Gbogbo ènìyàn ni a kí káàbọ̀ Ẹ bẹ ìjọ kan wò nítòsí yín.

A jẹ́ ìletò àfojúsùn-Krístì kan, tí a nṣe dídára jùlọ wa láti fẹ́ràn àti láti sin àwọn míràn. Ibì kan wà fún yín nihin.
Ẹ wá ìjọ kan nítòsí yín.
People in Lima, Peru: Attending Church

Àwọn ìbéèrè Tó Wọ́pọ̀

Njẹ́ Krìstẹ́nì ni àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn bí?

Bẹ́ẹ̀ni! Gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, a gbàgbọ́ pé Jésù Krístì ni Ọmọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà ti Aráyé. Ó ní ìfẹ́ gbogbo wa ju bí a ṣe lè rò lọ. A rí ara wa gẹ́gẹ́bí olùfọkànsìn ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krísti. Nígbàtí díẹ̀ nínú àwọn ìgbàgbọ́ wa yàtọ̀, a gbàgbọ́ pé nípasẹ̀ ìgbésí-ayé Rẹ̀, iṣẹ́ ìránṣẹ́, ẹbọ, àti àjínde, Jésù Krístì gbà wá là kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ìjìyà, àti ikú.

Ẹ kọ́ díẹ̀ síi nípa àwọn ìgbàgbọ́ wa.

Báwo ni awọn ìsìn Ìjọ ṣe rí?

Àwọn àkókò ìsìn yàtọ̀ láti agbo-ìjọ sí agbo-ìjọ. Síbẹ̀síbẹ, ẹ lè gbáralé iṣẹ́-ìsìn àkọ́kọ́ kan nígbàgbogbo fún gbogbo ènìyàn, tí kílásì àwọn ọmọdé, ọ̀dọ́, àti àwọn àgbàlagbà ó tẹ̀lé.

Ìsìn fún gbogbo ènìyàn ni à npè ní “ìpàdé oúnjẹ Olúwa.” Ìpàdé yìí ní àwọn orin, àdúrà, àti àwọn ìwàásù (tàbí “àwọn ọ̀rọ̀”) nínú tí a nfúnni nípasẹ̀ olúkúlùkù àwọn ọmọ ìjọ ti agbo-ìjọ ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Ṣùgbọ́n apákan pàtàkì jùlọ ti ìpàdé ni ìgbàtí a bá gba oúnjẹ Olúwa (èyítí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú kọmúníọ́nì) láti rántí Olùgbàlà.

Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ díẹ̀ síi nípa àwọn ìsìn ọjọ́ Ìsinmi tàbí kí ẹ wá Ìjọ kan nítòsí yín.

Kíni Ìdí tí Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ṣe ní àwọn Tẹ́mpìlì?

Fún Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn, tẹ́mpìlì kan yàtọ̀ sí àwọn ilé Ìjọ míràn. Tẹmpili jẹ́ ibi tí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ti ngba ìtọ́ni pàtàkì nípa Ọlọrun àti Jesu Kristi. Nínú tẹ́mpìlì, àwọn ọmọ ìjọ ndá àwọn májẹ̀mú ayérayé (tàbi àwọn ìlérí) pẹ̀lú Ọlọ́run. Èyí pẹ̀lú àwọn ìlérí láti pa àwọn òfin mọ́, gbé ìhìnrere ti Jésù Krístì, jẹ́ olótitọ́ nínú ìgbeyàwó, àti láti ṣe ìrànlọ́wọ́ làti tọ́jú ara wa nípa pínpín ohun tí a ní.

Bákannáà, nìtorítí a gbàgbọ́ pé àwọn ẹbí wà láéláé, púpọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ tí a nṣe nínú àwọn tẹ́mpìlì ni látí jẹ́kí àwọn ìsopọ̀ ẹbí pàápàá ní okun síi. Àwọn ìgbéyàwó nínú tẹ́mpìlì ni a nṣe làti wà láéláé, kìí ṣe “títí ikú ò fi pín níyà nìkan.” Àwọn òbí àti àwọn ọmọdé ndi àwọn ẹbí ayérayé nínú àwọn tẹ́mpìlì. Àwọn babanla tún lè gba gbogbo àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì bí ẹnìkan bá ṣe àwọn ìlànà mímọ́ ní ìtìlẹhìn wọn tí wọ́n sì tẹ́wọ́gba ìṣe iṣẹ́ ìsìn náà. Àwọn tẹ́mpìlì jẹ́ àwọn ibi iṣẹ́-àṣekára!

Kíni Ìwé ti Mọ́mọ́nì?

Ìwé ti Mọ́mọ́nìni ìwé mímọ́ onímìísí kan tí ó kọ́ wa lẹkọ nípa Ọlọ́run àti Jésù Krístì. Ó nràn wá lọ́wọ́ láti gba ìdarí fún ìgbésí ayé araẹni wa ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára sísúnmọ́ Jesu Krístì si. Níbo ni orúkọ náà ti wá? Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́hìn, wòlíì ìgbàanì kan tí a pè ní Mọ́mọ́nì ṣe àkójọ àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀. Wọ́n dojúkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpèníjà kannáà tí a ní. Àti gẹ́gẹ́bí àwa, wọ́n rí agbára nígbàtí wọ́n padà sọ́dọ̀ Jésù Krístì. Ẹ Gba ìfihàn sí Ìwé ti Mọ́mọ́nì pẹ̀lú àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere.

Ìwé ti Mọ́mọ́nì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí míràn ti Jésù Krístì àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ àtọ̀runwá Rẹ̀ gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà àti Olùràpadà aráyé. Lápapọ̀, Bíbélì àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì pèsè òye díẹ̀ síi nípa ìfẹ́ nlá ti Ọlọ́run fún gbogbo wa àti pé ó le rànwálọ́wọ́ láti súnmọ́ Ọ. 

Ẹ kẹ́kọ síi nípa bí bíbélì àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì ṣe nṣiṣẹ́ papọ̀.

Njẹ́ a gbàgbọ́ nínú Bíbélì?

Bẹ́ẹ̀ni. Bíbélì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìdìpọ̀ mímọ́ ti ìwé mímọ́, àti pé títẹ̀lé àwọn ìkọ́ni rẹ̀ nmú ayọ̀ wá sí ìgbésí ayé wa. Lẹgbẹ pẹ̀lú Bíbélì, a tún rí ìmísí nínú àwọn ìwé mímọ́ míràn tí ó lámì sí Ìjọ ti Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Gbogbo wọn nṣiṣẹ́ papọ̀ láti kọ́ wa ní àwọn òtítọ́ pàtàkì nípa Ọlọ́run àti Jésù Krístì.

Ẹ kọ́ diẹ síi nipa igbagbọ wa ninu Bíbélì.

Ẹ Wò Díẹ̀ síi

Ẹ dàgbà súnmọ́ Ọlọ́run. Ẹ pàdé pẹ̀lú àwọn Òjíṣẹ́ ìhìnrere.

Ẹ pàdé lórí ayélujára tàbí ojúkojú. A ó dáhùn àwọn ìbèèrè yín a ó sì fi yín hàn sí ìjọ ìbílẹ̀ ìletò yín.

Ẹ Bèèrè fún Ìbẹ̀wò kan
Two sister missionaries prepare to ride the subway in Hong Kong

Jésù Krístì, Àpẹrẹ Wa Pípé

“A nílò láti fẹ́ràn àti láti ṣe rere sí gbogbo ènìyàn. A nílò láti yẹra fún ìjà kí a sì jẹ́ onílàjà nínú gbogbo ìbánisọ̀rọ̀ wa. Èyí kò túmọ̀ sí pé kí a tẹ́mbẹ́lú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àti ààyò wa, ṣùgbọ́n kí a fi títako àwọn ẹlomíràn ní lílelíle sílẹ̀ fún tiwọn. Iyẹn ni ohun tí Ojúṣe Àwòkọ́ṣe Pípé wa ṣe nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀. Ìyẹn ni àpẹrẹ tí Òun ti filélẹ̀ fún wa, bí Ó ti pè wá láti tẹ̀lé Òun.”
Leon Parson will be doing a painting of President Oaks and has requested photos of President Dallin H. Oaks as reference
Ààrẹ Dallin H. Oaks
Wòlíì àti ààrẹ̀ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn

Ìletò Ìgbàgbọ́ kan ní Ìfojúsùn lórí Jésù Kristi

Four Corners: Primary Children
Kíni Ẹ Nretí ní Ìjọ
Ìjọ jẹ́ ibi ààbò kúrò nínú rúdurùdu ti ìgbésí ayé ojojúmọ́—àyè kan níbití ẹ ti lè sin Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ míràn tí wọ́n ngbìyànjú láti dàbí Jésù síi. A o fẹ́ kí ẹ ṣe ìbẹ̀wò!
Pacific, New Zealand, Stock Photos
Àwọn Ìgbàgbọ́ Wa
Gbogbo ìgbàgbọ́ wa dá lórí Ọlọ́run àti Jésù Krístì. Ẹ kẹ́kọ́ díẹ̀ síi nípa ohun tí ẹ gbàgbọ́ àti bíi àwọn ìgbàgbọ́ pàtàkì náà ṣe lè fún yín ní ìmísí láti tẹ̀lé Olùgbàlà.
Ẹ Wá láti Mọ̀ Wá
Pacific, Tonga, Stock Photos
Ẹ Wá láti Mọ̀ Wá
Ẹ ó rí àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn káàkiri gbogbo àgbáyé. Àwa jẹ́ ọ̀rẹ́ àti aládúgbò yín tó nṣiṣẹ́ papọ̀ láti gbìyànjú láti mú kí ayé di ibi tí ó dára síi.

Ẹ gba àwọn ìròhìn lọ́wọ́lọ́wọ́ látinú Ìjọ.

Àwọn ohun rere nṣẹlẹ̀ ní àyíká ayé. Ẹ gba ìmúdojú-ìwọ̀n lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí àwọn iṣẹ́, ìṣẹ̀lẹ̀, ìtiraka ìrànlọ́wọ́ àjalù Ìjọ, àti púpọ̀ síi.

Ẹ Bẹ Yàrá-ìròhìn Wo
Chile: Family Life
Ẹ Wá Ìjọ kan
Nítòsí Yín.
Ẹ pàdé pẹ̀lú àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere
Ẹ Ṣe Àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì