“Rútù àti Nàómì,” Fríẹ́ndì, Oṣu. 2026, 46–48.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ̀ndì, Oṣù Kẹsan 2026
Rutu àti Nàómì
Ẹbí Nàómì gbé ní Júdàh. Wọn kò ní oúnjẹ tí ó tó nítorí ìyàn, nítorínáà wọ́n kó lọ̀ sí Móábù.
Ní Móábù, ọkọ Nàómì kú àti pé àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ gbé àwọn obìnrin tí a pè ní Ọ́pàh àti Rútù níyàwó. Wọ́n tọ́jú Nàómì fún ọdún mẹwa. Ṣùgbọ́n lẹ́hìnnáà àwọn ọkọ Ọ́pàh àti Rútù kú. Nísisìyí àwọn obìnrin náà dánìkanwà.
Ọ́pah padà sílé. Ṣùgbọ́n Rútù nfẹ́ láti dúro kí ó sì tọ́jú Nàómì. Rútù àti Nàómì gbọ́ pé ilẹ̀ Júdàh ti ní ohun ọ̀gbìn lẹ́ẹ̀kansi, nítorínáà wọ́n rìnrìnàjò lọ síbẹ̀.
Wọ́n dé ní ìgbà ìkórè. Ìbátan Nàómì Bóásì ní àwọn pápá. Ó jẹ́ kí Rútù mú wóró àjẹkù fún oúnjẹ. Ó jẹ́ iṣẹ́ aṣekára.
Bóásì bọ̀wọ̀ fún Rútù nítorí ó ṣiṣẹ́ àṣekára ó sì ṣòótọ́ sí Náòmì àti Olúwa.
Rútù ní kí Bóásì fẹ́ òun. Bóásì mọ pé Rútù jẹ́ aṣòótọ́ àti onínúrere obìnrin. Ó faramọ.
Rútù àti Bóásì ṣe ìgbeyàwó wọ́n sì ní ọkùnrin ọmọ-ọwọ́ kan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́hìnnáà, a bí Jésù Krístì sínú ìràn ẹbí yí.
Ojú-ewé Kíkùn
Nítorí Jésù Krístì, Mo Lè Ronùpìwàdà Ki nsì Di Mímọ́
Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Audrey Day. A lè ṣe ẹ̀dà fún lílò Ìjọ nìkan.
Kíni ó nràn yín lọ́wọ́ láti ṣe àwọn yíyàn?
© 2026 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹ́san 2026. Yoruba. 20073 779