yí ti wà àní ṣíwájú ìpìlẹ̀ ayé! Ètò tí a gbé kalẹ̀ nínú Ìgbìmọ̀ Nlá ní Ọ̀run ní ìdámọ̀ ìronú jinlẹ̀ nínú pé gbogbo wa ni a ó ké kúrò ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ṣe ìlérí pé Òun yíò pèsè Olùgbàlà kan tí yíò borí àwọn àyọrísí Ìṣubú náà. Ọlọ́run sọ fún Ádámù lẹ́hìn ìrìbọmi rẹ̀ pé:

“Ìwọ̀ sì tẹ̀lé ètò ẹni náà tí ó wà láì ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin àwọn ọdún, láti gbogbo ayérayé dé gbogbo ayérayé.

“Kíyèsíi, ìwọ jẹ́ ọ̀kan nínú mi, ọmọ Ọlọ́run; àti báyìí ni gbogbo ènìyàn lè jẹ́ ọmọ mi” (Mósè 6:67–68).

Ádámù àti Éfà tẹ́wọ́gba ìlànà ìrìbọmi wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ètò jíjẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run. Wọ́n ti wọ ipa-ọ̀nà májẹ̀mú.

Nígbàtí ẹ̀yin àti èmi bákannáà bá wọ ipa-ọ̀nà náà, a ní ọ̀nà ìgbé-ayé titun kan. À nti ipa bẹ́ẹ̀ ṣe ẹ̀dá ìbáṣepọ̀ kan pẹ̀lú Ọlọ́run tí ó nfi ààyè gbà Á láti bùkún àti láti yí wa padà. Ipa-ọ̀nà májẹ̀mú ndarí wa padà sí I. Bí a bá jẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ayé wa, májẹ̀mú náà yío darí wa súnmọ́ àti súnmọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sí i. Gbogbo àwọn májẹ̀mú ni a ní èrò láti jẹ́ dídeni. Wọ́n ṣe ẹ̀dá ibáṣepọ̀ kan pẹ̀lú àwọn àsopọ̀ àìlópin.

Ifẹ́ àti Àánú Pàtàkì Kan

Níwọ̀n ìgbàtí a bá ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, à nfi ààye àìmọ́kànle sílẹ̀ títíláé. Ọlọ́run kò ní pa ìbáṣepọ̀ Rẹ̀ tì pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti fi irú ìsopọ̀ kan bẹ́ẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú Rẹ̀. Nítóótọ́, gbogbo àwọn tí wọ́n ti dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú Ọlọ́run ní ààyè sí irú ìfẹ́ àti àánú pàtàkì kan. Ní èdè Hébérù, májẹ̀mú ìfẹ́ náà ni à npè ní hesed (חֶסֶד).3

Hesed kò ní àfiwé Èdè-gẹ̀ẹ́sì tí ó bámu tó . Àwọn ayírọ̀padà ti Ẹ̀dà Ọba Jákọ́bù ti Bíbélì gbọ́dọ̀ ti ní ìlàkàkà pẹ̀lú bí a ó ti lo hesed nínú Èdè-gẹ̀ẹ́sì. Wọ́n máa nyàn “ìfẹ́ni-inúrere nígbàkugbà.” Èyí di púpọ̀ mú ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo ìtúmọ̀ hesed. Àwọn ìyírọ̀padà míràn ni a lò bàkannáà, bí irú “àánú” àti “ìwàrere.” Hesed ni ọ̀rọ̀ àrà ọ̀tọ̀ kan tí ó njúwe ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú nínú èyí tí àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì ní ìsopọ̀ láti jẹ́ olódodo àti olotítọ́ sí ara wọn.

Ìgbeyàwó sẹ̀lẹ́stíà jẹ́ irú ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú kan bẹ́ẹ̀. Ọkọ àti aya dá májẹ̀mu pẹ̀lú Ọlọ́run àti pẹ̀lú ara wọn láti jẹ́ olódodo àti olotítọ́ sí ara wọn.

Hesed jẹ́ irú ìfẹ́ àti àánú pàtàkì kan tí Ọlọ́run ní ìmọ̀lára fún tí ó sì nawọ́ rẹ̀ sí àwọn tí wọ́n dá májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀. A sì ṣe ìdapadà pẹ̀lú hesed fún Un.

Àwòrán
Tọkọ-taya àṣẹ̀ṣẹ̀-gbéyàwó ní òde tẹ́mpìlì kan

Níwọ̀n bí ẹ̀yin àti èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, ìbáṣepọ̀ wa pẹ́lú Rẹ̀ di sísúnmọ́ síi ju ìṣaájú májẹ̀mú wa lọ. Nísisìyí a jẹ́ síso papọ̀.

Fótò láti ọwọ́ Jerry L. Garns

Nítori Ọlọ́run ní hesed fún àwọn tí wọ́n ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀, Òun yíò nifẹ wọn. Òun yíò tẹ̀síwájú láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn yío sì fún wọn ní àwọn ànfàní láti yípadà. Òun yíò dáríjì wọ́n nígbàtí wọ́n bá ronúpìwàdà. Tí wọ́n bá sì ṣáko lọ, Òun yíò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà wọn padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Níwọ̀n bí ẹ̀yin àti èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, ìbáṣepọ̀ wa pẹ́lú Rẹ̀ di sísúnmọ́ síi ju ìṣaájú májẹ̀mú wa lọ. Nísisìyí a jẹ́ síso papọ̀. Nítorí májẹ̀mú wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Òun kò ní ṣàárẹ̀ láé nínú àwọn ìtiraka Rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́, a kò sì ní tán sùúrù tó kún fún àánú Rẹ̀ pẹ̀lú wa láé. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní ibi pàtàkì kan nínú ọkàn Ọlọ́run. Òun ni àwọn ìrètí gíga fún wa.

Ẹ mọ nípa ìkéde onítàn náà tí Olúwa fún Wòlíì Joseph Smith. Ó wá nípa ìfihàn. Olúwa wí fún Joseph pé, “Ìlérí yíì jẹ́ tiyín pẹ̀lú, nítorí ẹ̀yin jẹ́ ti Ábráhámù, ìlérí yíì ni a sì ṣe fún Ábráhámù” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 132:31).

Nípa-èyí, májẹ̀mú àìlópin yí ni a múpadàbọ̀sípò bí ara ìmúpadàbọ̀sípò nla ti ìhìnrere ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀. Ronú nípa rẹ̀! Májẹ̀mú ìgbeyàwó tí a dá nínú tẹ́mpìlì ni a sopọ̀ tààrà sí májẹ̀mú bíi ti Ábráhámù nnì. Nínú tẹ́mpìlì à nfi tọkọ-taya hàn sí gbogbo àwọn ìbùkún ti a pamọ́ fún àwọn olotitọ àtẹ̀lé Ábráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù.

Bí Ádámù ti ṣe, ẹ̀yin àti èmi fúnra wa wọnú ipa-ọ̀nà májẹ̀mú náà ní ibi irìbọmi. Nígbánáà a wọnú rẹ̀ tán pátápátá síi nínú tẹ́mpìlì. Àwọn ìbùkún májẹ̀mú bíi ti-Ábráhámù ni a fúnni nínú àwọn tẹ́mpìlì mímọ́. Àwọn ìbùkún wọ̀nyí fi àyè gbà wa, lẹ́hìn tí a bá di jíjínde, láti “jogún àwọn ìtẹ́-ọba, ìjọba, agbára, agbára-ọba, ilẹ̀-ọba, sí ‘ìgbéga àti ògo wa nínú ohun gbogbo’ [Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 132:19].”4

Ní ìparí àtẹ̀kọ Májẹ̀mú Láéláé, a kà nípa ìlérí Málákì pé Èlíjàh yíò “sì yí ọkàn àwọn bàbá sí àwọn ọmọ, àti ọkàn àwọn ọmọ sí ti àwọn baba wọn” (Málákì 4:6). Ní Ísráẹ́lì àtijọ́, irú ìtọ́ka sí àwọn baba bẹ́ẹ̀ lè ti jẹ́ pẹ̀lú àwọn baba Ábráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù. Ìlérí yí ni a fiyéni nígbàtí a bá ka oríṣi ẹ̀dà ẹsẹ yí tí Mórónì ṣe àtúnwí rẹ̀ sí Wòlíì Joseph Smith: “Òun [Elijah] yíò sì gbìn sí ọkàn àwọn ọmọ àwọn ìlérí tí a ṣe fún àwọn baba, ọkàn àwọn ọmọ yíò sì fà sí ọ̀dọ̀ àwọn baba wọn” (Àkọọ́lẹ̀-ìtàn—Joseph Smith 1:39). Nínú àwọn baba wọnnì dájúdájú ni Ábráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù wà. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 27:9–10.)

Àwòrán
àwòrán ti Jésù Krístì

Àwọn tí wọ́n dá àwọn májẹ̀mú mímọ́ tí wọ́n sì npa wọ́n mọ́ ni a ṣe ìlérí ìyè ayérayé àti ìgbéga fún. Jésù Krístì ni olùdúró ti àwọn májẹ̀mú wọnnì.

Àlàyé láti inú Krístì àti Ọ̀dọ́ Ọlọ́rọ̀ Alakoso, láti ọwọ́ Heinrich Hofmann

Jésù Krístì: Ààrin Gbùngbun ti Májẹ̀mú

Ìrúbọ ètùtù Olùgbàlà mú kí ó ṣeéṣe fún Baba láti mú àwọn ìlérí Rẹ̀ ṣẹ tí Ó ṣe sí àwọn ọmọ Rẹ̀. Nítorí Jésù Krístì ni “ọ̀nà, ati òtítọ́, ati ìyè,” ó tẹ̀le pé “kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le wá sí ọ̀dọ̀ Baba, bíkòṣe nípasẹ̀ [Rẹ̀]” (Jòhánù 14:6). Ìmúṣẹ májẹ̀mú bíi ti-Ábráhámù di rírí nítorí Ètútú Olùgbàlà, Olúwa wa Jésù Krístì. Jésù Krístì wà ní ààrin gbùngbun májẹ̀mú ti-Ábráhámù.

Májẹ̀mú Láéláé kìí ṣe ìwé ti ìwé-mímọ́ nìkan; ó jẹ́ ìwé àkọọ́lẹ̀-ìtàn kan bákannáà. Ẹ rántí kíkà nípa ìgbeyàwó Sáráì àti Ábrámù. Nítorí wọn kò bímọ, Sáráì fi ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀, Hagar, sílẹ̀ láti jẹ́ ìyàwó Ábrámù bákannáà, ní ìbámu pẹ̀lú ìdarí Olúwa. Hagar bí Ishmaẹ́lì.5 Ábrámù nifẹ Ishmaẹ́lì, ṣùgbọ́n òun kọ́ ni ọmọ nípasẹ̀ ẹnití májẹ̀mú yíò fi wá sí ìmúṣẹ. (Wo Gẹ́nẹ́sísì 11:29–30; 16:1, 3, 11; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 132:34.)

Bí ìbùkún láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àti ní ìfesì sí ìgbàgbọ́ Sáráì,6 ó lóyún ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ kí májẹ̀mú náà lè wá sí ìmúṣẹ nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ , Ísáákì (wo Gẹ́nẹ́sísì 17:19). A bí i sínú májẹ̀mú.

Ọlọ́run fún Sáráì àti Ábrámù ní orúkọ titun—Sarah àti Ábráhámù (wo Gẹ́nẹ́sísì 17:5, 15). Fífúnni ní àwọn orúkọ titun wọnnì ṣe àmì ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé titun áti àyànmọ́ titun fún ẹbí yí.

Ábráhámù nifẹ àwọn méjèèjì Ishmaẹ́lì àti Ísáákì. Ọlọ́run wí fún Ábráhámù pé a ó mú Ishmaẹ́lì pọ̀si yíò sì di orílẹ̀-èdè nlá kan (wo Gẹ́nẹ́sísì 17:20). Ní ìgbà kannáà, Ọlọ́run mu hàn kedere pé májẹ̀mú àìlópin ni a ó gbékalẹ̀ nípasẹ̀ Ísáákì (wo Gẹ́nẹ́sísì 17:19).

Gbogbo ẹnití ó bá tẹ́wọ́gba ìhìnrere di ara ìran ti Ábráhámù. Nínú àwọn Galátíà a kà pe:

“Nítorípé iye ẹ̀yin tí a ti ṣe ìrìbọmi fún sínú Krístì ti gbé Krístì wọ̀.

“… Gbogbo yín jẹ́ ọ̀kàn nínú Krístì Jésù.

“Bí ẹyin bá sì jẹ́ ti Krístì, nígbànáà ẹ jẹ́ irú-ọmọ Ábráhámù, àti ajogún gẹ́gẹ́bí ìlérí náà” (Galátíà 3:27–29).

Báyìí, a lè di ajogún sí májẹ̀mú bóyá nípa ìbí tàbí ìsọdọmọ.

Àwòrán
àwọn ènìyàn kórajọ fún ìsìn irìbọmi

Níwọ̀n ìgbà tí a bá ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, à nfi ààye àìmọ́kànle sílẹ̀ títíláé. Ọlọ́run kò ní pa ìbáṣepọ̀ Rẹ̀ tì pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti fi irú ìsopọ̀ kan bẹ́ẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú Rẹ̀.

Ísáákì àti Jákọ́bù ọmọ Rèbékàh ni a bí nínú májẹ̀mú. Ní àfikún, ó yàn láti wọ̀ọ́ nínú ìfẹ́ ti ararẹ̀. Bí ẹ ti mọ̀, orúkọ̀ Jákọ́bù yí padà sí Isráẹ́lì (wo Gẹ́nẹ́sís i`32:28), tí ó túmọ̀ sí “jẹ́ kí Ọlọ́run borí” tàbí “ẹnìkan tí ó borí pẹ̀lú Ọlọ́run.”7

Nínú Ẹ́ksódù a kà pé “Ọlọ́run rántí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ábráhámù, Ísáákì, àti pẹ̀lú Jákọ́bù” (Ẹ́ksódù 2:24). Ọlọ́run wí fún àwọn ọmọ Isráẹ́lì pé, “Bí ẹ̀yin bá fẹ́ gba ohùn mi gbọ́ nítòótọ́, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́, nígbànáà ni ẹ̀yin ó jẹ́ ìṣúra fún mi” (Ẹ́ksódù 19:5).

Gbólóhùn ọ̀rọ̀ “ìṣura ọ̀tọ̀” ni a yípadà láti inú Hébérù segullah, tí ó túmọ̀ sí ohun-ìní onìyelórí gíga—“ìṣura” kan.8

Ìwé Deuterónómì ṣe àtúnsọ pàtàkì májẹ̀mú náà. Àwọn Àpóstélì Májẹ̀mú Titun mọ májẹ̀mú yí. Lẹ́hìn tí Pétérù ti wo ọkùnrin arọ sàn lórí àwọn àtẹ̀gùn tẹ́mpìlì, ó kọ́ àwọn olùwòran nípa Jésù. Pétérù wípé, “Ọlọ́run Ábráhámù, àti Ísáákì, àti Jákọ́bù, Ọlọ́run àwọn baba wa, ti yin Ọmọ rẹ̀ Jésù logo” (Ìṣe àwọn Àpóstélì 3:13).

Pétérù parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa wíwí fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ni ọmọ àwọn wòlíì, àti ti májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti ba àwọn baba yín dá nígbàtí ó wí fún Ábráhámù pé, Àti nínú irú-ọmọ rẹ ni a ti fi ìbùkún fún gbogbo ìdílé ayé” (Acts 3:25). Pétérù mú hàn kedere sí wọn pé ara iṣẹ́ ìránṣẹ́ Krístì ni láti mú májẹ̀mú Ọlọ́run ṣẹ.

Olúwa fi irú ìwàásù kannáà fún àwọn ènìyàn Amẹrika àtijọ́. Níbẹ̀, Krístì tó jínde wí fún àwọn ènìyàn ẹni tí wọ́n jẹ́ gan an. Ó wípé:

“Ẹyin ni ọmọ àwọn wòlĩ; ẹ̀yin ni ti ilé Ísráẹ́lì; ẹ̀yin sì ni májẹ̀mú èyítí Bàbá dá pẹ̀lú àwọn bàbá yín, tí ó wí fún Ábráhámù pé: Àti nínú irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkún fún gbogbo ìbátan ilẹ̀ ayé.

“Bàbá nítorítí ó ti kọ́kọ́ gbé mi dìde sí yín, tí ó sì ti rán mi láti bùkúnfún yín ní mímú olúkúlùkù yín kúrò nínú àwọn ìwà àìṣedẽdé [yín]; èyĩ sì rí bẹ̃ nítorípé ẹ̀yin ni ọmọ májẹ̀mú náà” (3 Néfì 20:25–26).

Njẹ́ ẹ rí pàtàkì èyí bí? Àwọn tí wọ́n bá pa àwọn májẹ̀mú wọn pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́ yíò di sísẹ́ àwọn ẹ̀mí tó nta ẹ̀ṣẹ̀ dànù! Àwọn tí wọ́n bá pa májẹ́mú wọn mọ́ yíò ní okun láti tako ipá ti aráyé lemọ́lemọ́.

Àwòrán
ọkùnrin nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa

Àwọn tí wọ́n bá pa àwọn májẹ̀mú wọn pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́ yíò di sísẹ́ àwọn ẹ̀mí tó nta ẹ̀ṣẹ̀ dànù! Àwọn tí wọ́n bá pa májẹ́mú wọn mọ́ yíò ní okun láti tako ipá ti aráyé lemọ́lemọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Ìhìnrere: Pípín Májẹ̀mú náà

Olúwa ti pàṣẹ pé kí a tan ìhìnrere ká kí a sì pín májẹ̀mú. Ìdí nìyí tí a fi ní àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere. Ó nfẹ́ kí olukúlùkù àwọn ọmọ Rẹ̀ ní ànfàní láti yan ìhìnrere Olùgbàlà kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ lórí ipa-ọ̀nà májẹ̀mú. Ọlọ́run nfẹ́ láti ṣe ìsopọ̀ gbogbo ènìyàn sí májẹ̀mú tí Òun ti dá ní ìgbà àtijọ́ pẹ̀lú Ábráhámù.

Báyìí, iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere jẹ́ apákan pàtàkì ti ìkójọ nlá ti Ísráẹ́lì. Ìkójọpọ̀ náá ni iṣẹ́ pàtàkì jùlọ tí ó nṣẹlẹ̀ ní orí ilẹ̀ ayé ní òni.” Kò sí ohun kankan tí a lè fi wé ní títóbi. Kò sí ohun kankan tí a lè fi wé ní pàtàkì. Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere Olúwa—àwọn ọmọ-ẹ̀hìn—wà nínú ìpènijà títóbi-jùlọ, èrò títóbí-jùlọ, iṣẹ́ títóbí-jùlọ lórí ilẹ̀ ayé ní òní.

Ṣùgbọ́n àní ọ̀pọ̀ wà—púpọ̀ síi. Ìnílò nlá kan wà láti tan ìhìnrere ká sí àwọn ènìyàn ní ẹ̀gbẹ́ kejì ìkelè. Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo ènìyán, ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìkelè, gbádùn àwọn ìbùkún májẹ̀mú Rẹ̀. Ipa-ọ̀nà májẹ̀mú ṣí sílẹ̀ fún gbogbo ènìyàn. A bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn láti rìn ní ipa-ọ̀nà náà pẹ̀lú wa. Kò sí iṣẹ́ míràn tí ó kóni pọ̀ káàkiri ayé tóbẹ́ẹ̀. Nítorí “Olúwa jẹ́ alãnú sí gbogbo àwọn tí yíò fi òtítọ́-inú, pe orúkọ rẹ̀ mímọ́” (Hẹ́lámánì 3:27).

Nítorípé a ti mú Oyè-àlùfáà Melkísédékì padàbọ̀sípò, àwọn obìnrin àti ọkùnrin olùpamọ́-májẹ̀mú ní ààyè sí “gbogbo àwọn ìbùkún ti ẹ̀mí” nípa ìhìnrere (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 107:18; àfikún àtẹnumọ́).

Níbi ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Kirtland ní 1836 lábẹ́ ìdarí Olúwa, Èlíjàh farahàn. Èrèdí Rẹ̀? “Láti yí … ọkàn àwọn ọmọ padà sí àwọn baba” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 110:15). Elíásì bákannáà farahàn. Èrèdí Rẹ̀? Láti fi fún Joseph Smith àti Oliver Cowdery “ìgbà ìríjú ìhìnrere ti Abráhámù, ní wíwí pé nínù wa àti irú ọmọ wa ní gbogbo ìran lẹ́hìn wa yíò di ẹni ìbùkún” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 110:12). Báyìí, Olùkọ́ni fi àṣẹ oyè-àlùfáà àti ẹ̀tọ́ láti gbé àwọn ìbùkún àrà ọ̀tọ̀ ti májẹ̀mú bíi ti-Ábráhámù sí àwọn míràn, sórí Joseph Smith àti Oliver Cowdery.9

Nínú ìjọ, à nrin ìrìnàjò ipa-ọ̀nà májẹ̀mú bí ẹnìkọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀ bákannáà. Gẹ́gẹ́bí àwọn ìgbeyàwó àti àwọn ẹbí ti npín ìsopọ̀ àràọ̀tọ̀ ti ìhà tí ó nṣe ẹ̀dá ìfẹ́ pàtàkì kan, bẹ́ẹ̀ni ìbáṣepọ̀ titun nwáyé nígbàtí a bá so ara wa pọ̀ nípa májẹ̀mú ní-ìbú sí Ọlọ́run wa!

Èyí lè jẹ́ ohun tí Néfì túmọ̀sí nígbàtí ó wípé Ọlọ́run “fẹ́ràn àwọn tí ó bá fẹ́ẹ láti jẹ́ Ọlọ́run wọn” (1 Nefi 17:40). Èyí ni ìdí gan an, bí apákan májẹ̀mú náà, àánú àti ìfẹ́ pàtàkì kan—tàbí hesed—wà fún gbogbo ẹni tí ó wọnú ìsopọ̀ àti ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ yí pẹ̀lú Ọlọ́run, àní “sí àwọn ìran ẹgbẹgbẹ̀rún” (Deuteronomy 7:9).

Dídá májẹ̀mú kan pẹ̀lú Ọlọ́run nyí ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Rẹ̀ padà títíláé. Ó nbùkún wa pẹ̀lú ọ̀pọ̀ òṣùwọ̀n ìfẹ́ àti àánú.10 Ó nhàn lára ẹni tí a jẹ́ àti bí Ọlọ́run yíò ṣe rànwá lọ́wọ́ láti di ohun tí a lè dà. A gba ìlérí pé àwa, bákannáà, lè di “ìṣura ọ̀tọ̀” sí I (Psalm 135:4).

Àwọn Ìlérí àti Ànfàní

Àwọn tí wọ́n dá májẹ̀mú mímọ́ tí wọ́n sì pa wọ́n mọ́ ni a ṣe ilérí ìyè ayérayé àti igbéga fún, “ẹ̀bùn títóbi julọ nínú gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 14:7). Jésù Krístì ni olùdúró ti àwọn májẹ̀mú wọnnì (wo Hébérù 7:22; 8:6). Àwọn olùpamọ́ májẹ̀mú tí wọ́n nifẹ Ọlọ́run tí wọ́n sì fun Un ní ààyè láti borí lórí ohun gbogbo míràn nínú ayé wọn nmu U jẹ́ ipá tó lagbára jùlọ nínú ayé wọn.

Ní ọjọ́ wa a ní ànfàní láti gba àwọn ìbùkún bàbánlá kí a sì kọ́ nípa àwọn ìsopọ̀ wa sí àwọn bàbánlá àtijọ́. Àwọn ìbùkún wọnnì bákannáà pèsè díẹ̀ nínú ohun tí ó wà níwájú.

Àwòrán
Jésù nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú Pétérù

Nítorí májẹ̀mú wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Òun kò ní ṣàárẹ̀ láé nínú àwọn ìtiraka Rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́, a kò sì ní tán sùúrù tó kún fún àánú Rẹ̀ pẹ̀lú wa láé.

Ìwọ Ha Fẹ́ Mi Ju Àwọn Wọ̀nyí Lọ Bí? Láti ọwọ́ David Lindsley

Ìpè wa bí Isráẹ́lì onímájẹ̀mú ni látì ríi dájú pé gbogbo ọmọ Ìjọ mọ ayọ̀ àti àwọn ànfàní tí ó rọ̀mọ́ dídá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó jẹ́ ìpè láti gba gbogbo ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin olùpamọ́-májẹ̀mú níyànjú, láti pín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn tí wọ́n wà ní àyíká agbára wọn. Ó jẹ́ ìpè bákannáà láti ṣe àtílẹhìn àti láti gba àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wa, tí a rán jáde pẹ̀lú àṣẹ láti ṣe ìrìbọmi àti láti ṣèrànwọ́ kó Ísráẹ́lì jọ níyànjú, pé lápapọ̀ a le jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run tí Òun yío sì jẹ́ Ọlọ́run wa (wo Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 42:9).

Gbogbo ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n nkópa nínú àwọn ìlànà oyè-àlùfáà àti tí wọ́n ndá tí wọ́n sì npa àwọn májẹ̀mú mọ pẹ̀lú Ọlọ́run ní ààyè tààrà sí agbára Ọlọ́run. A ngba orúkọ Olúwa lé orí ara wa bí ẹnìkọ̀ọ̀kan. Bákannáà à ngba orúkọ Rẹ̀ lé orí wa bí àwọn ènìyàn. Jíjẹ́ onítara nípa lílo orúkọ Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní títọ́ jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tí àwa bí ẹ̀nìyàn fi ngba orúkọ Rẹ̀ lé orí wa. Nítòótọ́, gbogbo ìṣe àánú ti Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn àti àwọn ọmọ-ìjọ rẹ̀ jẹ́ àfihàn hesedti Ọlọ́run.

Kínìdí tí a ṣe fọ́n Isráẹ́lì ká? Nítorípé àwọn ènìyàn náà já àwọn òfin wọ́n sì sọ àwọn wòlíì ní òkúta. Olùfẹ́ni Baba kan ṣùgbọ́n ti ó nṣọ̀fọ̀ fèsì nípa fífọ́n Isráẹ́lì káàkiri jìnnà réré.11

Bákannáà, Ó fọ́n wọn ká pẹ̀lú ìlérí kan pé ní ọjọ́ kan Isráẹ́lì yíò di kíkójọ lẹ́ẹ̀kansi sínú agbo Rẹ̀.

Ẹ̀yà Júdàh ni a fún ní ojúṣe láti múra ayé sílẹ̀ fún bíbọ̀ àkọ́kọ́ Olúwa. Láti inú ẹ̀yà náà, Màríà ni a pè láti jẹ́ ìyá Ọmọ Ọlọ́run.

Ẹ̀yà Joseph, nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ àti ọmọ Asenath, Ephraim àti Manasseh (wo Gẹ́nẹ́sísì 41:50–52; 46:20), ni a fún ní ojúṣe láti darí nínú ìkójọ Isráẹ́lì, láti múra ayé sílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Olúwa.

Ní irú àkokò-àìlónkà ìbáṣepọ̀ hesed , ó jẹ́ àdánidá nìkan pé Ọlọ́run nfẹ́ láti kó Isráẹ́lì jọ. Òun ni Bàbá wa Ọ̀run! Ó nfẹ́ kí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Rẹ̀—ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìkelè—kí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ìmúpadàbọ̀sípọ̀ ìhìnrere Jésù Krístì.

Ipa-ọ̀nà Ìfẹ́ kan

Ipa-ọ̀nà májẹ̀mú ni ipa-ọ̀nà Ìfẹ́ kan— hesed líle náà, ìtọ́jú àánú náà fún àti nínawọ́ jáde sí ara wa. Níní ìmọ̀lara pé ìfẹ́ ntúnisílẹ̀ ó sì ngbénisókè. Ayọ̀ títóbijùlọ tí ẹ ó ní ìrírí rẹ̀ láé ni ìgbàtí ẹ bá ní ìwọra pẹ̀lú ifẹ́ fún Ọlọ́run àti fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀.

Fífẹ́ Ọlọ́run síi ju ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun míràn lọ ni ipò tí ó nmú àláfíà òtítọ́, ìtùnú, ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni, àti ayọ wá

Ipa-ọ̀nà májẹ̀mú wà nípa ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run—ìbáṣepọ̀ hesed wa pẹ̀lú Rẹ̀. Nígbàtí a bá wọnú májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, a ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú Òun ẹnití yíò pa àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mọ́ nígbàgbogbo. Òun yíò ṣe ohungbogbo tí Ó lè ṣe, láìsí ìrúfin lórí agbára òmìnira wa, láti ràn wá lọ́wọ́ láti pa tiwa mọ́.

Ìwé ti Mọ́mọ́nì bẹ̀rẹ̀ ó sì parí pẹ̀lú ìtọ́ka sí májẹ̀mú àìlópin. Láti ojú-ewe àkọlé rẹ dé ìparí àwọn ẹ̀rí ti Mọ́mọ́nì àti Mórónì, Ìwé ti Mọ́mọ́nì ṣe ìtọ́ka sí májẹ̀mú (wo Mormon 5:20; 9:37). “Jíjáde wá Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni àmì sí gbogbo ayé pé Olúwa ti bẹ̀rẹ̀ láti kó Isráẹ́lì jọ àti láti mú àwọn májẹ̀mú ti Ó ti dá fún Ábráhámù, Ísáákí, àti Jákọ́bù ṣẹ.”12

Ẹ̀yin arákùnrin àti Arábìnrin mi ọ̀wọ́n, a ti pè wá ní àkokò pàtàkì yí nínú ìtàn ayé láti kọ́ aráyé nípa ẹwà àti agbára májẹ̀mú àìlópin. Baba wa Ọ̀run gbẹ́kẹ̀lé wa tààrà láti ṣe iṣẹ́ nlá yí.

Ọ̀rọ̀ yí ni a fúnni bákannáà ní ìpàdé àwọn olórí nínú ípàdé àpapọ̀ gbogbogbò Ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n Oṣù Kẹta, 2022.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Wo Russell M. Nelson, “Àwọn Ọmọ Májẹ̀mú,” Ensign, May 1995, 34.

  2. Májẹ̀mú titun àti àìlópin ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere Jésù Krístì. Ó pẹ̀lú gbogbo àwọn ìlànà àti májẹ̀mú tí ó ṣeéṣe fún ìgbàlà wa (Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 66:2). Ó jẹ́ “titun” nígbàkugbà tí Olúwa bá túnṣe tàbí mú u padàbọ̀sípò, tí ó sì jẹ́ “àìlópin” nítorí kìí yípadà.

  3. Ìsọ̀rọ̀ ní kíkún nípa hesed àti májẹ̀mú àìlópin tí a rí nínú Kerry Muhlestein, Ọlọ́run Yíò Borí: Àwọn Májẹ̀mú Àtijọ́, Àwọn Ìbùkún Òde-òní, àti Ìkójọ Ísráẹ́lì (2021).

  4. Russell M. Nelson, nínú “Àwọn Ẹlẹri Pàtàkì ti Krístì,” Liahona, Apr. 2001, 7.

  5. Ọ̀rọ̀ Hébérù náà Ishmael túmọ̀ sí “Ọlọ́run gbọ́” (Ìtúmọ̀ Bíbélì, “Ishmael”).

  6. “Nípa ìgbàgbọ́ ni Sárà tìkararẹ̀ pẹ̀lú fi ní agbára láti lóyún, nígbàtí ó kọjá ìgbà rẹ̀, nítorí tí ó ka ẹni tí ó ṣe ìlérí sí olotitọ” (Àwọn Hébérù 11:11).

  7. Ìwé Ìtumọ̀ Bíbelì, “Ísráẹ́lì.”

  8. Wo Ìtúmọ̀ Bíbélì, “Ọ̀tọ̀”; “Ìwé-ìtumọ̀ Hebrew àti Chaldee,” Strong’s Exhaustive Concordance of the Bible (1984), 82, word 5459.

  9. Wo Russell M. Nelson, “Ọpẹ́ fún Májẹ̀mú” (Brigham Young University devotional, Nov. 22, 1988), 4, speeches.byu.edu.

  10. “Gbogbo májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run ni ànfàní kan láti súnmọ́ ọ. Sí ẹnikẹ́ni tí ó ronú fún àkokò kan lórí ohun tí wọ́n ti ní ìmọ̀lára rẹ̀ tẹ́lẹ̀ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, láti ní ìsopọ̀ lílejù náà àti ìbáṣepọ̀ sísúnmọ́ si tí ó jẹ́ ìfúnni áílèyẹ̀” (Henry B. Eyring, “Dídá Májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run” [Brigham Young University fireside, Sept. 8, 1996], 3, speeches.byu.edu).

  11. “Bákannáà Olúwa lo ìfọ́nká ti àwọn ènìyàn yíyàn Rẹ̀ yí ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè” (Ìtọ́nisọ́nà sí àwọn Ìwé-mímọ́, “Ísráẹ́lì,” scriptures.ChurchofJesusChrist.org; bákannáà wo Jacob 5:1-8, 20).

  12. Russell M. Nelson, “Ọjọ́ Iwájú Ìjọ náà: Mímúra Ayé Sílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olùgbàlà,” Làìhónà, Apr. 2020, 9.Apr. 2020, 7.